Olódùmarè, Ẹlẹ́da Ọmọ Yorùbá àti Olùṣẹ̀dá Ilẹ̀ Yorùbá, olùṣẹ̀dá àwọn babanlá baba wa, Ẹni tí Òun Fún’ra rẹ̀ jíìnkí ilẹ̀ Yorùbá pẹ̀lú agbára ẹ̀mí, agbára Ìṣẹ̀dálẹ̀, Agbára Ìwòsàn, àti bẹ́ẹ̀-bẹ́ẹ̀ lọ, ni ó fi oríṣiríṣi iìnkan àti Agbára wọ̀nyí ṣe Yorùbá àti Ilẹ̀ Yorùbá lọ́jọ̀, pé kí a máa lò wọ́n fún ìgbélékè ìgbésí ayé wa; lọ́nà kíní, kí ẹ̀mí wa, ẹ̀mí ọmọ Yorùbá ó lè jogún irúfẹ́ agbára tí Èdùmàrè fúnra Rẹ̀ ti fi sí ilẹ̀ àti àyíká àti òfúrufú wa, kí á le jẹ́ ẹ̀yà tí yíò máa máa wà títí, nítorí Àkọ́dá Elédùmarè ni a jẹ́, Ẹni ti Olódùmarè fúnra Rẹ̀ jogún Agbára Rẹ̀ fún; pé kí àwa Yorùbá, nínú Ọlánlá àti ipò gíga tí òun Ẹlẹ́da fi ‘wa sí, nínú ayé yí, kí á le fi Agbára, Ìmọ̀, pẹ̀lú Ògo Yí ṣe Àkóso Ayé yí fún òun.
Ìdí ni’yí tí ó fi fún wa ní Ilẹ̀ àti Àyíká tí ó lógo, tí ó kún fún Ìmọ̀, pé kí àwa ọmọ Yorùbá ó lè máa Túmọ̀ Àyíka wa yí, láti lè mọ Òun Ẹlẹ́da wa si: ìbá ṣeé pé a ti tètè kọ’bi ara sí èyí ni, àwa ni Èdùmàrè jogún àkóso Àgbáyé fún, ní Rere!
Olódùmarè, jọ̀wọ́ dárí Ẹ̀ṣẹ̀ wa yí Jì wá! Kí ó ṣí ojú wa sí Ìtúmọ̀ àyíká wa, kí á le rí Ògo Rẹ, àti Ọ̀rọ̀ Rẹ, tí ìwọ nsọ sí wa, lójoojúmọ́, kí Ọ̀rọ̀ yí lè ṣe Ìtọ́nà fún wa, bí O ṣe nsọọ́ sí wa, láti igi wa, láti Omi wa, láti àjà inú Ilẹ̀ wa, bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, nítorí ìwọ ni Alágbára, o sì gbé Agbára yí Lé Yorùbá lọ́wọ́, ká fi ṣe Àkóso Ayé yí fún Ọ, ìwọ Olódùmarè.
Jọ̀wọ́, bá wa ṣíjú wo ọ̀rọ̀ Rẹ, àti Ògo Rẹ, tí O ti kọ, tí O sì fi sí inú Omi Àjàbọ́ ti Ẹ̀rìn-Ìjèṣà; máṣe jẹ́ kí Omi yí kí ó kígbe kú!
Ojojúmọ́ ni Ó nkígbe, tí Ó sì npè wá, pé Kí á bojú wo Òun; òun nbá wa sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n a ò fetí sí ohun tí òun nsọ; Olódùmarè, jọ̀wọ́ má ṣe jẹ́ kí Omi Àjàbọ́ Ẹ̀rìn-Ìjèṣa kí ó bínú sí wa mọ́: a mọ̀ pé Angẹ́lì Rẹ, ìkan nínú àwọn Ángẹ́lì tí Ìwọ Olódùmarè sọ L’ọjọ̀ ni, sí ilẹ̀ Yorùbá, pé, tí a bá ti nri, kí Ìmọ̀ kí Ó máa sọ nínú wa; kí òye àyíká wa, kí Ó máa sọ, kí ó di Ìwòsàn fún wa; kí Ìgbàlà ní Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ó lè jẹ́ àjogún Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá, kí ilẹ̀ Orílẹ̀-Èdè wa, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, ó le jẹ́ Odi Agbára yí wa ká; kí Ọ̀tá kankan má ṣe lè borí wa, ṣùgbọ́n kí Àwọn Ọmọ Wa, láti Ìran-dí-‘Ran, ó le jogún ayé yí; kí wọ́n dúró gẹ́gẹ́bí Ìmọ́lẹ̀ Olódúmarè; kí ayé ó rí Wọn, kí ayé sì máa júbà ìwọ Ọlọ́run Ọ̀gá-Ogo, nítorí wọ́n ṣe àbápàdé Ògo Rẹ̀ nínú Ẹ̀yà náà tí ìwọ ti Yàn, Ẹ̀ya Ìran Ọmọ Yorùbá.
Ní àìpẹ́ yí ní a rí fọ́nrán tí ó fi hàn, bí àwọn ẹ̀dá ọmọ ènìyàn ṣé kó ìdọ̀tí wọn sí Ẹ̀bá Omi-Àjàbọ́ Ológo yí: ó ṣe’ni láanú, ó ti’ni lójú, ó gba ẹkún lójú ojúlówó ọmọ-ìbílẹ̀ Yorùbá, pé, ìkan nínú àwọn pàtàkì Angẹ́lì Oódùmarè sí Ìran Yorùbá ni wọ́n ṣe irú ìdọ̀tí báyi lé lórí!
Èdùmàrè, jọ̀wọ́, ṣílẹ̀kùn Àyọ̀ fún Ìjọba-Adelé wa, láìpẹ́; kí o fi Àánú rẹ Ṣí’dí ọ̀tá wa, Nàìjíríà, kúrò ní ilẹ̀ Wa, kí á le Rí Ojú-Rere rẹ, nígbàtí Ìjọba-Adelé wa bá wọnú àwọn ilé-iṣẹ́ wa gbogbo lọ, láti ṣe Àkóso ilẹ̀ Yorùbá; inú wa kí ó Dùn, tí A Ó sì máa kọrin Ogo Rẹ, bẹ́ẹ̀ ni àwọn Angẹ́lì tí o fi yí wa ká wọ̀nyí, bí Omi-Àjàbọ́ Ẹ̀rìn-Ìjèṣà, yíò fò fáyọ̀, pé, Ìgbàlà Ọmọ Yorùbá ti dé: wọn ó sì fọhùn sí wa: Ìran Ọmọ Aladé yíò sì gbọ́ Ọ̀rọ̀ Rẹ Nínú Ohùn wọn: Ẹ̀mí yíò kan Ẹ̀mí, a ó sì máa yìn ọ́ títí Ayé, ṣebí O ti sọ̀ọ́ pé ìfarahàn Rẹ wà nínú àwọn ohun tí o dá; Olùgbàlà tí O dẹ̀ rán sí’wa, Ìránṣẹ Rẹ, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, ti sọ fún wa pé, Ohun gbogbo tí ìwọ Olódùmarè dá, ni ó ní Ẹ̀mí tirẹ̀: Omi-Àjàbọ́, Ẹ̀rìn-Ìjèṣa, Fọ’hùn sí wa, ní Orúkọ Olódùmarè, kí Inú Ọmọ Yorùbá Ó dùn, kí àwọn Ọ̀tá ó ṣègbé.