Lára àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣe kókó tí màmá wa, Modupẹọla Onitiri-Abiọla (Olóyè Ìyá-Ààfin) bá gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) ti orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y) sọ láìpẹ́ yí, màmá wa MOA sọ̀rọ̀ nípa ilé iṣẹ́ kan tí wọ́n ń pè ní Sẹ̀gilọlá Resources Operating Limited (SROL) tó nwa góòlù ọmọ Yorùbá ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y).
MOA fi léde wípé, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ bá wà ní àyíká ilé iṣẹ́ yí, ẹ ya fọ́tò gbogbo àyíká ní agbègbè tí wọ́n ti nwa góòlù náà, a fẹ́ mọ̀ bóyá wọ́n ti ba agbègbè ibẹ̀ jẹ́ pẹ̀lú bí wọ́n ṣe nwa góòlù náà.
Màmá wa MOA sọ pé gbogbo I.Y.P ti D.R.Y tó ngbé ní agbègbè ibi tí Segilọla ti nwa góòlù yí, kíni àwọn ìrírí yín, láti ìgbà tí wọ́n ti nwa góòlù níbẹ̀? ṣé orí máa nfọ́ yín? tàbí ara máa nro yín, látàrí wíwa góòlù tí wọ́n nṣe níbẹ̀? báwo ni nkan tí Segilọla nṣe ní agbègbè yẹn, irú àkóbá wo ló nṣe fún àgọ́ ara yín? ṣé ó máa nṣe àkóbá fún bí ọkàn yín ṣe nṣiṣẹ́?
Ohunkóhun tí ó wù kó jẹ́, ẹ jẹ́ kí ìṣàkóso-adelé D.R.Y ó mọ̀! ṣé ó ní irúfẹ́ òórùn tí ẹ máa ngbọ́ ni, nípasẹ̀ bí wọ́n ṣe nwa góòlù níbẹ̀? tàbí kẹ̀, bóyá láti ìgbà tí wọ́n ti nwa góòlù ọ̀ún, ṣé ó ní bí àwọn ọmọ tí wọ́n bá bí ní agbègbè yẹn, ṣé ó ní nkan tí ó máa nṣe wọ́n? Inkan-k’inkan tí ìbáà wù kó jẹ́, a fẹ́ mọ̀. Màmá sọ pé àwọn nkan wọ̀nyẹn, D.R.Y máa gbe jáde sí àgbáyé.
Màmá ní, wọ́n máa kàn sí ilé iṣẹ́ yí, tí wọ́n bá wá kàn sí wa padà, tí wọ́n bá jọ sọ̀rọ̀, ohun tí wọ́n bá sọ, màmá ní àwọn máa jẹ́ kí àwa I.Y.P mọ̀.
Nítorí náà, a fẹ́ kí ó yé gbogbo ẹ̀yin tí kò tíì yé wípé, Yorùbá ti kúrò lára ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà láti ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbàáọdúnóléméjìlélógún, bẹ́ẹ̀ ni a sì ti ṣe ìbúra wọlé fún olórí adelé wá bàbá wa Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọkọrẹ ní ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbàáọdúnólémẹ́rìnlélógún.
Ní báyìí, a ti di orílẹ̀ èdè aṣàkóso ara ẹni, kò sí ààyè fún ayé fàmílétèntutọ́ ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá, àwọn àlùmọ́ọ́nì tí Olódùmarè fún wa, fún ìgbá’yé gbádùn gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá ni, kìí ṣe fún àwọn kan, tàbí fún àwọn ìdílé kan, nítorí pé bákan náà ni gbogbo wa ní orílẹ̀ èdè D.R.Y.
Ẹ máṣe gbàgbé: èkíní: ẹ ya fọ́tò agbègbè tí Segilọla ti nwa góòlù, bóyá wọ́n ti ba agbègbè yẹn jẹ́, Màmá sọ pé D.R.Y fẹ́ mọ̀! Èkéjì, kíni ìrírí ẹ̀yin tí ẹ ngbé ní agbègbè yẹn láti ìgbà tí wọ́n ti nwa góòlù náà.
Ẹ fi gbogbo nkan wọ̀nyí ránṣẹ́ sí ìṣàkóso-adele: