Àìmọ̀ máa njẹ́ kí ohun tí a kò mọ̀ ó ṣe àgbà fún’ni; ṣùgbọ́n nígbàtí a bá ti ní ìmọ̀, òtítọ́ tí a mọ̀ á ṣe wá ní òmìníra, ẹnikẹ́ni kò ní le tàn wá jẹ lórí ohun náà mọ́.

Ní ọjọ́ kéjìlá, oṣù igbe, ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rinlélógún, lẹ́yìn tí a ti ṣe Ìpolongo Ìṣèjọba-Ara-Ẹni wa níjọ́ náà, ni a sì ṣe ìbúra-wọlé fún Olóri-Ìjọba Adelé wa; wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn adelé tókù.

Ọjọ́ kéjìlá oṣù ọ̀wàrà tí a wà nínú rẹ̀ yí ni ó wá fi pé oṣù mẹ́fà, géérégé, tí àwọn Ìjọba-Adelé wa, lábẹ́ Olórí Ìjọba-Adelé, Bàbá wa, Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọ́kọrẹ́, ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́.

Tí kò bá sí ti ìjẹgàba àwọn agbésùnmọ̀mí nàìjíríà lórí ilẹ̀ wa ni, gbogbo ilé-iṣẹ́ agbóhùn-sáfẹ́fẹ́ tí ó wà ní ilẹ̀ Democratic Republic of the Yoruba, tí wọ́n sì ti ní àṣẹ lábẹ́ ìjọba D.R.Y, ni wọn ìbá ti máa gbé ìròyìn, lóríṣiríṣi, jáde nípa bí iṣẹ́ ṣe nlọ, tí àwa fún’ra wa pàápàá á ti máa ri ní àyíká àti agbègbè wa, bí ìtẹ̀síwájú ṣe nlọ sí ní orílẹ̀-èdè D.R.Y. Bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo ohun tí a ò lè ṣe báyi torí olóríburúkú agbésùnmọ̀mí  nàìjíríà ta’wọ́ dí ọ̀nà, ni àá ti máa máa ṣe! Gẹ́gẹ́bí àpẹrẹ, àá ti máa fi ojú wa rí àwọn adelé wa nígbàkúgbà tí wọ́n bá wá sí agbègbè wa, tàbí tí a ní nkan lá ti lọ ṣe ní ilé-iṣẹ́ ìjọba wa gbogbo. Àá ti rí ìjọba D.R.Y láarín ìgboro, ní ilé-ìwé, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ; gbogbo ibi tí ohun kan tàbí òmíràn bá sì ti farahàn ní àwùjọ wa, ni àwọn ilé-ìròyìn gbogbo á máa fi tó wa létí.

Nítorí náà, ìtadí’nà tí agbésùnmọ̀mí nàìjíríà ṣì nta dí’nà nínú ìwà ìjẹgàba wọn, ṣùgbọ́n tí Ọlọ́run máa ṣí wọn ní’dí ní àìpẹ́ yí, òun ló fàá tí àwa ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) kò ti máa ri lójúkorojú àti lóòrèkóòrè gbogbo iṣẹ́ tí Ìjọba-Adelé wa ti nṣe láti oṣù mẹ́fà tí wọ́n ti dé orí àlééfà. Ṣùgbọ́n o, wọ́n nṣiṣẹ́ lọ takuntakun, gẹ́gẹ́bí Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá fún’ra wọn ti sọ, pàápàá, nínú ọ̀rọ̀ wọn sí àwa ọmọ Ìbìlẹ̀ Yorùbá ní àìpẹ́ yí.

Gẹ́gẹ́bí àpẹrẹ, Màmá sọ pé tí kìí bá nṣe àsìkò tí kò sí, àwọn fẹ́ fi tó wa léti iṣẹ́ tí wọ́n ti ṣe lórí ọ̀rọ̀ owó-ìná wa (currency) àti ètò ìkọ́jà-wọlé, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, ṣùgbọ́n ìyẹn tún di ọjọ́’wájú, látàrí pé ọ̀rọ̀ tí Màmá wá bá wa sọ gbẹ̀yìn yí pọ̀ gan-an ni, bẹ́ẹ̀ ni ó jẹ́ yàjóyàjó.

Ohun tí Màmá nsọ ni pé kò sí ìdáwọ́dúró kankan rárá! Ìjọba-Adelé Democratic Republic of the Yoruba nṣiṣẹ́ lọ ní gidi; láìpẹ́, láìjìnà, lágbára Olódùmarè, àwọn asíwín àjẹgàba wọ̀nyí á kúrò ní ilẹ̀ wa, bẹ́ẹ̀ náà ni àá tún máa gbọ́ bí iṣẹ́ ṣe nlọ si, lágbára Olódùmarè. 

Nítorí èyí, kí a máṣe rò pé nṣe ni iṣẹ́ dáwọ́ dúró! Ohun tí ó ṣe pàtàkì, ní àkọ́kọ́, ni pé, a ti gba ìṣèjọba-ara-ẹni Democratic Republic of the Yoruba padà, àgbáyé ti mọ̀ pé orílẹ̀-èdè ni wá; nítorí èyí, iṣẹ́ nlọ ní gidi.

Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá