Oníṣègùn Ìtọ́jú-Àwọn-Ọmọdé kan, ní ìlú Ìbàdàn, Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), níbití agbésùmọ̀mí Nàìjíríà tí ń jẹ gàba, Dókítà Folúṣọ́ Balógun, ní ó ké gbàjarì, tí ó fí ọ̀rọ̀ yí léde; ó sọ pé, fún ìgbà-àkọ́kọ́ láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn, ohun abàmì kan nṣẹlẹ̀ ní Ilẹ̀ Yorùbá. Gẹ́gẹ́bí oníṣègùn, ọ̀rọ̀ náà ṣe-é ní kàyéfi! Ó ní, fún ìgbà àkọ́kọ́, ilẹ̣̀ Yorùbá nrí àwọn ọmọ tí àìsàn àìrónjẹ-tó-péye jẹ, nṣe wọ́n!

Àìsàn yí, tí àwọn èèyàn mọ̀ sí KWASHIORKOR, jẹ́ ìyàlẹ́nu fún dókítà yí, pé ní’lẹ̀ Yorùbá kẹ̀! Nítorí Dókítà Folúṣọ Balogun yí jẹ́ oníṣègùn tí ó jẹ́ pé ìtọjú-àwọn-ọmọdé gan-an-gan ni ìtọ́jú-ìṣègùn tí ó yàn láàyò, tí ó sì gba oyè lé; àfi ìgbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkíyèsí báyi, pé ohun tí a kò gbúro rẹ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn, nṣe ní ó yọjú – a! ó wá gbóhùn síta gẹ́gẹ́bí oníṣègùn ìtọ́jú-ọmọdé pé, ará ìlú, ohun tí ó nṣẹlẹ̀ mà l’eleyi o! ọmọdé ní ilẹ̀ Yorùbá n-ní àrùn kwashiorkor, àrùn àìrónjẹ-tó-péyé jẹ!

Ẹ jọ̀wọ́, ẹ̀yin èènìyàn, ibi tí ogun ti njà lọ́jọ́ pípẹ́, nígbà-náà l’ọhún, ni a ti gbọ́ pé àwọn ọmọ wọn ń-ní kwashiorkor! Ní ilẹ̀ Yorùbá tí ó l’ọrá, kwashiorkor ti jẹ́?

Èyí fi yé àwa ọmọ Yorùbà pé, OJÚ OGUN LA WA O!

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal

Ẹ̀yin wèrè tí ẹ pe ara yín ní gómìnà agbésùmọ̀mí nàìjíríà tó ń fipá jẹgàba lórí ilẹ̀ wa, tí ọmọ yín njẹun ṣùgbọ́n tí ọmọ Yorùbá ń-ní kwashiorkor, a! kò níí dáa fún yín; a ní kí ẹ jáde kúrò ní gbogbo oríkò ilé-iṣẹ́ ìṣàkóso wa gbogbo ní ilẹ̀ Yorùbá, kí ìṣàkóso D.R.Y ó wọlé wá láti ṣe iṣẹ́ ti Olódùmarè gbé lé wọn lọ́wọ́, àfi ìjẹgàba yíì náà ni ẹ nṣe!

Dókítà Folúṣọ́ Balogun jẹ́ oníṣègùn tí ó nṣiṣẹ́ ní Ilé-Ìwòsàn ìkọ́ni-níṣẹ́ ti Fásitì ìlú Ìbàdan, èyí tí a mọ̀ sí U.C.H, èyí tí ó jásí pé ó mọ nkan tí òun rí, ó sì mọ nkan tó nsọ!

Ọ̀rọ̀ yí wá láti ẹnu bàbá wa, BLACK LION, pé kí gbogbo wa, kí á dìde, kí á lé gbogbo àwọn wèrè tí wọ́n pera wọn ní gómìnà wọ̀nyí, tí wọ́n njẹgàba sorí ilẹ̀ wa, D.R.Y, kúrò, àti pé kí gbogbo wa fi ọwọ́sowọ́pọ̀ láti lé wọn kúrò lórí ilẹ̀ wa.

