Ẹni tí Olódùmarè bá ti ṣe àánú fún, kí ó máṣe fi ọwọ ara rẹ̀ tún fa ara rẹ̀ sẹ́yìn –, ojúlówó ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), a ò níí fún’ra wa fa ara wa sẹ́yìn.
Ṣùgbọ́n, àwa fúnra wa ni a máa ṣọ́ ara wa ní gidi! Èdùmàrè ti ṣe wá lógo, a ò gbọ́dọ̀ tún já ara wa kulẹ̀.
Ní àìpẹ́ yí ni Màmá wa tún bá wa sọ ọ̀rọ̀, ó sì di dandan kí á fi ọkàn si: Màmá wa, Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá-Ààfin) gbé ohùn sí ìta, wọ́n ní, Gbogbo I.Y.P ti D.R.Y, tí ó dúró tán, tí wọ́n jẹ́ I.Y.P ti D.R.Y ní òtítọ́ àti ní òdodo, Ẹ yéé fi etí sí ọ̀rọ̀ ráda-ràda káàkiri!
Ẹ yéé fi etí sí àwọn ọ̀dàlẹ̀, ẹ yéé fi etí sí ọ̀rọ̀ tó bá tako, tàbí lòdì sí ohun tí Olódùmarè ti gbé fún wa, nípasẹ̀ Màmá wa, MOA.
Màmá wa MOA sọ pé kí a yéé fi etí sí àwọn ìkà, àwọn tí ó lòdì sí Àlàkalẹ̀ (BluePrint) tí Olódùmarè gbé fún Ìran Yorùbá nípasẹ̀ àwọn.
Ẹ jẹ́ kí á ṣọ́ra fún ohun tí a ngbọ́ lórí ẹ̀rọ ayélujára. Ẹ máṣe jẹ́ kí á sọ pé mo fẹ́ mọ bóṣe nlọ, kí á wá máa lọ sí oríṣiríṣi ìkànnì láti lọ máa gbọ́ ọ̀rọ̀ tí kò ṣe àǹfààní tí wọ́n nsọ níbè.
Nígbàtí a ti mọ irúfẹ́ àwọn tí ó wà níbẹ̀, pé wọn ò fẹ́ ire fún D.R.Y, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò fẹ́ ire kankan fún I.Y.P ti D.R.Y.
Àwọn wọ̀nyí, a ti mọ̀ wọ́n tẹ́lẹ̀-ẹ. A mọ̀ pé wọn ò fi ara mọ́ D.R.Y, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ ọ̀dàlẹ̣̀ ni wọ́n. Àwọn ni wọ́n nṣi ọmọ-Yorùbá lọ́nà.
Kíni a nwá kiri gan? Kíni a nwá kiri lórí àwọn ìkànnì tí ó nda ọkàn wa rú? Màmá wa MOA ní, àwa I.Y.P òtítọ́, ti D.R.Y, ẹ jẹ́ kí a fọkàn balẹ̀, ẹ máṣe jẹ́ kí á máa fetí sí gbogbo rádaràda.
MOA ní, ẹ jẹ́ kí ẹni tó bá fẹ́ máa kóra wọn jọ fún aburú, ẹ jẹ́ kí wọ́n máa tẹ̀síwájú láti máa kóra wọn jọ. Wọ́n ní kìkìdá kí á kàn gba ohùn wọn sílẹ̀ ni, kìí ṣe pé kí á jẹ́ kí nkan tí wọ́n bá sọ ó dà wá láàmú. Wọ́n ní èyí nínú àwọn ẹni ibi wọ̀nyí tí ó bá ya wèrè lórí ayélujára, kí á fi sílẹ̀ kí ó ya wèrè.
Èyí nínú wọn tí ó bá nfi ọrọ̀ rádaràda sílẹ̀ káàkiri ìkànnì, ẹ jẹ́ kó fi sílẹ̀. Ẹ̀rí tí ó máa kó wọn sí wàhálà ni wọ́n nfi sílẹ̀-ẹ. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ á sì fi ojú winá ìdájọ́ ọ̀ràn tí ó ndá. Ìyẹn di dandan.
Ẹ jẹ́ kí wọ́n máa fúnra wọn kó ẹ̀rí-ìdájọ́ ara wọn jáde – ẹ̀rí tí a máa fi dá wọn lẹ́jọ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀rí-ìdájọ́ wọn kúkú ti wà nílẹ̀ tẹ́lẹ̀.
Màmá sọ pé, àwa I.Y.P, ẹ jọ̀wọ́, ibi tí àwa nlọ ni kí á f’ojú sí; wọ́n ní kí á dúró ṣinṣin kí á sì ṣe òtítọ́ sí ìgbàlà tí Olódùmarè ṣe fún’wa yí.
Màmá wá MOA sọ pé, iṣẹ́ pọ̀ tí a máa ṣe. Wọ́n ní kí oníkálukú wa bẹ̀rẹ̀ sí ni ròó, bí òun ṣe máa kó ipa kan tàbí èkejì – bóyá ní ètò ẹ̀kọ́ ni tàbí nkan míràn, nígbàtí a bá bẹ̀rẹ̀ sí níí gbé Àlàkalẹ̀ náà jáde.
Màmá sọ pé ohun tí ó yẹ kí onikálukú wa máa sọ báyi ni pé báwo ni mo ṣe máa rí ipa tèmi kó nínú Àlàkalẹ̀ náà, báwo ni Àlàkalẹ̀ náà ṣe máa ṣe mí ní ànfààní? Ìyẹn ló yẹ kó jẹ wá lógún báyi, kìí ṣe fífi etí sí ọ̀rọ̀ rádaràda káàkiri!
MOA sì ti sọ pé, ní ti ẹ̀yáwó fún àwọn nkan tí a fẹ́ ṣe gẹ́gẹ́bí ẹnìkọ̀ọ̀kan, wọ́n ní nípele-nípele ni ó máa máa kàn wá díẹ̀-díẹ̀; ṣùgbọ́n kò ní sí ẹni tí kò ní rí tiẹ̀ gbà, níwọ̀n-ìgbà tí o bá ti jẹ́ ọmọ-ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P).
Màmá wa MOA sọ pé kí àwa I.Y.P kí a máṣe fi etí sí gbogbo rádaràda tí àwọn ọ̀tá wọ̀nyí nsọ mọ́!
Màmá ní kò di dandan kí ojúlówó I.Y.P lọ ma gbọ́ àwọn ọlọ́rọ̀ rádaràda wọ̀nyẹn.