Tí Ọmọdé Bá Ńjẹ Èèwọ̀ Tí Ẹnìkan Ò Bi Í, Bó Pẹ́ Bó Yá, Ohun Tí Ńbi’ni Ò Ní Ṣàì Bi’ni
Òwe Yorùbá
“Mo kí gbogbo ọmọ Yorùbá, lọ́kùnrin, lóbìrin, lọ́mọdé, lágbà, lárúgbó.
Gbogbo ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P) tí ó jẹ́ oníṣòwò, olókòwò, àti oníṣẹ́-ọwọ́, ẹ máa gbáradì, ìjọba wa ti bẹ̀rẹ̀.
“Lóni, mo fẹ́ sọ àwọn ọ̀rọ̀ àṣírí kan fún yín; mo dẹ̀ máa mẹ́nu ba àwọn kan tí wọ́n jẹ́ olórí nínú ìlú nàìjíríà lọ́hun.
Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X” Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ nṣe rádaràda, tí ẹ rò pé ẹ le dí Yorùbá lọ́wọ́, a nṣe àkọsílẹ̀ gbogbo ohun tí ẹ nṣe. Gbogbo ìwà agbésùnmọ̀mí tí ẹ nhù, àti ìwà ìjẹgàba, àkọlù, fífi ipá dúró sórí ilẹ̀ wa, ìhalẹ̀-mọ́’ni, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ẹjọ́ tí ilé-ẹjọ́ àgbáyé kò dá rí, tí kò sì gbọ́ rí, ó máa gbọ, ó dẹ̀ máa da – lórí yín.
Gbogbo ọ̀ràn tí ẹ ndá, ẹ máa sán! A nṣọ́ yín ní gidi. Aà fẹ́ ẹ̀rí tí ó jẹ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́wa tàbí ogún ọdún péré ni ẹ máa lò lẹ́wọ̀n; ju bẹ́ẹ̀ lọ ni. Ibi tí ẹ jọ’ra yín lójú dé ni ìparun yín máa dé.
“Gbogbo I.Y.P, mo fẹ́ kí ẹ farabalẹ̀, láti gbọ́ ọ̀rọ̀; tórí àwọn wọ̀nyí, wọ́n nṣe oríburúkú; wọ́n nṣe ìpàdé.
“Ẹ nṣe ìpàdé pé ẹ fẹ́ pa tani? Ẹẹ̀ pá mí: gbogbo ohun tí ẹ ní ló máa kú. Ẹ́ẹ̀ lè rí wa pa. Ẹẹ̀ lèrí àwọn adelé pa. Àfi kí gbogbo okun tí ẹ ní kí ó kú lójijì. Kílódé!?
“Mo wá wòó wípé, àwọn ará ibíi, tí wọ́n fi ní ọpọlọ yí? I.Y.P, ẹ máa gbọ́ àṣírí tí ẹ ò gbọ́ rí nípa àwọn ènìyàn wọ̀nyí.
Àkọ́kọ́, mo fẹ́ kí àwọn nkankan kó yé wa. Oko ẹrú ni Nigeria – ìlú tí kò lédè, tó jẹ́ èdè àjèjì ni wọ́n nsọ. Olódùmarè ṣe ẹ̀dá Yorùbá, wípé a kò gbọ́dọ̀ wà lábẹ́ ẹnikẹ́ni. Nínú ìtàn wa ni a ti gbọ́ eléyi. Ọlọ́run ló gbé wa jóko sorí ilẹ̀ wa – ìtàn wa fi èyí hàn wá.
Ọlọ́run ló fún wa ní àlàkalẹ̀ (blueprint) wa, ẹ̀yin kan wá sọ wípé ẹ ò ní jẹ́ ká ṣèjọba! Níbo lẹ ti rí irú ìrònú yẹn? Àwọn ìpàdé wèrè tí ẹ nṣe, gbogbo fídíò rẹ̀ pátá ni a nrí. Ìgbéraga yín ju ti àṣìtáánì lọ. Ẹ̀ẹ́ sùn, ìgbà tí ẹ bá máa jí, wọ́n á sọ ọgbà ẹ̀wọ̀n tí ẹ wà fún yín.
