Àfi ẹnití kò bá mọ ọṣẹ́ tí àwọn ọmọ Íbò tí ṣe sí àwọn ẹ̀yà míràn ní ibi tí àwọn òyìnbó amúnisìn kó papọ̀ ní’jọ́ náà l’ọhún, tí wọ́n pè ní Nigeria, l’ó máa rò wípé ènìyàn gidi ni àwọn ìran Íbò jẹ́.
Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí.
Olori Adele Orílẹ̀-Èdè Yorùbá, Ọgbeni Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọkore
Ìran Íbò ni ọ̀dàlẹ̀ t’ó sábà f’ara sin fún ọ̀pọ̀l’ọpọ̀ ọmọ Yorùbá l’oní, tí wọn kò mọ̀ wípé ọ̀ta paraku àti ẹni ibi ni ìran Íbò jẹ́. Íbò ní ìmọ̀ t’ara ẹ̀ nìkan; kò sì sí ibi tí wọ́n máà wà tí kìí ṣe wípé kí wọ́n jẹ gàba lé’rí ẹni t’ó kù ni wọ́n máa ma wá kiri.
Ó tí pẹ́, ní pàtàkì pàápàá, tí ọmọ Íbò ti nf’ọwọ́ la’lẹ̀ fún ọmọ Yorùbá l’orí ilẹ̀ Yorùbá.
Ọ̀pọ̀l’ọpọ̀ àwọn ènìyàn – gẹ́gẹ́bí àpẹrẹ – ni wọ́n rò wípé Nnamdi Azikiwe ni ó dá ẹgbẹ́ òṣèlú NCNC sí’lẹ̀, ní ayé ìgbàanì, kí Nigeria ó tó gba òmìnira! Rárá o!
Ka Ìròyìn: Ọ̀daràn Nigeria ndókùkùlajà mọ́ ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá
Bàbá, ọmọ Yorùbá tí a mọ orúkọ rẹ̀ sí Herbert Macaulay, ní ọ̀pọ̀l’ọpọ̀ ọdún kí Azikiwe ó tó dé l’ati ìlú òyìnbó, ni ó dá ẹgbẹ́ NCNC sí’lẹ̀, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ wípé l’ẹhìn ìgbà t’ó dé, t’ó sì da’ra pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ náà ni wọ́n tó wá fi jẹ Akọ̀wé ẹgbẹ́ náà, ṣùgbọ́n ẹgbẹ́ àwọn ol’oṣè’lú ọmọ Yorùbá ni.
Ṣé ẹ mọ̀ wípé ní àkókò yẹn, Yorùbá wà gẹ́gẹ́bí orílẹ̀-èdè ti’rẹ̀ ni; nít’orí náà, ẹgbẹ́ òṣè’lú orílẹ̀-èdè Yorùbá ni ẹgbẹ́ náà; ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ wípé wọ́n gba ẹ̀yà míràn mọ́’ra tí ó ngbé ní ilẹ̀ Yorùbá.
Bí wọ́n ṣe gba Azikiwe mọ́’ra nìyẹn, kìí ṣe wípé òun l’ó dá NCNC sí’lẹ̀. Ṣùgbọ́n nígbàtí Herbert Macaulay, tí ó jẹ́ olùdásí’lẹ̀, tí ó sì jẹ́ ọmọ Yorùbá, nígbàtí ó wà ní ìdúbú’lẹ̀ àìsàn, kí ó tó lọ ibi àgbà nrè ní ọjọ́ ogbó rẹ̀, ní ó lọ sí okè ọya l’áti la àkókò àìle-ara yí kọjá. Ní àkókò yí ni ó fi gbé blueprint (àgbéka’lẹ̀) NCNC fún Azikiwe; l’ẹhìn náà, àfì’gbà tí Azikiwe yí bírí tí ó sọ ẹgbẹ́ NCNC di ẹgbẹ́ tí ọmọ Íbò ti nfi ọwọ́ la’lẹ̀ fún ọmọ Yorùbá l’orí ilẹ̀ Yorùbá.
