ỌLỌ́RUN OLÓDÙMARÈ, ÀWÁMÁRIDÍ, NÍSIÌYÍ, BA GBOGBO OHUN-IBI JẸ́, PÁTÁPÁTÁ; GBOGBO MÁJẸ̀MÚ ÌRÁNṢẸ́-ẸNI-IBI, ÀṢÌTÁÁNÌ, GBOGBO ÌLÉRÍ, ÈTÒ, ÈTE, ÀTI ÈRÒ TÍ Ó LÒDÌ SÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ YORÙBÁ, ÌRAN YORÙBÁ, ILẸ̀ YORÙBÁ, ÌṢÈJỌBA YORÙBÁ, AGBÈGBÈ-ÀJOGÚNBÁ YORÙBÁ. NÍ AGBÁRA TÍ ỌLỌ́RUN FI NJẸ́ ÈMI-NI, KÍ ÌPARUN NÁÀ ṢẸLẸ̀ SÍ ÀWỌN Ọ̀TÁ YORÙBÁ WỌ̀NYÍ, LỌ́WỌ́LỌ́WỌ́ BÁYI
OLÓDÙMARÈ, ALÁGBÁRA, TÍ Ó NÍ IPÁ; OLÓDÙMARÈ TÍ Ó NÍ IPÁ LÓJÚ OGUN, ỌLỌ́RUN ÀWỌN ỌMỌ-OGUN, ṢE ÌPARUN PÁTÁPÁTÁ, NÍSIÌYÍ, FÚN ÀṢẸ, AGBÁRA ÀTI IPÒ TÍ WỌ́N NLÒ LÁTI JẸGÀBA LÓRÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TI YORÙBÁ, ÌRAN YORÙBÁ, ILẸ̀ YORÙBÁ, ÌṢÈJỌBA YORÙBÁ, AGBÈGBÈ-ÀJOGÚNBÁ YORÙBÁ.
ṢE ÌPARUN FÚN GBOGBO ÌWÀ ÌDÚKOKÒ, ÌJẸGÀBA, DÍDẸ́RÙBANI, ÌHÀLẸ̀, ÌGBÓGUN-TINI, TÍ WỌ́N DOJÚKỌ ỌMỌ-ÌBÍLẸ̀-YORÙBÁ, TI ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TI YORÙBÁ
Àṣírí ti wá tú pátápátá báyi o! À ṣé àjọ tí ó sọ pé àwọn ń mojútó ètò ìlera ní àgbáyé (W.H.O), ni àjàkálẹ̀ àrùn tí ó njà wá ní Áfríkà báyi!
Ẹ gbọ́, kí a tún tún-un gbọ́, àwọn onímọ̀ ìwòsàn kan ní Áfríkà ti sọ fún ààrẹ Museveni ti ìlú Uganda pé, a ò lè gbẹ́kẹ̀ wa lé W.H.O mọ́! – àwọn gan-an ló nṣe’kú pa wá; wọn kò jẹ́ kí tọkùnrin tobìnrin lè ṣe bàbá ìkókó àti ìyá ìkókó mọ́!
Àṣírí yí tú níbi tí àwọn onímọ̀ nípa ètò ìwòsàn wọ̀nyí ti nsọ fún ààrẹ Musoveni, èyí tí a rí fọ́nràn rẹ̀ lórí ẹ̀rọ ayélujára X, wọ́n sọ ojú abẹ ní’kó pé W.H.O fún’ra rẹ̀ ló nṣe olùpín oríṣiríṣi àrùn káàkiri Áfríkà. Báwo ni wọ́n ṣe nṣe èyí?
Àwọn ló máa sọ pé àrùn kan ti dé o! Àwọn náà ló máa sọ pé abẹ́rẹ́ àjẹsára báyi ni kí àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí gbà! – bẹ́ẹ̀ kẹ̀ dẹ̀ ré, wọ́n á ti mọ̀ọ́-mọ̀ fí nkan tí ó lè ṣe’kú pa’ni sínú abẹ́rẹ́-àjẹsára náà, tàbí ohun tí kò ní jẹ́ kí àwọn tí ó bá gba ó lè tún bí’mọ mọ́!