“I.Y.P, mo fẹ́ ṣe àlàyé kan fún wa, mò dẹ̀ fẹ́ kí á fi ara balẹ̀ gbọ dáadáa. Àwọn ará ibíi, wọ́n nṣe ìpàdé, wọ́n nkó’ra wọn jọ láti ṣe’kú pa’ni. Àkọ́kọ́, mo fẹ́ sọ fún ọmọ Yorùbá, àwọn àláyé kan tí mo máa ṣe fún yín, mi ò ní bọ̀wọ̀ fún àwọn kan; nítorí, lẹ́hìn àpọ́nlé, àbùkù ló kù.
Alábùkù ni wọ́n. Mo máa kàn wọ́n lábùkù. Nítorí wọ́n pe’ra wọn jóko, pé àwọn fẹ́ pa tani? Àwọn tí mo máa pè yí, mi ò bá wọn jẹ, mi ò bá wọn mu o! Mi ò ya ẹnu ọ̀nà wọn, lẹ́hìn pé wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ ọkọ mi. Wọn ò jẹ mí ní sísì, mi ò dẹ̀ jẹ wọ́n ní sísì rí. Owó àti ipò l’o nyà wọ́n ní wèrè, tí wọ́n fi npète láti pà’yàn.
“Nígbà ìjàngbara ‘June 12,” nígbà tó dé ipele kan, tí wọ́n ri wípé mi ò gbà; tí mo ní dandan wọ́n máa dá yínyàn tí ará-ìlú yan ọkọ mi padà fun; nígbà tó dé ipele kan, wọ́n bá kó’ra wọn dé, ni wọ́n bá gbé àlàyé kalẹ̀. Wọ́n ní àwọn wá fún mi lówó, kí nlè jáwọ́! Èmi lẹ fẹ́ f’owó wá’jú ẹ̀ mọ́’ra? Ṣé ẹ ò wádi mi kẹ́ẹ tó wá ni? Wọ́n wá ní kíni mo fẹ́? Mo ní mo fẹ́ kí ìyà kó má jẹ ará-ìlú.
“L’ẹhìn ìgbà tí wọ́n wá pa ọkọ mi, ni wọ́n wá pè mí sí ìpàdé. Àwọn tó wà nípàdé, àjèjì ni gbogbo wọn! Wọ́n wá sọ fún mi pé kín wá jẹ ipò olórí nàìjíríà! Mo ní kí lẹ wí? ẹ ti ṣìí. Mo wá sọ fún wọn wípé mo fẹ́ tú’ṣu dé’sàlẹ̀ ìkòkò; mo fẹ́ mọ kí ló wà níbẹ̀ gan-an, kí ló fàá tí ọkọ mi ṣe kú irú ikú yẹn.
“Wọ́n mí kanlẹ̀; wọ́n wá ní tí nbá ti padà sí òkè-òkún l’ọhún, àwọn á jẹ́ kí nmọ̀. Wọ́n wá ní tani mo ní lọ́kàn tí ó lè jẹ ààrẹ nàìjíríà. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí pe orúkọ. Gbogbo orúkọ tí mo pè, wọ́n ti mọ gbogbo aburú tí ẹni yẹn kò lè fi ṣe olórí. Wọ́n wa sọ wípé kí àwọn ó pe orúkọ kan fún mi. Wọ́n wá pe orúkọ Àrẹ̀mú Ọbásanjọ́. Mo ní kò burú. Wọ́n tún wá tẹ̀ síwájú, wọn ní ṣé ó tẹ́ mi lọ́rùn, tí ẹni báyi báyi náà bá tún wà ní àwọn ipò báyi bayi. Mo wá wòó wípé, Kí ló nṣẹlẹ̀ gan? Ṣé ẹ̀yin ni ẹ nṣe ìlú fún nàìjíríà ni? Wọ́n bá rẹ́rin! Mo ṣáà nwò wọ́n bíi pé irú idán wo leléyi?
