Ohun tí kò ṣẹlẹ̀ rí láti àtayébáyé wá, tí ìwọ́de ìf’ẹ̀hónúhàn ti máa ń ṣẹlẹ̀, inú ilé ni oníkálukú òbí máa ń tọ́jú àwọn ọmọdé sí, wọn kì í jẹ́ kí ọmọdé jáde rárá.
Ẹ wò ìwọ́de tí ó ń lọ lọ́wọ́ ní Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bí a ṣe ríi nínú fídíò, níbi tí àwọn ónìròyìn kan tí ń fi ọ̀rọ̀ wá ọ̀dọ́mọdé bìnrin, ọmọ ọdún mẹ́jọ tí ó dárapọ̀ mọ́ àwọn tí ń ṣe ìwọ́de, ẹ gbọ́ ohun tí ó fí dáhùn pé, ohun darapọ̀ nítorí pé bàbá òun kò rí owó ilé ìwé òun àti owó ilé san, pàápàá jù lọ, owó bisikiiti, tí a mọ̀ sí oúnjẹ àwọn èwe, tí bisikiiti náírà mẹ́wàá, owó ìlú wọ́n ti dí ọgọ́rùn-ún naira, ọ̀dọ́mọdé náà dáhùn wípé òun fẹ́ kí ìjọba wọn dín owó ọjà wá’lẹ̀.
O se ni ní àánú pé irú àwọn ọmọdé bayìí tí ń la gbogbo irú nkan báwọ̀nyí kọjá, ṣùgbọ́n, ẹ jẹ́ kí àwa ọmọ Yorùbá Olómìnira Tiwantiwa fi ọkàn sii pé a kò gbọ́dọ̀ fi àyè gba ìwà ìbàjẹ́ tí ó lé mú gbogbo nkan bàjẹ́ tó báyìí nítorí ìwà ìmọtaraẹni nìkan àti ọkánjúwà.
Àti wípé bí ìyá wa Modupeola Onitiri-Abiọla ṣe gbé ìpìlẹ̀ rere sílẹ̀ fún àwa ọmọ Aládé yìí, kò lè sí àyè fún ẹnikẹ́ni láti bẹ̀rẹ̀ ìwà ìbàjẹ́ bẹ́ẹ̀.
Ká Ìròyìn Síwájú sí:
- ÀMERICA TI F’ỌWỌ́ SÍ ỌSIN ADÌẸ LÁTI YÀRÁ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ÌMỌ̀ ÌJÌNLẸ̀
- ẸGBẸ̀RÚN MÁRUN NÁÍRÀ NI ÀWỌN ARÁ ÌLÚ NÀÌJÍRÍÀ FI DA’LẸ̀ ARA WỌN !
- ÀNFÀÀNÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TI YORÙBÁ
- ÒFÉGÈ ÌRÀNLỌ́WỌ́: ọmọ Yorùbá, máṣe yà sí’bẹ̀ !
- ỌMỌKÙNRIN KAN ṢE’KÚ PA BÀBÁ TÓ BÍ BÀBÁ RẸ̀ NÍTORÍ OKO
- JAMIU ABÍỌ́LÁ NHU ÌWÀ ỌMỌ ALÈ
Ìdí tí èyí fi kàn wá gbọ̀ngbọ̀n ni pé àwọn wèrè ìlú Nàìjíríà yí níláti kúrò lórí ilẹ̀ wa ní kíá ni. À ò fi àyè gbà wọ́n láti ṣe ìfẹ̀hónúhàn Nàìjíríà kankan ní orí ilẹ̀ Yorùbá; nítorí èyí, ó bí wa nínú gidi pé ní Ọjọ́ta, ní ìpínlẹ̀ Èkó, D.R.Y, ni eléyi ti ṣẹlẹ̀; ṣùgbọ́n ìsọ̀rọ̀sí ọmọ náà kò jọ ahọ́n ọmọ Yorùbá.
Tí ó bá jẹ́ ọmọ Yorùbá, á jẹ́ pé àwọn òbí rẹ̀ ti wọ gàù lábẹ́ òfin orílẹ̀-èdè Yorùbá. Tí kìí bá nṣe Yorùbá, ìyẹn á jẹ́ ẹ̀sùn sí ọrùn Nàìjíríà, pé wọ́n gbé ìfẹ̀hónúhàn wọn wá sí orílẹ̀-èdè D.R.Y