Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on XBẹ́ẹ̀ ni! Ohun nlá l’ó ṣẹ’lẹ̀, ní Ọjọ́ Kéjìlá, Oṣù kẹ́rin, èyíinì, Oṣù Ìgbé; ní ọdún 2024 yí (ẹgbàá ọdún, olé mẹ́rin-lé-l’ogún).
Ohun tí ó ṣẹ’lẹ̀ ni wípé, ILẸ̀ YORÙBÁ, èyí tí ó jẹ́ wípé, tẹ́’lẹ̀, a mọ̀ọ́ sí àwọn Ìpínlẹ̀ Èkó, Ìpínlẹ̀ Ògùn, Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Ìpínlẹ̀ Ondo, Ìpínlẹ̀ Èkìtì; Ìpínlẹ̀ Kwara, àti apákan ìpínlẹ̀ Kogí, tí ó ti wà tẹ́’lẹ̀ ní ara ìlú Nigeria; ṣùgbọ́n ní ọjọ́ yi, ọjọ́ kéjìlá, oṣù kẹ́rin, ọdún 2024 yí, Ṣe ohun tí a npè ní ÌPÓLONGO ÌṢÈ’JỌBA ARA RẸ̀ gẹ́gẹ́bí orílẹ̀-èdè OLÓMÌNIRA ARA RẸ̀, èyí tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, tí ó sì ṣe ìbúra-wọ’lé fún Olórí Ìjọba Rẹ̀ ní ìlú Ìbàdàn, tí nṣe Olú-Ìlú orílẹ̀-èdè tuntun yí, tí ó jẹ́ orílẹ̀-èdè tí ó tuntun jùlọ ní gbogbo àgbáyé l’oní; bẹ́ẹ̀ náà ni ó jẹ́ orílẹ̀-èdè aṣè’jọba-ara-ẹni kárun-dín-l’ọgọ́ta ní ilẹ̀ Afríkà!
Èyí tú’mọ̀ sí wípé, gbogbo ilẹ̀ Yorùbá tí a kà yí, kò SÍ NÍ ARA NIGERIA MỌ́ l’ati ọjọ́ kéjìlá, oṣù kẹ́rin, ọdún 2024 yí; ṣùgbọ́n, njẹ́ ìwọ gẹ́gẹ́bí ọmọ Yorùbá mọ eléyi?
Má ṣe jẹ́ kí ìwà ìpánle tí Nigeria nhù – tí wọ́n fi ipá dúró l’orí ilẹ̀ Yorùbá, l’ẹhìn ìgbà tí Yorùbá ò ti sí ní abẹ́ Nigeria mọ́; máṣe jẹ́ kí ìwà ìpánle yí kí ó mú ọ ṣàìmọ̀ wípé, loótọ́, àti ní òdodo Yorùbá ti dá dúró, a sì ti kúrò pátápátá l’abẹ́ Nigeria!
Má ṣe jẹ́ kí eléyi kí ó ṣe ọ́ ní kàyéfì! Ohun tí ó hàn sí’wajú gbogbo àgbáyé ni, títí dé Àjọ àgbáyé (United Nations), tí wọ́n dẹ̀ ti fi orúkọ olórí ìjọba wa sí’lẹ̀ ní’bẹ̀!
Ẹrú tí a bá ti tú sí’lẹ̀, ṣùgbọ́n tí kò mọ̀ wípé a ti tú òun sí’lẹ̀, oko ẹrú l’ó ṣì máa wà!
Ẹ má ṣe dàbí àwọn dúdú amẹ́ríkà tí wọn wà ní oko ẹrú.
Kà Atẹ̀jade: Yorùbá, Orílẹ̀-Èdè Tún-tún Ní Àgbáyé, Olómìnira Tiwantiwa 55th Ní Áfíríkà
Ka Ìròyìn: Àwa Ojúlówó Ọmọ Òmìnira Yorùbá Àtàtà Kìí Ṣe Ajìjàgbara Mọ́ Ooo
Nígbàtí wọ́n tú wọn sí’lẹ̀ ní ọdún 1863, ọ̀pọ̀l’ọpọ̀ wọn ni kò mọ̀ wípé wọ́n ti tú wọ́n sí’lẹ̀, tí wọn sì wà l’oko ẹrú sí’bẹ̀!
Bẹ́ẹ̀ ni! Ènìyàn ṣì lè wà l’oko ẹrú nígbàtí a ti yọọ́ kúrò nínú oko ẹrú náà. Àìmọ̀ l’ó nfa eléyi! Má ṣe wà ní aláìmọ̀ o! Yorùbá kò sí l’abẹ́ Nigeria mọ́!
L’ati ọjọ́ kéjílá oṣù kẹ́rin, ọdún yí (2024) ni a ti gbe ìjọba orílẹ̀-èdè Yorùbá wọ’lé ní’lú Ìbàdàn, kìkìdá wípé àwọn gómìnà tí ó ti wà tẹ́’lẹ̀ nígbàtí a ṣì wà l’abẹ́ Nigeria ni wọ́n máa kúrò l’orí àlééfà wa láìpẹ́ láìjìnà yí.
Má ṣe dàbí àwọn dúdú Amẹ́ríkà, tí wọ́n ti tú wọn sí’lẹ̀ nínú oko ẹrú l’ati 1863 ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ wípé wọn kò mọ̀ – èyíinì, ọ̀pọ̀l’ọpọ̀ wọn!
