Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X
The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal

Ilé-ẹjọ́ tí ó gajù ní agbègbè tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Orílẹ̀ Èdè wa, Democratic Republic of the Yorùbá, èyí tí nwọ́n npè ní Nàìjíríà, ti fi òpin sí ìwa kí a máa jẹ gàba lórí owó ìṣúná tí ó yẹ láti lọ sí àpò ìjọba tí ó súnmọ́ ará ìlú jùlọ ní orílẹ̀-èdè tiwọn l’ọhún, èyí tí àwọn Gómìnà Ìpínlẹ̀ wọn jókòó lé.

Àwọn Adàjọ́ náà sọ pé kò bá òfin tí àwọn fi nṣe ìjọba ìlú náà mu, ní ẹsẹ̀ èkejìlélọ́gọ́jọ (sẹ́kíṣọ̀n 162) nínú ìwé ìṣofin ọdún ìkọkàndínlẹ́gbẹ̀wá (1999) ti nwọ́n nlò ni ìlú náà.

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal

Ilé-ẹjọ́ ọ̀ún tún sọ pé ìwà kí a máa yan ẹnìkan láti máa bojútó iṣẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ náà kò tún bá òfin mu. 

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdájọ́ yìí kò kàn wá nítorí Orílẹ̀ Èdè Yòrùbá kò sí lára Nàìjíríyà mọ́, ṣùgbọ́n èyí fi hàn bí àwọn Gómìnà Nàìjíríyà kò ti bọ̀wọ̀ fún òfin tó, nwọn kò bọ̀wọ̀ fú òfin wọn, bẹ́ẹ̀ni nwọn kò bọ̀wọ̀ fún òfin àgbáyé. Nítorí èyí ni nwọ́n fi njẹ gàba lórí ilẹ̀ wa ní Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, Democratic Republic of the Yorùbá. 

Ìkìlọ̀ wá ni eléyi o, Kí Ìlú Nàìjíríà dáwọ́ dúró nínú ìwà agbésùnmọ̀mí tí nwọ́n nṣe lórí Ilẹ̀ Democratic Republic of the Yorùbá. 

Ilé-ẹjọ́ tí ó gajù náà l’ọhún wá kọ̀ o, láti gba àwíjare tí àwọn gómìnà wọn sọ.