Bí irọ́ bá lọ lógún ọdún, ọjọ́ kan ni òtítọ́ yóò bá. Eléyìí ló bí ọ̀rọ̀ òtítọ́, tó ti ẹnu obìnrin aṣojú orílẹ̀ èdè Adúláwọ̀ kan jáde, tí a rí lórí ayélujára.
Ọ̀rọ̀ obìnrin yìí ló dá bíi ọ̀rọ̀ tí màmá wa, Ìyá Ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla sọ nípa ìwà àrékérekè àwọn òyìnbó láti ọdún mọ́ ọdún. Oríṣiríṣi ìwà búburú ló kún ọwọ àwọn amúnisìn yìí, àgàbàgebè, ìwà ejò paramọ́lẹ̀, íjẹgaba àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Màmá MOA tí rí gbogbo àṣírí wọn tán ló jẹ́ kí wọ́n sọ wípé aò ni kúrò ní oko ẹrú kan, kí a tún bọ́sí òmíràn.
Ohun tó jẹ́ ìyálẹ́nu ni pé, obìnrin aṣojú yi, ṣe alábápàdé àwọn ọmọ Adúláwọ̀ méjì kan tí wọ́n jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìṣúná owó, ṣùgbọ́n wọ́n jẹ́ opè nípa àwọn ohun tí wọ́n béèrè lọ́wọ́ wọn. Obìnrin náà sì jẹ́ ọlọ́gbọ́n àti akíkanjú ólóye, ó dáhùn gbogbo ìbéèrè tí wọn béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.
Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í ńṣí aṣọ lójú eégún àwọn aláwọ̀ funfun, nípa ọ̀nà tí wọ́n gbà kó àwa Adúláwọ̀ l’ẹ́rú àti ẹrù títí di òní.
Ó ní wọn bẹ̀rẹ̀ nípa àpérò tí babańlá wọn ṣe ní ìlú Berlin, níbẹ̀ ni wọ́n ti ṣe ìjíròrò fún oṣù mẹ́ta gbáko, tí wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ bí wọ́n ṣe máa ṣe ètò ìṣàkóso gbogbo ilẹ̀ Adúláwọ̀. Bí wọn ṣe pinnu àti ṣẹ́gun gbogbo ilẹ̀ Adúláwọ nìyẹn ̀ àti kí wọn máa jẹgàba lórí wa títí láé.
Lórí ìpinnu burúkú yí ni wọ́n dúró leé tí wọ́n sì ndarí gbogbo ilẹ̀ Adúláwọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kò sì dẹ́kun ìwà ìjẹgàba náà bí a ṣe nsọ yíì.
Gbogbo ìwà àrékérekè yí ni wọ́n ń hù láti má kó ọrọ̀ wa ní Áfríkà. Ìpinnu tí àwọn babańlá wọn ti ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀ ni ìlù Berlin ni wọ́n ń tẹ̀lé.
Ọpẹ́lọpẹ́ ìyá Ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla tí wọn tí tú àkàrà kúrò nínú epo agbada wọ́n. Ní kété tí Olódùmarè gbé wọn kalẹ̀ fún òmìnira àwa ọmọ Aládé ni ojú wa ti là sí òtítọ́ yí.
Obìnrin Adúláwọ̀ yíì, tó tún jẹ́ aṣojú orílẹ̀ èdè rẹ lo tún sọ ọ̀rọ̀ òtítọ́ yìí jáde fún àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n isunná owó tí wọ́n yangàn lórí irọ́.
Ara ìdi pàtàkì tí a fi ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè àti Màmá MOA nìyí, fún ìtúsílẹ̀ àwa ọmọ Yorùbá kúrò lọ́wọ́ àwọn apanilẹ́kún jayé òyìnbó.
A ti bọ́ títí láé láti ogúnjọ́ oṣù Bélú, ẹgbàá ọdún ó le méjìlélógún tí àti ṣe ìkéde òmìnira wa.Ìṣèjọba-ara-ẹni sì ti bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ kejìlá oṣù Igbe, ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rìnlélógún pẹ̀lú ìdarí olórí adelé wa, bàbá wa Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọkọrẹ.
A kí gbogbo àwa ọmọ aládé pé a kú oríire, ìyá ìrọ̀rùn lóbádé ti parí iṣẹ́ ìtúsílẹ̀ orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) ìmúrasílẹ̀ àjọyọ̀ ńlá nì gbogbo ìpínlẹ̀ méjèèje ló kù báyìí. Ẹ jẹ́ ká jáde lọ́pọ̀ yanturu nígbà tí ipè náà bá ti dún.