ÌJỌBA AGBÉSÙNMỌ̀MÍ NÁÌJÍRÍÀ DÁ ÒṢÌṢẸ́ TÍ Ó NTỌRỌ OWÓ NÍ PÁPÁKỌ̀-OFÚRUFÚ DÚRÓ LẸ́NU IṢẸ́

Ní àìpẹ́ yí ni a rí fídíò lórí ẹ̀rọ ayélujára, tí ó fi hàn bí òṣìṣẹ́ àjọ ètò ìrìnnà-wọ̀lú àwọn ìjọba agbésùnmọ̀mí nàìjíríà tí ó njẹgàba lé ilẹ̀ Democratic Republic of the Yoruba, ṣe ntọrọ owó lọ́wọ́ arìn’rìn-àjò kan. Ohun tí a wá gbọ́ nísiìyí ni pé àjọ náà ti dá òṣìṣẹ́ yí dúró fún ìgbà kan ná, lẹ́nu iṣẹ́.

Kò sí ohun tí èyí fi kàn wá ju pé orí ilẹ̀ wa, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y) ni eléyi ti ṣẹlẹ̀; ní pápákọ̀-òfúrufú ní Ìlú Èkó.

Èyí tí a fẹ́ kí aráyé kí ó mọ̀ ni pé, àti ẹni tí ó ntọrọ owó lọ́wọ́ arin’rìn-àjò, àti àwọn àjọ tí ó dáa dúró l’ẹnu iṣẹ́, ọ̀daràn ni wọ́n.

Àjọ kankan tí ó jẹ́ ti Nàìjíríà kò ní ẹ̀tọ́ kankan lórí ilẹ̀ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá; gbogbo nkan wọ̀nyí sì jẹ́ Ẹ̀rí t’ó dájú gidi níwájú àgbáyé, pé ní òtítọ́ ni, ìjọba agbésùnmọ̀mí nàìjíríà fi ipá dúró lórí ilẹ̀ D.R.Y, lẹ́hìn tí a ti jáde kúrò nínú Nàìjíríà ní ogúnjọ́ oṣù bélú, ẹgbàá ọdún ó lé méjì-lé-lógún, tí a sì ti di orílẹ̀-èdè-aṣèjọba-ara-ẹni, pẹ̀lú pípolongo ìṣèjọba-ara-ẹni wa, àti ṣíṣe ìbúra-wọlé fún ìjọba wa, ní ọjọ́ kéjìlá, oṣù igbe, ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rin-lé-lógún, èyí tí ó fi jẹ́ pè ọ̀daràn ni Nigeria àti gbogbo ohun tí ó njẹ́ orùkọ ìṣèjọba Nàìjíríà, ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, ní àkókò tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀, àti di bí a ṣe nsọọ́ yí.

Nàìjíríà dà bí ẹni pé wọn kòì tíì mọ irú ọ̀ràn tí wọ́n ndá; bẹ́ẹ̀ wọ́n dẹ̀ mọ̀ọ́, ṣúgbọ́n ohun tó sọ pé àkókò ìparun Nàìjíríà ti dé, ni ó njẹ́ kí wọ́n máa ṣe agídí wèrè.

Gbogbo àwa ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá, àsìkò tí a máa rẹ́yìn Nàìjíríà lórí ilẹ̀ Yorùbá ló dé yí.

Ká Ìròyìn Síwájú sí: