Ọmọ Bìní kan lórí ẹ̀rọ ayélujára ló ṣe àlàyé bí ibi tí wọ́n npè ní Nàíjíríà kò ṣe jẹ́ orílẹ̀-èdè, àti pé kíkó tí wọ́n kó Nàìjíríà jọ, gẹ́gẹ́bí ilé-iṣẹ́ ìdókòòwò ni – Royal Niger Company, èyí tí ó di Unilever lóni.
Èyí fi hàn wá, gedegbe, bí ó ti ṣe pàtàkì kí á wádi gbogbo ilé-iṣẹ́ tí ó wà ní Orílẹ̀-Èdè Democratic Republic of the Yorùbá (D.R.Y), kí á máṣe kó wàhálà mọ́ra.
Bẹ́ẹ̀ náà ni Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá ti ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ alaye bí ọ̀rọ̀ Nàìjíríà ṣe rí àti bí ó ṣe jẹ́, fún wa, lóríṣiríṣi ọ̀nà; nítorí náà, a ò lè sọ pé a ò mọ gbogbo nkan wọ̀nyí; ṣùgbọ́n a ní lati rán ara wa létí, nígbà gbogbo, gẹ́gẹ́bí Màmá wa ṣe máa nsọ fún wa pé, a ò ní ti oko ẹrú kan bọ́ sí èkejì.