Wọ́n sọ fún ààrẹ Musoveni pé, kò sí nkan tó nṣe wá ní Áfríkà! W.H.O ló nṣe wá! Kí a máṣe tẹ̀lé ọ̀rọ̀ wọn mọ́ tí a bá fẹ́ wà ní àláfíà! W.H.O gan-gan ni àrùn tí ó nṣe wá!
Nígbàtí ààrẹ Musoveni gbọ́ ọ̀rọ̀ yí, nṣe ló ṣe hàà! À ṣé W.H.O tí a ní kó fẹ́’ni lójú, òun gan-an ló fi ata sẹ́nu!
Àwa Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P), ẹ jọ̀wọ́, ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yí kí ó yé wa dáadáa, kí a máṣe rò pé àwọn kan wà tí wọ́n nṣètò ìlera fún àgbáyé: rárá o! Ọwọ́ ara wa la máa fi tún ọ̀rọ̀ wa ṣe!
Ohun tí ó tún wá ṣe pabambarì rẹ̀ báyi ni pé, àwọn onímọ̀ ìwòsàn wọ̀nyí, ọkùnrin àti obìnrin wọn sọ pé, nígbàtí W.H.O kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, nígbànáà l’ọhún, àdéhùn tí ó wà ni pé ÌMỌ̀RÀN gbígbà ni W.H.O wà fún – kí wọn gbà àwọn orílẹ̀-èdè ní Ìmọ̀ràn lórí bóṣenlọ nípa ọ̀rọ̀ Ìlera; ṣùgbọ́n, wọ́n ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyi, ọ̀rọ̀ W.H.O ti ndi ti Apàṣẹ-Wàá, èyí tí ó jẹ́ pé ó lòdì pátápátá gbáà sí agbára-ìṣèjọba-ara-ẹni tí orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan ní láti ṣe ìjọba-ara-rẹ̀.
Èyí túmọ̀ sí pé, ibi tí ọ̀rọ̀ W.H.O dé báyi, ó ti ndi pé ó fẹ́ẹ́ fi tipá mú àwọn orílẹ̀-èdè láti ṣe ohunkóhun tí ó bá ṣáà ti sọ – èyí tí ó já sí pé, W.H.O fẹ́ sọ ara rẹ̀ di kònkárí ìjọba tí yíò máa pàṣẹ lórí gbogbo àgbáyé!
Ní ìsiìyí ni ọ̀rọ̀ tí Màmá wa sọ láìpẹ́ yí á wá yé wa: Màmá òmìnira Yorùbá, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, sọ pé kí àwọn Ọ̀dọ́ I.Y.P ó ri dájú pé àwọn dáàbò bo agbára-ìṣèjọba-ara-ẹni D.R.Y
Ní’kóríta tí a dé lọ́wọ́lọ́wọ́ báyi, ẹ jẹ́ kí ó yé wa pé, kò sí nkan tí ó ga ju agbara-ìṣèjọba-ara-ẹni o! Ẹnikẹ́ni, tàbí àjọkájọ ní àgbáyé kò ní àṣẹ láti ti orí ìlú tàbí orílẹ̀-èdè tí ó bá ti jẹ́ aṣèjọba-ara-ẹni, ẹnikẹ́ni kò ní ẹ̀tọ́ tàbí àṣẹ kankan láti sọ fún irú orílẹ̀-èdè bẹ́ẹ̀ pé, yà sí’bí tàbí yà-s’ọhún!
Orílẹ̀-Èdè Aṣèjọba-Ara-Ẹni ni wá (Democratic Republic of the Yoruba); nítorí èyí, kí a jẹ́ kí ó yé wa pé W.H.O kò ní agbára lé wa lóri o! Ìjọba tó ga jùlọ pátápátá ní gbogbo nkan tí ó níṣe pẹ̀lú D.R.Y náà ni Ìjọba D.R.Y
A ò ní gba W.H.O, láyé, kó máa júwe ọ̀nà ìgbésí ayé wa fún wa!
A ti wá ri báyi, gbogbo kùrùkẹrẹ tí Bill Gates àti W.H.O jọ máa nṣe pọ̀! Kí á rántí pé láìpẹ́ yí ni ẹnikan sọ síta pé owó tí Bill Gates fi nṣàtìlẹ́hìn W.H.O ni kò tún sí irúfẹ́ rẹ̀. Nítorí èyí, W.H.O ni ẹṣin, Bill Gates ló mú ìjánu ẹṣin dání!