“Ibi tí mo nlọ ni pé, ti’gbéraga kọ́, Ọlọ́run fún mi kín mọ àṣírí tó pọ̀ nípa nigeria, àti Afríkà pàápàá, pẹ̀lú gbogbo àgbáyé. Àṣírí yẹn bọ́ sí mi lọ́wọ́. Wọ́n ní àwọn kàn fẹ́ gba àyè lọ́wọ́ mi ni; mó ní Ọlọ́run ló nfún’ni láyè.
“Babangida, o dẹ́rin pa’yàn gan o! Mo ti nrẹkẹ ẹ! Torí láti ìgbà tí a ti ṣe Ìbúra-Wọlé fún Olórí ìjọba Adelé Yorùbá, gẹ́gẹ́bí àṣírí tí mo ti mọ̀ nípa ọkùnrin tó njẹ́ Ibrahim Badamọ́sí Babangida yí, mo ti mọ̀ pé ó máa fẹ́ dún! Ó ní ìwà kan – ó máa nmúra bí àlùbọ́sà ni, tí ẹ máa máa ṣí ipele ipele aṣọ tó dà bo’ra – ẹẹ̀ le ri pé òun ló wà ní’dí ìbàjẹ́ yẹn! Ó máa ti to àwọn ènìyàn jọ tí wọ́n máa máa ṣe aburú yẹn. Ẹẹ̀ tí ní fọkàn sí òun. Torí ó máa nṣe bíi pé èèyàn dáadáa ni òun! Irọ́ dẹ̀ ni – ibi aburú ni ayé ẹ̀; gbogbo nkan tó ti ṣe láyé ẹ̀, ibi aburú ni. Kò sí nkankan tó jẹ́ rere nínú ayé ẹ̀!
“Babangida, ṣé o mọ̀ wípé nígbà tí o pa MKO, mi ò ta sí ẹ? Jẹ́jẹ́ mi ni mo máa nlọ! Ẹ̀yin, ìwọ, lẹ máa ntọ́ mi o! O wá ta sí Ìran mi, báyi, o ta sí ọmọ Yorùbá?! O ti ṣìṣe! Ìwọ Babangida, èèyàn-k’eèyàn ni ẹ́! Ibrahim Badamọsi Babangida, èèyàn burúkú ayérayé ni ẹ́! Àsìtáánì burúkú ni ẹ́! Oò ní ifẹ́ alààyè kan láyé rí. Oò ní’fẹ́ ara ẹ pàápàá. O kóríra ara ẹ, o kóríra gbogbo èèyàn.
Wàá wá máa díbọ́n bí ẹni pé o mọ kiní kan! Ìwọ tani? Àbí ‘wọ kọ́? Kiní kan máa ndùn mí nínú ọ̀rọ̀ ẹ, ìwọ Ibrahim Badamọsi Babangida, pẹ̀lú ọ̀rọ̀ MKO. MKO ní ìfẹ́ ẹ! Ó dẹ̀ gbára lé ẹ! Kò dẹ̀ sí ohun tó fàá ju wípé o kìí gbé ìwa síta; o máa ndíbọ́n kú ni.
Bóo ṣe ṣọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Délé Gíwá náà nìyẹn, tóo dẹ̀ paá. Bóo ṣe pa Maman Vatsa náà nìyẹn. Oò ní àánú kan, láyé, bí ó ti wù kó kéré mọ! Oò ní àánú nínú ayé ẹ; oò ní àánú nínú ojú ẹ, wàá dẹ̀ máa ṣe bí ẹni ‘pé inkan burúkú tí o nṣe, bíi pé dídára ni! Wàá tún ní àwọn wèrè kan tó nkó lẹ́yìn, tí wọ́n á máa sà ẹ́ bí ẹni pé nkan dáadáa lo nṣe!
“Ibrahim Badamosi Babangida, gbọ́ mi dáadáa – inkankan ṣẹlẹ̀. MKO wá bá mi. Ó ní pé o fẹ́ rìnrìn àjò kan, o fẹ́ lọ sí ojú àgbáyé. Ìrìn-àjò ẹ yẹn, Ísíákà Adélékè (tó ti kú) ó tẹ̀lé ẹ lọ. Kóo rántí. MKO wá sọ fún mi pé, títorí tí àwọn nkan tí mbá nṣe, Ọlọ́run máa nfi iyì si.