Gbogbo àwọn àgbà òfò, àwọn tí wọ́n ńbá ilẹ̀ wa jẹ́, wọ́n ní kí gbogbo wa kí á dìde, ká lé wọn kúrò lórí ilẹ̀ wa. Nítorí, ọmọ Yorùbá ló ni ilẹ̀ Yorùbá. Èyí tí wọ́n ńjẹ́ kí oríṣiríṣi àìsàn kí ó máa ṣe ọmọ Yorùbá yí, ṣé ó dìgbà tí wọ́n bá pa gbogbo ọmọ Yorùbá tán ni a tó máa gbé ìgbésẹ̀ ni?

Àsìkò nìyí fún wa, láti dìde, láti jà, kí á lé wọn kúrò lórí ilẹ̀ wa. Àwọn àìsàn rádaràda gbogbo, tí ó jẹ́ pé Nàìjíríà ni ibùgbé wọn, tí wọ́n wá nko wá sí orí-ilẹ̀ wa yí. 

Àwọn ẹni ibi wọ̀nyí, wọ́n nmọ̀-ọ́-mọ̀ ba ilẹ̀ wa jẹ́. Àwọn òyínbó ńkó onjẹ tí kò ṣe ànfààní fún ara, wá sí ilẹ̀ wa; àwọn tí ó pera wọn ní àgbà-à-gbà sì ńgbà wọ́n láyè; ìwọ̀nyí ló nfa oríṣiríṣi àìsàn.

Ṣé bí àwa ọmọ Yorùbá ṣé máa máa wò ré, títí tí gbogbo nkan máa fi bàjẹ́ tán? Àsìkò rèé fún wa! Ọmọ Yorùbá ilẹ̀ Yorùbá ti dúró; àti ní ìṣàkóso wa; ńkan tó kù tí a fẹ́ ṣe báyi ni kí àwọn ìṣàkóso Nàìjíríà tí wọ́n ńjẹgàba lórí ilẹ̀ wa kúrò níbẹ̀. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á dìde fún orílẹ̀-èdè wa, nítorí Ẹ̀tọ́ wa ni láti ṣe èyí, ẹ̀tọ́ wa ni láti lé àwọn ọ̀tá ìran Yorùbá kúrò lórí ilẹ̀ wa; ilẹ̀-àjogúnbá wa ni. Ìyà yí ti tó gẹ́ẹ́, àbí kílódé?

Awọn tó jẹgàba sórí ilẹ̀ wa wọ̀nyí, àwọn ni Ọ̀TÁ INÚ ILÉ. Kí gbogbo àwa ọmọ Yorùbá pawọ́pọ̀, kí á lé wọn kúrò lórí ilẹ̀ wa, kí wọ́n máṣe ba ilẹ̀ wa jẹ́ mọ́, kí wọ́n máa lọ sí Nàìjíríà wọn l’ọhún, nígbà tí ó jẹ́ pé Nàìjíríà ni ó wù wọ́n.

Àgbàrá ò ní òun ò ní’lé wó, onílé ni a ò níí gbà fun. Àwa ni a ni ilẹ̀ wa; àwa ni Olódùmarè fifún.

Wọ́n ní kí a máṣe la ojú wa sílẹ̀, kí tàlùbọ̀ ó kó wọ̀-ọ́ o! Ìyà tí a jẹ yí ti-tó-gẹ́ẹ́. Ọlọ́run ti ṣàánú fún wa, a ti bẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso wa. Ó kù sí àwa ọmọ Yorùbá lọ́wọ́ báyi kí á dìde o. Ẹ jẹ́ kí á lé wọn, kí ẹsẹ̀ wọn ó máṣe ba’lẹ̀. Wọ́n mọ̀ pé Yorùbá ti dádúró. Ẹ jẹ́ kí á mú gbogbo ẹ̀mí-ìbẹ̀rù kúrò lọ́kàn wa.

Gbogbo àwọn tó ń pera wọn ní ọba àti bọ̀rọ̀kìní, ẹlẹ́tàn ni wọ́n, amúnisìn ni gbogbo wọn nṣiṣẹ́ fún – èyí tí ó pọ̀jù nínú wọn. Àti ní kọ̀rọ̀, àti ní gbangba, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa kí á jọ pawọ́pọ̀, kí á lé wọn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n máa rán àwọn ọ̀dàlẹ̀ sí àárín wa, ẹyin ẹ ṣáà jẹ́ kí a ṣọ́ra, bí a bá ṣe ńpa ọwọ́ pọ̀, ní àdúgbò wa, níbíkíbí gbogbo tí a wà ni. Kí á rántí pé ojú ni alákàn fi nṣọ́ orí. Bí a ṣe ní àwọn ọmọ-ọkọ Yorùbá, bẹ́ẹ̀ ni a ní àwọn ọmọ-àlè. Àsìkò sì nìyí fún àwọn ọmọ-àlè láti kúrò.

