Ọ̀rọ̀ Bill Gates kòì tíì tán o! Bílíọ́nù mẹ́ta dọ́là, ó dín ní igba-mílíọ̀nù ni ó ndà sí ìlú agbésùnmọ̀mí nàìjíríà báyi. Wọ́n ti nkó àwọn dókítà àti àwọn olùtọ́jú aláìsàn (nọ́ọ̀sì) kúrò ní nàìjíríà.
Òfin pé kí wọ́n máa yọ ara àwọn èèyàn – ẹ̀dọ̀, ìfun, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, ti wà nílẹ̀ o! Òun ló fún wọn ní òfin yẹn o! Ọ̀nà àti pa ìran aláwọ̀dúdú run ni o!
Gbogbo àwọn tó wúlò ní ilẹ̀ Yorùbá ni wọ́n ti kó kúrò nílé tán! Wọ́n wa sọ àwọn tó kù di aláìrínkan ṣe – jàndùkú, amugbó, ọmọ-ìta, aṣẹ́wó, oníjìbìtì; àwọn tí kò lè jóko kí wọ́n ronú, àwọn nkan yẹn ni wọ́n gbé lé wọn lọ́wọ́.
Àwọn tí wọ́n pe ara wọn ní Ọba ní ilẹ̀ Yorùbá ni wọ́n nlò, láti fi ba ilẹ̀ Yorùbá jẹ́.
Àwọn ọmọ-àlè ilẹ̀ Yorùbá, afẹ́nifẹ́bi tó npe’ra wọn ní afẹ́nifẹ́re, àwọn tó pe’ra wọn ní olórí (elite), – gbogbo wọn ni wọ́n nlo láti fi ba ilẹ̀ Yorùbá jẹ́.
Ọgbọọgbọ́n ni àwọn òyìnbó amúnisìn wọ̀nyí, fi nba ìlú-onílu jẹ́; tí wọ́n dẹ̀ fẹ́ lò láti gba ilẹ̀ Yorùbá. Ọwọ́ àwọn òyìnbó yí ni oríṣiríṣi ọgbọ́n àrékérekè àṣìtáánì wà. Látàrí kí wọ́n lè jogún ilẹ̀ wa.
Àwọn tí wọ́n pe’ra wọn ní Olówó ní ilẹ̀ Yorùbá, tí wọn ò ní’rònú, ara àwọn tí òyìnbó nlò náà nìyẹn, àgàgà àwọn Fúlàní tí ò tilẹ̀ ní ilẹ̀-ajogúnbá láarín nàìjíríà wọn, àwọn náà jẹ́ irin-iṣẹ́ lọ́wọ́ òyìnbó fún dídojú kọ ìran Yorùbá! Ṣé a ti wá ri báyi pé àwọn òyìnbó amúnisìn gan-gan-gan ni baba-ìsàlẹ̀ ọ̀tá Yorùbá.
Ìjẹgàba tí wèrè Nàìjíríà ṣì jẹ gàba sórí ilẹ̀ wa ló jẹ́ kí èyí ó ta bá wa.
Ọmọ Yorùbá, ẹ jẹ́ ká dìde, gbogbo ohun tí ó báa máa gbà, pátá, ni kí á fun o, kí á gba ara wa pátápá kúrò lọ́wọ́ amúnisìn; ẹ ṣáà jẹ́ kí á máa fi gbogbo ara tẹ̀lé àṣe àwọn ìjọba-adelé orílẹ̀-èdè wa, Democratic Republic of the Yoruba, pẹ̀lú ìtọnà láti ọ̀dọ̀ Ìránṣẹ́ tí Olodùmarè rán sí wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá.