Èdùmàrè máṣe jẹ́ kí á fi ìpìlẹ̀ ayé wa lé orí irọ́! Tí kìí bá ṣe pé Ọlọ́run Olódùmarè tí ó gba Ìran Yorùbá sílẹ̀ nípasẹ̀ iṣẹ́ ribiribi tí Ó lo Ìyá wa, Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá fún, Kínni à bá ma wí? 

Ẹ jẹ́ kí á wo iye ọdún tí a ti wà nínú Irọ́ kàbìtì tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Nàìjíríà! Wọ́n sọ fún wa pé Orílẹ̀-Èdè wa nìyẹn, láì mọ̀ pé kìí ṣe Orílẹ̀-Èdè, dé’bi tí yíò ti wá jẹ́ orílẹ̀-èdè wa! Gbogbo àgbáyé sì gba eléyi gbọ́! INÚ irọ́ nlá yí ni wọ́n bí àwọn bàbá ti wa sí! Àwọn náà wá bí wa sínú ìgbé-ayé irọ́ náà: tí a npe nàìjíríà ní orílẹ̀-èdè wa, láì mọ̀ pé kìí ṣe orílẹ̀-èdè!

Ṣùgbọ́n tìtorí pé wọ́n ti mú wa gbàgbọ́ pé orílẹ̀-èdè wa nìyẹn, a nf’ara da gbogbo ìyà tí ó njẹ wá nínú àdàmọ̀dì tí wọ́n pè ní Orílẹ̀-Èdè ọ̀ún: bẹ́ẹ̀ kẹ̀ sì ré, àtọwọ́dá ni nàìjíríà kìí ṣe orílẹ̀ èdè. 

Lára àwọn ọ̀rò tị́ Màmá wa ti ńbá wa sọ tẹ́lẹ̀ ní wọ́n tún gbé síta fún gbogbo àgbáyé ní àìpẹ́ yí, tí wọ́n sì ṣe àlàyé le lórí fún wa.

Èyí tí ó ṣe pabambarì rẹ̀ ni pé àwọn tí wọ́n mọ̀ pé Nàìjíríà kìí ṣe orílẹ̀-èdè, wọ́n sì dákẹ́.

Wọ́n pa irọ́ yí dé’bi pé, bí ọdún ṣe nyí lu ọdún, ó dií-pé ọmọ Yorùbá kò wá mọ̀ pé Yorùbá ni orílẹ̀-èdè ti òun! Kò mọ̀ pé orí-ilẹ̀ tí wọ́n ti ní Èdè kan, Àṣà kan àti Ìtàn kan ni wọ́n ń pè ní Orílẹ̀ èdè.

Gbogbo ìyà tí àwọn amúnisìn (ti inú-ilé àti ti ìta) fi njẹ wá ni a ṣáà nf’aradà torí pé wọ́n ti ko sí ọpọlọ wa pé Nàìjíríà ni orílẹ̀-èdè wa, tí àwa náà wá rò pé a máa máa ba yí lọ! Àà, Èdùmàrè máṣe jẹ́ kí a bá irọ́-àti-ìyà yí!

Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yí kí ó yé wa dáradára, kí á le mọ adúrú ìkà ayébáyé tí àwọn amúnisìn ti ṣe fún wa, kí á sì le fi yé àrọ́mọd’ọmọ wa, pé, láyé, irú ìgbèkùn bẹ́ẹ̀ kò tún gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ sí Ìran Yorùbá!

Nítorí èyí, gbogbo àwọn tí ó pe’ra wọn ní ọba, tí wọ́n nṣe àtìlẹ́yìn fún agbésùmọ̀mí nàìjíríà, a ò gbọdọ̀ fi ojú rere wò wọ́n! A gbọ́dọ̀ rí irúfẹ́ wọn bíi Ọ̀TÁ ÌRAN YORÙBÁ; bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo àwọn tí wọ́n pe’ra wọn ní ‘olóṣèlú,’ tí wọ́n njẹgàba báyi s’orí ilẹ̀ Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), Ọ̀TÁ ÌRAN YORÙBÁ NI WỌ́N! Ẹ̀ṢẸ̀ TÍ KÒ NÍ ÌDÁRÍJÌ NI WỌ́N Ń DÁ!

Ẹ̀yin tí ẹ ka ara yín sí ọ̀mọ̀wé, ọ̀làjú, àbí bọ̀rọ̀kìní, tí ẹ lòdì sí òmìnira ọmọ Yorùbá, ìgbèkùn Nàìjíríà tí ẹ npàdí-àpò-pọ̀ mọ́ yẹn, kí ó jẹ́ ti yín àti ìdílé yín títí ayé, àwa Ìran Yorùbá ti bọ́!

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal