Ìròyìn orí ayelujara kan ti jẹ́ kí a mọ̀ nípa Bill Gates àti ẹ̀rọ satẹ́láìtì bíi ẹgbẹ̀rún lọ́na marun din láàdọ́rin tí ó ń pète-pèrò láti fi sí inú òfúrufú ní ọdún márun sí àkókò tí a wà yí, láti leè máa ṣe alamí àwọn ènìyàn ní àgbáyé.
Ìròyìn yí tẹ̀síwájú pé wọ́n máa fi ẹ̀rọ 5G sí ara àwọn satẹ́láìtì naa fun dídarí ìwà pẹ̀lú ìṣesí gbogbo ayé. Ara ètò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ìsàlẹ̀ rẹ̀, ní kí gbogbo ayé máa ná owó àìfojúrí lórí ayélujára, kí wọ́n sì máa darí oúnjẹ àti ètò abẹ́rẹ́ àjẹsára típátipá fún gbogbo ayé pátápátá.
Orílẹ̀ Èdè wa, Democratic Republic of the Yorùbá (D.R.Y) kò bá Bill Gates lọ́wọ́ nínú rádaràda yìí, torí màmá wa, Olóyè ìyá Ààfin Modúpẹ́ọlá Onitiri-Abiọla, tí Olódùmarè lò láti gba wa, ti jẹ́ kí á mọ òtítọ́ yìí lára àwọn àlàkalẹ̀ ìṣèjọba D.R.Y tí wọ́n gbé lọ́wọ́. Ìjọba orílẹ-èdè wa náà kò sì níí lọ́wọ́ nínú ohunkóhun tí yíò ṣe ìpalára fún ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P.)
Bill Gates wá ti sọ ara rẹ̀ di Ọlọ́run.
Nígbàtí a bá ti lé awon aláìnítìjú ajẹgàba Nàìjíría dànù kúrò lórí ilẹ̀ wa, tí àwọn adelè wa sì fi àlàáfíà wọlé sí oríkò ilé iṣẹ́ ìjọba wa ní àìpẹ́ yìí, tí a bẹ̀rẹ̀ síi rí ìfarahàn gbogbo iṣẹ́ tí àwọ́n adelé wa ti ń ṣe láti ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbẹ̀wá-ọdún-ó-lé-mẹ́rìnlélógún tí a ṣe ìbúra wọlé fún bàbá wa, Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọ́kọrẹ́ gẹ́gẹ́bí olórí ìjọba Adelé wá, gbogbo àgbáyé yíò wá ríi pé Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá kò ṣe fọwọ́ rọ́ sẹ́hìn láàrin àwọn orílẹ̀-èdè ayé yìí, nítorí gbogbo àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá ni a kún fún ẹ̀bùn, ògo àti ọpọlọ tó ta yọ ní àgbáyé. Àsìkò náà wọle dé tán.