Ìyàwó ilé kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Barkisu Sulaiman ní ọwọ́ tẹ̀ ní, Karaworo-Lokoja lórí wípé ó sọ ọmọ tuntun jòjòló, ọmọ òòjọ́ rẹ̀ sínú odò.
Obìnrin Barkisu yìí ni a gbọ́ pé, o ni oyún ọmọ náà fún ọmọ ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ̀ tì ń ṣáàrẹ̀, ìgbà tí ọkunrin ọmọ ọ̀dọ̀ náà gbọ́ pé ó lóyún fún òun, ó sọ fún wípé, kí ó lọ ṣẹ́ oyún ọmọ náà, tí ó sì sá lọ, obìnrin yi sọ pé ìdí nìyẹn tí òun fi lọ sọ ọmọ nù. Àṣírí ọ̀rọ̀ náà tú nípasẹ̀ ọ̀rẹ́ tí ó fi’nù hàn.
Màmá wa, ìyáàfin Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá tí sọ fún wa wípé, kò sì ohun tí ń jẹ́ ọmọ ọ̀dọ̀ ní Orílè-èdè Democratic Republic of the Yorùbá, (D.R.Y.), wípé, àparò kan kò ní ga ju kan lọ, gbogbo I.Y.P ló ma níṣẹ́ lọ́wọ́. Ọ̀kan lara ewu tí ó wà nínú ọmọ ọ̀dọ̀ nìyí o.
Irú ìwà apànìyàn báyìí kò ní wá’yé ní Orílè-èdè àwa ọmọ Olómìnira Tiwantiwa tí Yorùbá, nítorí ètò ìrọ̀rùn tí màmá wa Olóyè Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítìrí-Abíọ́lá tí ṣe àlàkalẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀ ní ọ̀kan ò jọ̀kan fún àwa Indigenous Yorùbá People, (I.Y.P.), tí ìtọ́jú to péye sì máa wà fún gbogbo ènìyàn, bẹ́ẹ̀ àwọn ìyàwó ilé tí kò bá ya ọ̀lẹ máa rí iṣẹ́ ṣe tí kì yóò sí àńtojúbọ’lé àti ìwà àìní ìtẹ́lọ́rùn mọ́ ní Orílè-èdè Democratic Republic of the Yorùbá, (D.R.Y.).