Ọmọ Yorùbá kan tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Ṣèyí Ọ̀jẹ́labí, ní ó ti ṣe ohun ìrìn fún àwọn tí ó ní ìpèníjà ojú o, láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè rìn ní agbègbè wọn láì kọlu ohunkóhun.
❗PÀJÁWÌRÌ FÚN ÀÀBÒ❗KÁÀKIRI GBOGBO ÌPÍNLẸ̀ YORÙBÁ TÍTÍ DÉ OLD Ọ̀YỌ́ EMPIRE, Ẹ MÁA YA FỌ́TÒ FÚLÀNÍ, OLỌ́PA, OLÓṢÈLÚ, SÓJÀ, TÍ Ẹ BÁ FURA SÍ ÌRÌN ÀTI ÌṢESÍ WỌN NÍ AGBÈGBÈ YÍN. KÍ Ẹ FI ṢỌWỌ́ SÍ BÀBÁ ÌJÌNLẸ̀ +905367341665 (WHATSAPP). (ÌKÉDE… Pín Sórí Àgbàgbé X (Twitter)Ṣùgbọ́n kìí wá nṣe ọ̀pá igi o, ti irinṣẹ́ ìgbàlódé ni, tí ẹni tí ó nlòó máa mú dání, á sì rọra nàá síwájú; tí ó bá ku díẹ̀ kí ó kọlu nkan, ẹ̀rọ náà á dún, èyí tí ẹni yẹn á fi mọ̀ pé òun ti fẹ́ dé ibi tí òun ti lè kọlu nkan.
Ìnkan ayọ̀ tí ó tún wà níbẹ̀ ni pé, Ọ̀gbẹ́ni Ọ̀jẹ́labí sọ pé èyí tí ó pọ̀jù nínú ohun-èlò tí òun fi ṣe ẹ̀rọ yí, láti àyíká rẹ̀ ni ó ti rí wọn.
Ó ti bẹ̀rẹ̀ náà nìyẹn; ṣebí ohun tí Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá ti nsọ nìyẹn, pé ògo wà lára ọmọ Yorùbá, wọ́n dẹ̀ máa rí ogo náà lò ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá.
Orí ẹ̀rọ ayélujára ni a ti rí ìròhìn náà, èyí tí ó mú ìnú ènìyàn dùn, pé, ní àìpẹ́, ní kété tí Olódùmarè bá ti ràn wá lọ́wọ́ tí a tí rí ẹ̀hìn àwọn ajẹgàba lórí ilẹ̀ wa, irúfẹ́ àwọn ọ̀dọ́ bí Ṣèyí Ọ̀jẹ́labí ni yíò pẹ̀lú àwọn tí ó máa gbé ògo ilẹ̀ Yorùbá ga síi.
Ká Ìròyìn Síwájú sí:
- ÀMERICA TI F’ỌWỌ́ SÍ ỌSIN ADÌẸ LÁTI YÀRÁ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ÌMỌ̀ ÌJÌNLẸ̀
- ẸGBẸ̀RÚN MÁRUN NÁÍRÀ NI ÀWỌN ARÁ ÌLÚ NÀÌJÍRÍÀ FI DA’LẸ̀ ARA WỌN !
- ÀNFÀÀNÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TI YORÙBÁ
- ÒFÉGÈ ÌRÀNLỌ́WỌ́: ọmọ Yorùbá, máṣe yà sí’bẹ̀ !
- ỌMỌKÙNRIN KAN ṢE’KÚ PA BÀBÁ TÓ BÍ BÀBÁ RẸ̀ NÍTORÍ OKO
- JAMIU ABÍỌ́LÁ NHU ÌWÀ ỌMỌ ALÈ
- ÌLÙ NÀÌJÍRÍÀ TI FI ŃKÀN ṢE ÀWỌN ÈWE
- ṢÍṢE ARA LÓGE NÍ ILẸ̀ YORÙBÁ