Ó ní òun fẹ́ kóo ní’yì, tóo bá jáde yẹn, k’awọn èèyàn rí ẹ, kí wọ́n ri wípé aṣọ tóo wọ̀ yẹẹ́, o yọ dáadáa. Ó ṣ’àpọ́nlé ẹ. Mo ní mo gbọ́. Mo ní kíni ká ṣe? Ó ní òun fẹ́ kín rán’ṣọ tí Babangida máa wọ̀ ni. Mo ní kílódé?
Ìyàwó ti Babangida ọ̀ún nkọ́? Àwọn èèyàn ẹ̀ nkọ́? Ó ní òun mọ nkan tí òun nsọ! Ó ní ṣé mo mọ̀ wípé aṣọ òkè l’òun fẹ́ kóo wọ̀, tí mò dẹ̀ mọ̀ pé taló máa rán àwọn aṣọ òkè. Ó ní ṣé mo mọ̀ pé ìdí tóun ṣe dìídì bẹ̀ mí pé kí nṣé ni, Ọlọ́run ṣ’oore fún mi, Ó máa nfi Ògo sínú nkan tí mo bá nṣe, pé òun dẹ̀ fẹ́ kó yọ dáadáa. MKO ro ire sí ẹ! Mó kọ́kọ́ fẹ́ yarí fún MKO. Ó ní ó tì; ó ní kí njọ̀ọ́; ó bẹ̀bẹ̀. Mo ní kò búrú, mo ti gbọ́, màá ṣeé.
“Mo wá lọ ṣe ìkọ́hàn (design) aṣọ òkè. Mo lọ bá àwọn ìdílé tó jẹ́ wípé wọ́n ti pẹ́ nínú aṣọ òkè ṣíṣe. Mo wá lo aṣọ-òkè ayé-àtijọ́. Mo wá hun aṣọ-òkè yẹn – ó ga jù! Ṣé o rántí aṣọ-òkè yẹn, ìwọ Ibrahim Badamosi Babangida? Èmi tí mo ṣe aṣọ-òkè yẹn nìyí – torí ìfẹ́ tí ọrẹ́ ẹ ní sí ẹ! Kóo mọ̀ pé èèyàn-k’eèyàn ni ẹ́! O wọ aṣọ yẹn, o dẹ̀ níyì.
Nígbàtí MKO fi máa gba aṣọ yẹn lọ́wọ́ mi, ó ní kí nṣàdúrà si – pé, tóo bá ti wọ̀ọ́, o máa níyì. Ṣé oò níyì, ìwọ Ibrahim Badamosi Babangida, nígbàtí o wọ aṣọ yẹn; ṣé wọn ò máa bi ẹ́? Kóo lọ padà sí ìwé ìrántí ẹ. Ṣé o mọ̀ pé ìkà ni ẹ́? Èmi yẹn ni ìwọ nṣe’pàdé lé lórí pé kán lọ pa ẹ́ dànù, láìí ṣe’mi!
“Ṣebí Abdusalam lẹ rán kó pa MKO? Abdusalam rádaràda, játijàti, tó jẹ́ àpò pacemaker ló ngbé s’ẹgbẹ́; ẹni tó jẹ́ pé ìdọ̀bálẹ̀ ló fi di Olórí nigeria.
“MKO ro ire fún ẹ.
“Ìgbà tó ti di pé wọ́n nṣe ìpàdé léra léra, lẹ́hìn tí a ti ṣe ìbúra-wọlé fún Adelé, ni mo ti mọ̀! Tí mo rí fídìò ìpàdé wọn, tí mo rí Abdusalam níbẹ̀, ni mo ti mọ̀ pé ìwọ lo wà ní’dí ẹ̀! Ẹ̀yin nṣe ìpàdé, kí wọ́n má jẹ kí ìjọba Yorùbá kí ó bẹ̀rẹ̀, kí wọ́n pa eléyí, kí wọ́n pa tọ̀hún! Irọ́ lẹ pa! Gbogbo yín ti kú nìyẹn.