Wọ́n ṣì nṣe iṣẹ́ ẹrú fún àwọn ọ̀gá wọn, bí ó ti’lẹ̀ jẹ́ wípé a ti tú wọn sí’lẹ̀ nínú oko ẹrú l’ati ọjọ́ kíní oṣù kíní, ọdún 1863, ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀, àti wípé àwọn ọ̀gá t’ó mú wọn l’ẹrú kò tilẹ̀ fẹ́ kí wọ́n mọ̀, tàbí wípé kí wọ́n gba ìtúsí’lẹ̀ bí wọ́n ti’lẹ̀ mọ̀!
Àf’ìgbà t’ó di ọjọ́ kọ́kàn-dín-l’ogún oṣù kẹ́fà ọdún 1865 – ọdún méjì-àbọ̀ l’ẹyìn tí wọ́n ti ní ẹ̀tọ́ l’ati máa lọ kúrò nínú oko ẹrú, ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bọ́ nítorí wípé nígbànáà ni ìròhìn dé ọ̀dọ̀ wọn wípé “kò sí oko ẹrú mọ́ o!” K’á ní wípé wọ́n ti gbọ́ ní ọdún-méjì-àbọ̀ s’ẹhìn ní’gbà náà ni, wọn ìbá ti bọ́ pátápátá!
Àwọn ọmọ Yorùbá kan kò mọ̀ wípé ilẹ̀ Yorùbá kò sí l’abẹ́ Nigeria mọ́! Àwọn kan mọ̀, ṣùgbọ́n wọn kòì tíì gbàgbọ́! Ẹ má ṣe ṣ’iyèméjì! Yorùbá kò sí l’abẹ́ Nigerià mọ́!
Ka Ìròyìn: Ìkéde Pàtàkì Fún Gbogbo Àgbè Nípa Oríṣiríṣi Èso Ọ̀gbìn Aláyé D’èrú
Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ wà ní ìpínlẹ̀ Èkó, ẹ ò sí l’abẹ́ Nigeria mọ́ o! gbogbo ẹ̀yin tí ẹ wà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ẹ ò sí l’abẹ́ Nigeria mọ́ o! Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ wà ní ìpínlẹ̀ Ògùn, ẹ ò sí l’abẹ́ Nigeria mọ́ o!
Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ wà ní ìpílẹ̀ Ọ̀ṣun, ẹ ò sí l’abẹ́ Nigeria mọ́ o! Gbogbo ẹni tí ó wà ní ìpínlẹ̀ Ondo, ẹ ò sí l’abẹ́ Nigeria mọ́ o! Gbogbo ẹni tí ó wà ní Ìpínlẹ̀ Èkìtì, ẹ jọ̀wọ́, kí ẹ gbọ́ dáadáa, ẹ ò sí ní abẹ́ Nigeria mọ́ o!
Yorùbá ti dádúró gẹ́gẹ́bí orílẹ̀-èdè ti ara rẹ̀! A ti ní Olórí Ìjọba Yorùbá, wọ́n dẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ wọn nì ìlú Ìbàdàn! Ìgbà díẹ̀ l’ó kù tí Ṣèyí Mákindé máa fi já’de kúrò ní Secretariat (oríkò ilè-iṣẹ Ìjọba) ní ìlú Ìbàdan o!
Ẹyin tí ẹ wà ní Ìpínlẹ̀ Kwara, ẹ ò sí l’abẹ́ Nigeria mọ́ o! Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ tiwa ó dàbí ti àwọn dúdú amẹ́ríkà, tí wọ́n ti tú wọn sí’lẹ̀ l’ati 1863, ṣùgbọ́n tí wọ́n ṣì nṣ’iṣẹ́ ẹrú títí di 1865!
Ka Ìròyìn: Ilẹ̀ Yorùbá, Agbára Ọ̀dọ́
Gbogbo ọmọ Yorùbá, a ò sí l’abẹ́ Nigeria mọ́ o! L’ati ọjọ́ kèjìlá, oṣù kẹ́rin ọdún yí (2024) ni a ti gbé ìjọba Yorùbá, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, ni a ti gbé ìjọba rẹ̀ wọ’lé, tí àjọ àgbáyé (United Nations) àti gbogbo àgbáyé ti mọ̀ si! Ìjọba Nigeria ni wọn ò jẹ́ kí ẹ gbọ́ o!
Gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀gá ẹrú ní apákan america kò ṣe jẹ́ kí àwọn ẹrú abẹ́ wọn gbọ́ ní 1863! tí ó fi jẹ́ wípé 1865 ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọ́! Ẹ jọ̀wọ́, gbogbo ọmọ Yorùbá, ẹ má ṣe jẹ́ kí tiwa ó rí bẹ́ẹ̀ o!
Ẹ jẹ́ kí á ṣe àjọyọ̀ òmìnira wá báyi ni o! Ẹ má ṣe jẹ́ kí ó di ọjọ́ iwàjú bíi ti àwọn dúdú america!
Gbogbo ẹyin tí ẹ wà ní ilẹ̀ Yorùbá ti ìpínlẹ̀ Kogí! Ilẹ̀ Yorùbá ní Kogí kò sí l’abẹ́ Nigeria mọ́ o! Gómìnà t’ó wà ní ìlú Lọ́kọ́ja kò ní pẹ́ kúrò ní’bẹ̀, nítorí ìjọba Yorùbá ti bẹ̀rẹ̀ o!