Gbogbo àwọn tí ó jẹ́ ọ̀dàlẹ̀, pátá, èpè ni kí á ṣẹ́ fún wọn.

Gbogbo àlùmọ́nì tí Elédùmarè fún wa, àwọn olóríburúkú yí ni wọ́n ńdá kó gbogbo ẹ̀! Wọ́n tún wá gbé oríṣiríṣi àìsàn wọlé sorí ilẹ̀ Yorùbá wa báyi!

Ilẹ̀ Yorùbá ti wà láti àtètèkọ́ṣe! Àsopọ̀ tìpá-tìkúùkù tí àwọn Gẹ̀ẹ́sì sì so wá papọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà míràn, ọgọ́run-ọdún àsopọ̀ náà ti pé, ó tún ti lé! A sì ti kúrò láarín wọn; Olódùmarè ti yọ wá! – wọ́n lo Màmá wa Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá láti kó wa kúrò nínú ìdè. Ọmọ Yorùbá, ẹ jẹ́ kí á mọ ǹkan tí a ńṣe!

Wọ́n mọ̀ọ́-mọ̀ dá ebi àti ìyà sílẹ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá ni. Wọ́n nkó àwọn àjòjì wá láti máa kó àwọn àlùmọ́nì ilẹ̀ wa. Tí a bá dìde, kò sí ńkan tí wọ́n lè ṣe. Gbogbo agbára tí a bá ní, ẹ jẹ́ kí á gbe síta, láti dojú-ìjà kọ àwọn ọ̀tá ìran Yorùbá wọ̀nyí – àsìkò nìyí. Ó ti npẹ́ jù. Ẹ jẹ́ kí á fi yé àwọn ọ̀tá wọ̀nyí pé ilé baba-ọmọ kìí ba ọmọ l’ẹrù. Ẹ jẹ́ kí á tètè lé àwọn ọ̀tá-inú-ilé wọ̀nyí kúrò, kí a wá gbé Àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè fi rán Màmá wa, Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, sí Àwa Ọmọ Yorùbà sí ojú-iṣẹ́, kí á bẹ̀rẹ̀ sí mulò.

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal

Inú Àlàkalẹ̀ yí ni a ti máa rí ìṣerere, níbẹ̀ ni Àánú á ti fọ’hùn, tí eku á máa dún bí eku, ẹyẹ á máa dún bí ẹyẹ, ọmọ-ènìyàn á máa fọ’hùn bí ọmọ-ènìyàn. Kò ní sí ohun kankan t’ó njẹ́ ebi ní ilẹ̀ Yorùbá mọ́. Ilé-ìwé-ọ̀fẹ́ ni fún gbogbo wa. Oríṣiríṣi ànfààní ni ó wà nínú Àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè fi rán Màmá wa, MOA, sí àwa ọmọ Yorùbá.

Iṣẹ́ tí wọ́n rán àwọn ọ̀dàlẹ̀ wọ̀nyí ni wọ́n nṣe – pé kí wọ́n lè pa wá run, kí àwọn amúnisìn ó wá máa kó àlùmọ́nì ilẹ̀ wa lọ. A ò gbọdọ̀ gbà fún wọn. Olódùmarè fi oríṣiríṣi àlùmọ́nì sí inú ilẹ̀ wa. Tí a bá ti bẹ̀rẹ̀ sí mú Àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè gbé fún wa, wá sí ojú-ìṣe, kò sí pé a máa máa san èlé lórí ẹ̀yáwó. Onjẹ á pọ̀ ní ìlú; àgbẹ̀ á lọ sí oko; iná mọ̀nọ̀mọ́nọ́ á wà. Ẹ jẹ́ kí á dìde, àsìkò ré fún wa.

Ẹnikẹ́ni tí ó bá pe ara rẹ̀ ní Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P), ní ìkóríta tí a dé yí, ṣùgbọ́n tí ó ńfi itọ́ dúdú sínú, tó ńtú funfun sí ìta, máa parun, tìdílé tìdílé.

Gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P) ti orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y), ẹ jẹ́ kí a fi ọwọ́sow’ọ́pọ̀, kí a fi ìmọ̀ sọ̀kan, kí a lé gbogbo àwọn àgbà òfò àti àwọn ọ̀tá inú ilé ilẹ̀ Yorùbá yí jìnnà. 

