Ní ìlú Lọ́kọ́ja, ìpínlẹ̀ Ìṣèjọba Ọ̀yó (Old Oyo Empire)̣, Orílẹ̀-Èdẹ wa, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) ni ó ti ṣẹlẹ̀, Agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà tún ti ṣe bí wọ́n ṣe nṣe!

Ẹ̀mí ọmọ ènìyàn kan tún ti lọ! Látàrí ìwà burúkú, ìwà ìpànìyàn tí ìjọba agbésùnmọ̀mí nàìjíríà ti gbélé àwọn ènìyàn lọ́wọ́! Jẹ́jẹ́ ni ọmọbìnrin náà nlọ, ní agbègbè Fẹ́lẹ̀lẹ̀, níwájú “blue gas station” ní Lọ́kọ́ja wa, ìlú ológo; tí wọ́n sì wá ọ̀nà láti fàá lọ sí ibòmíràn ní’bi tí wọ́n ti fún-un l’ọrùn pa, tí wọ́n sì yọ ẹ̀yà ara ẹ̀.

Agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà kúrò lórí ilẹ̀ wa, Democratic Republic of the Yoruba! D.R.Y kì ńṣe ara apaná ògo Nàìjíríà! Ohun tí ẹ nṣe yí, ẹ máa j’ìyà rẹ̀! Kò bá dára kí ẹ tètè já’wọ́!

Democratic Republic of the Yorùbá daily newspaper

Tí afipá jẹ gàba Nàìjíríà bá jẹ́ ọmọlúàbí ni, (èyí tí ó jìnà sí wọn gbáà, tí wọn ò lè jẹ́); kí wọ́n ti kúrò l’orí ilẹ̀ wa ní kété tí a ti bẹ̀rẹ̀ ìjọba D.R.Y ní ọjọ́ kéjìlá oṣù igbe ọdún tí a wà nínú rẹ̀ yí, ìgbáyé-gbádùn ọmọ Yorùbá, ní ilẹ̀ Yorùbá, kò ní fi àyè sílẹ̀ fún irú ìṣe búburú yìí, ẹnikẹ́ni kò sí ní máa pèrò làti ṣe ẹlòmíràn ní’bi.

Gbogbo ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yorùbá, a kú ìrọ́jú o! Gbogbo èyí máa d’opin l’aìpẹ́!

A máa rí ẹ̀yìn agbésùnmọ̀mí nàìjíríà; bẹ́ẹ̀ ni wọ́n máa jẹ gbogbo ìyà tí ó tọ́ sí wọn. Kí a máṣe gbàgbé, ìjọba-Adelé wa nbá iṣẹ́ lọ! Wọn ò dúró; kí a máṣe rò pé orílẹ̀-èdè wa ndúró; ajẹgàba Nàìjíríà máa tó tẹ́!