“Nísiìyí, mo wá bọ́ sórí Olúṣẹgun Àrẹ̀mú Ọbásanjọ́…
Ìwọ Ọbásanjọ́, ṣé o mọ̀ pé Abacha tì ẹ́ mọ́lé, ó dẹ̀ fẹ́ pa ẹ́ ni. Èmi tí Ọlọ́run lò wípé kí wọ́n mọ́ pa ẹ́, nìyí. Eré tí mò nsá níta pé kí wọ́n má jẹ́ kọ́n pa ẹ́! Tí mo sọ pé tọ́n bá tún pa Ọbásanjọ́, mélo ló wá máa kù ní ọmọ Yorùbá?
“Nígbà tí wọ́n wá bá mi wípé ṣé mo gbà tó bá ṣe ìwọ ni kí ó di olórí nigeria, mo fi ọwọ́ si! Ṣé o dẹ̀ rántí ìgbà tí o ṣe aṣemáṣe, tóo ṣẹ̀ sí àwọn ọgá ẹ̀. Wọ́n wá fi ẹjọ́ ẹ sùn mí nígbà yẹn-ẹ.
Ó ní nkan tọ́n sọ. Mo sọ fún wọn kọ́n fi ẹ́ sílẹ̀, kọ́n kóo lo àsìkò ẹ lórí oyè tán! Mo ní kí wọ́n má bínú. Nítorí náà, jíjóko ẹ síbẹ̀, tóo fi lo àkókò ẹ tán, kò ṣẹ̀yìn èmi tí Ọlọ́run lò. Àdàbí máa pa gbogbo yín run. Ẹ̀yin nṣèpàdé lórí tani? Ẹ nṣèpàdé lórí ìran mi, ẹ nṣèpàdé lórí mi!? Ọ̀run máa pa yín, ayé máa pa yín. Gbogbo ọ̀nà tí ikú fi npa’ni ló máa pa gbogbo yín!
“Mo wá bọ́ sórí Bọlá Ahmed Tinubú..”
Nígbàtí MOA bọ́ sórí ọ̀rọ̀ Tinubú, ó fi yé Tinubú pé àwọn tó ndarí ìlú nàìjíríà láti ìta pe òun, kí òun gbé àṣírí kan jáde nípa Tinubú, tí kò ní le fi dé ipò ààrẹ, ṣùgbọ́n MOA sọ wípé, láyé, ẹyẹ ò lè gbọ́ àṣírí yẹn lẹ́nu òun – tí ó túmọ̀ sí wípé oore-ọ̀fẹ́ MOA, tí Olódùmarè fun láti ṣe, ni Tinubú ṣe dé orí àléfà!
Tinubú ọ̀ún ló wá nfi ikú lé MOA léni! Tí Olódùmarè kò dẹ̀ gbà, láyé! A wá ri wípé àwọn ayíradà mẹ́ta yí – Babangida, Ọbasanjọ àti Tinubú ni wọn ti jẹ oore tó tóbi láti ọ̀dọ̀ MOA, ní akókò tí ó lágbára ní ìgbésí ayé wọn, ṣùgbọ́n tí wọ́n wá nfi ikú wá MOA báyi, tí Ọlọrun kò dẹ̀ fún wọn ṣe; bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ntako Orílẹ̀-Èdè Yorùbá, tí Èdùmàrè kò dẹ̀ gbà fún wọn!
Ẹ ò ní ṣe rere láyé mọ́ o, Babangida, Ọbasanjọ́ àti ìwọ Tinubú; gbogbo agbára ilẹ̀ Yorùbá lòdì sí yín; láyé àti lọ́run ni a ti kọ̀ yín sílẹ̀; Orílẹ̀-èdè Yoruba ti dúró. Kò sí nkan tí ẹ lè ṣe si.
Ọ̀rọ̀ MOA tún wá fi hàn wípé láti ìta ni wọ́n ti ndarí ìlú nàìjíríà!