Ohun kan tí ó dájú fún gbogbo ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá ti Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, ni pé, àfi ẹni tí kò bá fẹ́ ṣe iṣẹ́, nìkan, ni kò ní rí iṣẹ́ tó wùú láti ṣe, tàbí láti dá sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ó máa rí owó t’ó tó owó ní’di rẹ̀.
Ìyá wá, Màmá Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá ti fi yé wa pé kò ní sí ìnira fún ẹni tí ó bá fẹ́ ṣe òwò káràkátà, àti fún ẹni tí ó fẹ́ dá ilé-iṣẹ́ sílẹ̀. L’ọnà kíní, owó àti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ kò ṣ’oro nítorí ìjọba Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá máa ṣe ìrànlọ́wọ́ owó fún ẹni t’ó bá ní’lò rẹ̀, tí yíò dẹ̀ dẹ’rùn fún oníṣòwò tàbí adá’lé-iṣẹ́-sí’lẹ̀ náà láti san padà.
Ọ̀nà kéjì, ètò agbára iná mọ̀nọ̀mọ́nọ́ àti títì pópónà tí ó dára ti wà nínú ìgbékalẹ̀ Orílẹ̀-Èdè wa, èyí tí ó fi jẹ́ pé òwò ṣíṣe àti ilé-iṣẹ́ dídásílẹ̀ kò ní le kokoko.
Ohun míràn tí ó tún wà fún ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá, ni pé, ohun ìṣẹ̀dá’lẹ̀ wa ni gbogbo iṣẹ́ wa máa dúró lé lórí, èyí tí ó túmọ̀ sí pé a máa lo ohun tí ó jẹ́ tiwa, tí ó bá ìṣẹ̀dá wa mu, tí ó bá àṣà wa mu, tí kò lòdì sí ìpín wa tàbí sí ìfẹ́ Olódùmarè fún ìgbésí-ayé ọmọ Yorùbá.
Bẹ́ẹ̀ náà ni a ti gbọ́ pé a ò ní máa ta ohun àlùmọ́ọ́nì wa sí’ta láì ṣe pé a ti ṣe iṣẹ́ síi l’ara tí ó fi máa ní’yé lórí. Gbogbo ohun tí a máa lò láti gbé iṣẹ́ àrọdá jádé, nílátí wá láti ilẹ̀ wa. Tí eléyi kò bá wa ṣeéṣe, a le wá irú nkan bẹ́ẹ̀ láti ilẹ̀ aláwọ̀dúdú, ṣùgbọ́n kìí ṣe láti Nàìjíríà. Ìyẹn bẹ́ẹ̀.
Ohun tí a bá nílò ni a máa ṣe, ohun tí a bá dẹ̀ ṣe ni a máa lò.
Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ti sọ fún’wa pé kí á máa ronú àwọn nkan tí a le ṣe, bẹ̀rẹ̀ láti ohun kékèké bí ìgbálẹ̀ tí ó rọrùn láti lò, ohun ìyọ’yín lẹ́hìn tí a bá ti jẹun, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.
Bẹ́ẹ̀ náà ni a ti gbọ́ pé ní àkọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀, àwọn nkankan wà tí ó jẹ́ pé tí ó bá ti ṣe ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá ni ó kó wọn wọ Orílẹ̀-Èdè wa, kò ní sí owó ìk’ọjà-wọ’lú lórí wọn; àwọn ìjọba wa yíò máa fi yé wa, irúfẹ́ àwọn ọjà wo ni eléyi, àti fún àkókò ìgbà wo.
Màmá wa sì ti sọ fún wa bákannáà pé, gbogbo ẹni tí ó bá nkó òṣìṣẹ́ lọ sí ibi iṣẹ́-ṣíṣe, nláti ní ètò adojút’ofò fún ẹnikọọkan wọn! Bẹ́ẹ̀ náà ni a ti gbọ́ pé, ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, ọ̀sẹ̀ méjì-méjì ni owó iṣẹ́, kìí ṣe oṣooṣù.
A ti sọ fún wa, bákannáà, pé, gbogbo ẹni tí ó bá máa gba iṣẹ́ ṣe lọ́wọ́ ìjọba ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, kò lè rí àyè yan ará ìlú jẹ, nítorí ohun gbogbo ni ó gbọ́dọ̀ hàn kedere sí ojú ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá.
Láì sí àní-àní, ìgbà ìrọ̀rùn ti dé, fún gbogbo ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P) ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y)