Ohun kan tí a rí lórí ẹ̀rọ ayélujára, ló sọ pé, ọ̀gá ẹ̀ka ètò Ọrọ̀-Ajé wọn ní ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà, ọkùnrin tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Edun, sọ pé kí àwọn ará ìlú wọn, pàtàkì, àwọn ti apá ìlú ààrẹ wọn àná, kí wọ́n di ààrẹ náà, Muhammadu, dání, torípé ó ti ta epo rọ̀bì tí wọn ò tíì wà jáde nínú ilẹ̀, títí di ọdún méjì síwájú, ó ti tàá, ó sì ti kó owó rẹ̀ lọ! Nítorí náà, àwọn kàn ngbé epo síta láì gba owó ni!
Ó ní ìyẹn ló jẹ́ pé ààrẹ wọn àná ló nfi ebi pa wọ́n o, tó sì nfi ìyà jẹ wọ́n; àwọn ò sì lè mu, kí wọ́n gbé ìwádi kalẹ̀ lórí rẹ̀, torí ó jẹ́ ọmọ-ẹgbẹ́ olóṣèlú tó wà lórí àléfà wọn ní nàíjíríà.
A dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run Elédùmarè, tí ó ti tipasẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀, Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, gbà wá kúrò nínú ìlú aṣebi yẹn. Ní agbára Èdùmàrè, wọ́n máa sá kúrò lórí ilẹ̀ Democratic Republic of the Yoruba láìpẹ́, ìjọba Orílẹ̀-Èdè wa á wọlé sí oríkò ilé-iṣẹ́ Ìjọba wa.