Azikiwe yíì náà, bákannáà, ni ó kọ́ pe èdè wípé ‘Lagos is no man’s land’ tí àwọn ọmọ Íbò npè l’oní (èyíinì, ìsọkúsọ tí wọ́n máa nsọ wípé Èkó kìí ṣe ilẹ̀ ẹnik’ẹni)! Hábà!
Ka Ìròyìn: Íbò Àti Fúlàní Gba Ilẹ̀ Yorùbá Kan
Azikiwe kan náà yí ló sọ ní ìwọ̀n àádọ́rin ọdún s’ẹhìn, nígbànáà l’ọhún wípé kí wọ́n má ṣe fi ọ̀rọ̀ sí’nú ìwé Òfin Nigeria nígbànáà wípé ẹ̀yàk’ẹyà tí ó bá fẹ́ kúrò nínú Nigeria nígbàkúgbà l’ẹtọ́ àti ṣe bẹ́ẹ̀; ṣé kí ó tó di ìgbà yí ni Bàbá wa Awólọ́wọ̀ ti lọ bá Azikiwe s’ọ̀rọ̀ wípé ó dára, ó sì yẹ, kí ó jẹ́ wípé ẹ̀yà tí ó bá fẹ́ kúrò nínú Nigeria kí ó ní ẹ̀tọ́ l’ati kúrò, tí òun àti Azikiwe sì ti f’ẹnù kò wípé ó dára bẹ́ẹ̀; ṣùgbọn kí’lẹ̀ ọjọ́ àkọsí’lẹ̀ àdéhùn yí ó tó mọ́, ni Azikiwe ti lọ bá àwọn Fúlaní wípé kí wọn má ṣe gbà; bẹ́ẹ̀ ni Azikiwe da’lẹ̀ Awólọ́wọ̀.
Ní’gbà tí àwọn ol’ógun kọ́kọ́ máa gba ìjọba ní Nigeria ní 1966, ṣe bí àwọn Íbò yí náà ni; tí wọ́n pa Fulàní, pa Yorùbá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n tí wọ́n dá àwọn Íbò sí láì pa wọ́n l’ara!
Nígbàtí ogun ṣẹ’lẹ̀, ṣèbí nṣe ni Victor Banjọ tí ó wà pẹ̀lú àwọn Íbò, nṣe ni Ojukwu pàpà paá tìt’orí wípé ó sọ Yorùbá sí Awólọ́wọ̀ nígbàtí wọ́n pàdé ní ibi ogun ní Ọ̀rẹ̀ l’ọjọ́ náá l’ọhún.
Ṣe bí àwọn Íbò yí náà, nígbàtí ogun tán, tí wọn kò ní nkankan, nṣe ni ọmọ Yorùbá fún wọn ní ilẹ̀ ní Alábà l’ati lè fi ṣ’òwò kí wọ́n le fi gbé’ra. Ṣùgbọ́n, l’oní, àwọn Íbò yí kò fẹ́ kófìrí ọmọ Yorùbá kí ó gbìyànjú àti dá nkan ṣe ní Alábà yí!
Ka Ìròyìn: Ọmọ Yorùbá, Ẹ Ṣọ́’ra! àwọn ọmọ Igbo ti ntú ní ọ̀pọ̀ yanturu wọ ìlú Èkó
Hábà! Mélo ni k’á kà ní eyín adépèlé ìwà ìkà àti ọ̀daràn tí àwọn ọmọ Íbò nhù, pàápàá sí ìran Yorùbá!
Àwọn ojúlówó ọmọ Yorùbá ni wọ́n gbé àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí’ta, l’orí ayélujára ní ọjọ́ ẹtì, ọjọ́ kẹ́rìnlá, oṣù kẹ́fa, ọdún 2024 yí, tí wọ́n sì tún ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn ọmọ Íbò wípé, kí Íbò ó so ewé agbéjẹ́ mọ́’wọ́ tí wọ́n bá fẹ́ rí àyè l’orí ilẹ̀ Yorùbá o!