Ẹlẹ́tàn ni wọ́n, àwọn amúnisìn ni gbogbo wọn ń ṣiṣẹ́ fún. Oríṣiríṣi àìsàn ni wọ́n ń dà síta, àwọn ará ìlú kò rí oúnjẹ jẹ,

nígbà tí púpọ̀ ọmọ tiwọn kò kúkú sí ní ilẹ̀ Yorùbá. Ìyà yí tó gẹ́ẹ́! Ọgọ́rùn-ún ọdún ti pé tí àwọn amúnisìn so irun iwájú pọ̀ mọ́ ti ìpàkọ́, ẹ jẹ́ kí a dìde láti gba ara wa sílẹ̀. Gbogbo wa ni a wáyé wá ṣe rere, ṣùgbọ́n wọn ò fẹ́ rere fún ẹnikẹ́ni nítorí ìdí ìbàjẹ́ ni gbogbo wọn ti ń jẹ. 

Wọ́n ń ta àwọn àlùmọ́ọ́nì tó yẹ kó wà fún ìgbá’yé gbádùn gbogbo wa fún àwọn amúnisìn láàárín ara wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n mọ̀-ọ́-mọ̀ ń fi ebi pa àwọn ará ìlú, àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ wá bẹ̀rẹ̀ sí í ní oríṣiríṣi àìsàn látàrí àìrí oúnjẹ tó dára jẹ́. Ṣé bí àwa ọmọ Aládé yóò ṣe máa wòran nìyí? Ẹ jẹ́ kí a mú ìbẹ̀rù kúrò, nítorí àgbàrá ò lóhun ò ní’lé wó, onílé ni ò ní gbà. Ẹ jẹ́ kí a fi yé wọn pé àwa ni a ni ilẹ̀ àjogúnbá wa. Kí wọ́n kò orí burúkú wọn lọ sí ìlú arírimáṣe Nàìjíríà

Gbogbo àwọn àlùmọ́ọ́nì tí wọ́n fi ń ṣe bààlúù, tí wọ́n fi ń ṣe títí àti oríṣiríṣi ohun mère-mère inú ilẹ̀ Yorùbá ni wọ́n ti ń ko, ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ni Olódùmarè fún wa ní ilẹ̀ Yorùbá. Ṣùgbọ́n àwọn alájẹbánu yí nìkan ló ń kó gbogbo rẹ̀ àti ìdílé wọn. Àkókò ti wá tó fún wa báyìí láti dìde, Olódùmarè ti gba orílẹ̀ èdè wa fún wa. Àwọn àlàkalẹ̀ ètò tí Olódùmarè gbé lé màmá wa ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla lọ́wọ́ kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbádùn, kò ní sí ebi mọ́ ni ilẹ̀ Yorùbá, 

iṣẹ́ yóò wà lọ́pọ̀ yanturu, iná mọ̀nà-mọ́ná wa kò ní sẹ́jú, ètò ẹ̀yáwó tí kò ní èlé yóò wà fún àwọn oníṣòwò, ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ àti ìlera ọ̀fẹ́ ìwọ̀nyí àti àwọn àǹfààní mìíràn ni ó wà nínú àlàkalẹ̀ náà. 

Ní àkótán, ẹ jẹ́ kí a sọ́ra gidi, nítorí àwọn ọ̀dàlẹ̀ tí wọ́n wà ní àárín wa, kí Ọlọ́run Olódùmarè pa gbogbo wọn run, gbogbo àwọn tí wọ́n ń fi ẹ̀jẹ̀ sínú tu itọ́ funfun síta fún àwọn ọmọ Yorùbá, àwọn ṣ’eku-ṣ’ ẹyẹ, wọn ò ní jẹ ire ilẹ̀ Yorùbá láé, gbogbo wọn máa parun ni. 

Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a sa gbogbo ipá wa, kí a lé àwọn ajẹgàba yí dànù kúrò lórí ilẹ̀ wa, kí a sì bẹ̀rẹ̀ sí í  jẹ ìgbádùn àlàkalẹ̀ ètò tí Olódùmarè fi rán màmá wa MOA sí ìran Yorùbá. 

Ọ̀rọ̀ yí wá láti ẹnu bàbá wa BLACK LION..