Láti ìgbà ìwásẹ̀ ni Olódùmarè ti fún àwọn babańlá wa ní ọgbọ́n, ìmọ̀ àti òye, láti lè bá ewé sọ̀rọ̀, àti oríṣiríṣi ohun tí ó wà ní àyíká wa; bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ní ìmọ̀ àwọn ohun tí èwé, egbò, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ le ṣe, pàápàá ní àgọ́-ara.
Èyí ló ṣe okùnfà oríṣiríṣi ìwòsàn tí àwọn babanlá wa ní fún àwọn àìsàn tàbí àrùn tí ó bá yọjú; bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń fi àwọn ń kan wọ̀nyí kọ́ àwọn ọmọ láti ìran-dé-ìran.
Ara ń kan tí àwọn òyìnbó rí nìwọ̀nyí tí wọ́n fi sọ pé ètò ẹ̀kọ́ wa wà lókè ju ti àwọn lọ, àti pé ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ láti ayébáyé ni; ṣùgbọ́n nínú ìwà ìkà wọn, wọ́n pinu láti gbàá lọ́wọ́ wa, wọ́n wá gbé tiwọn fún wa.
Gbogbo nǹkan wọ̀nyí, nípele nípele, ni Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ọlá Onítirí-Abíọ́lá sì ń fi yé wa ní ìgbà-dé-ìgbà, tí wọ́n sì sọ fún wa pé ètò ìwòsàn ní Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) máa dá gbogbo ìmọ̀, agbára àti ẹkọ́ nípa èwé àti egbò tí a ti ní láti ìpinlẹ̀ṣẹ̀ padà fún wa.
Èyí túmọ̀ sí pé ètò ìwòsàn wa ní D.R.Y máa rinlẹ̀ gidi, àjínde ara á máa jẹ́ fún wa nípasẹ̀ èwé àti egbò tí Olódùmarè fi dá wa lọ́lá. Òpin ti dé sí àìrójú àìrayè tí àìsàn ń fà fún’ni.
Gẹ́gẹ́bí Màmá ṣe sọ fún wa, ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn ní àgbáyé yí ló jẹ́ pé ọ̀dọ̀ àwa Yorùbá ni wọ́n ti máa ní ìwòsàn sí ń kan tí wọn kò rí ojútu rẹ̀ láti ìgbà pípẹ́ wá! A dúpẹ́ lọ́dọ̀ Elédùmarè tí ó fi Ìránṣẹ́ Rẹ̀ ṣe atọ́nà fún wa.