Ìròyìn kan tí a tún rí gbọ́ ni wípé, ọkùnrin sátánì nì, BILL GATES, ti ta gbòǹgbò kiri ayé, bẹ́ẹ̀ ni òun ni ó bẹ̀rẹ̀ ìmùnisìn ìgbàlódé ní Áfríkà nípasẹ̀ nǹkan ọ̀gbìn, ilẹ̀, àti oúnjẹ. Afrika kò le gbin ohun tí ó wù wọ́n, wọn ò le ṣètò ilẹ̀ wọn bí ó ti wù wọ́n, wọn ò le ṣe ìpèsè irú oúnjẹ tó wù wọ́n fún’ra wọn!
Ohun tí Bill Gates bá ní kí wọ́n gbìn, ohun tó bá ní kí wọ́n máa jẹ, bí ó bá ṣe ní kí wọ́n ṣe ilẹ̀ wọn ohun tí ó bá ṣáà ti sọ, òun ni kí Afrika máa ṣe! Ìmúnisìn ìgbàlódé tí Bill Gates fi Afrika sí nìyẹn. Ṣùgbọ́n àwa Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) ti bọ́ o!
Bẹ́ẹ̀ ni ó ti mú ìpèsè irúgbìn ní gbogbo àgbáyé kí ó wà ní ìkápá òun.
Èyí tí ó sì ti ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn bi tirẹ̀ ní gbogbo àgbáyé. Èyí kìí ṣe ìlú Afrika nìkan, pàápàá jùlọ ní ìlú India, òun ló mú ìjánu ìgbìmọ̀ tó ń ṣe ìwádi-ohun-ọ̀gbìn wọn dání. Bẹ́ẹ̀ ni ó ti dá ètò kan sílẹ̀ ní India fún bí yóò se fi òpin sí ètò òhun ọ̀gbìn àbáláyé lóríṣiríṣi, láti bàá jẹ́, kí ó sì di ohun ìgbàgbé. Òun ni àgbẹ̀ tí ó ni oko tí ó tóbi jùlọ ní ílú America.
Adúpẹ́ lọ́wọ́ Olúwa fún ìyá wa, Ìyá Àfin Modupẹ Onitiri-Abiọla tí Olódùmarè lò láti yọ wá kúrò nínú ogun apànìyàn-sára Bill Gates, ẹni tí ó ń wá ọ́nà láti dín àwọn ènìyàn kù lórílẹ̀ ayé, nípa ohun ọ̀gbìn ayédèrú tó ti wà lóde láti ọdún pípẹ́ sẹ́yìn, kó tó di wípé ásírí rẹ̀ wá tú sí ọwọ́ ọmọ Yorùbá, nípa bí Ìyá wa ṣe là wá lójú, tí Olúwa sì tì wọ́n lẹ́yìn.
Orílẹ̀-Èdè Demoratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), kò ní fi ààyè gba irú eléyi ní orílẹ̀ édé tuntun ilẹ̀ wa. Ìrànsẹ́ sátánì Bill Gates yí,
kò bìkítà láti pa ayé run rárá, sùgbọ́n irọ́ ni. Yorùbá bọ̀, wọ́n ní abẹ́rẹ́ bọ́ lọ́wọ́ adẹ́tẹ̀ ó ti di ète, nípasẹ̀ Ìya wa Modupẹ Onitírí-Abiọla.
Bóyá ni ọmọ Yorùbá Olómìnira Tiwantiwa mọ rírì ohun tí Ìyá wa ṣe fún wa, tí ó yọ wá kúrò nínú òṣì àti àdánù ilẹ̀ ajíríyà nàìjíríyà. Èkejì, wọ́n tún gbà wá lọ́wọ́ ikú òjijì nípa ohun-ọgbìn-oko àyédèrú tí àwọn amúnisìn rán Bill Gates láti ṣe alákoso ohun búburú náà lágbayé.
Ọ̀nà àbáyọ fún Yorùbá ní bí a ti ṣe ní Orílẹ̀-Èdè tiwa yí; èyí tí a ti ní, láti ogúnjọ́ osù Bélú ní ẹgbàá ọdún óléméjìlélógún, tí a sì ti bẹ̀rẹ̀ iṣèjọba wa láti ọjọ́ kéjìlá oṣù Igbe ẹgbàá ọdún ólé mẹ́rìnlélógún. Èyí nìkan kọ́, Olórí Ìjọba Adelé wa, Bàba wa, Mọbọlají Ọláwale Akinọla Ọmọkọrẹ, pẹ̀lú àwọn adelé wa ‘yókù sì ti wà ní sẹpẹ́ láti bọ́ sínú oríkò ilé-iṣẹ́ ìjọba wa gbogbo, gẹ́gẹ́bí ipò wọn láti tẹ̀síwájú nínú ìṣèjọba tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀, kété tí Èdùmàrè bá ti ṣe ìfarahàn bíbá wa lé àwọn ìjọba agbésúnmọ̀mí orílẹ̀ édé tí ó múlé tì wá, tí wọ́n bá ti kó ẹrù wọn kúrò ní ilé-isẹ́ ìjọba ìpínlẹ̀ wa gbogbo.
Màmá wa, Modupẹ Onítírí-Abiọla ni kí àwa ọmọ Yorùbá máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ nigba gbogbo, ẹnití ó fi ara jìn fún ìtúsílẹ̀ ọmọYorùbá.
Bill Gates ti ta gbòngbò kákiri àgbáyé, láti ri wípé ohun ọ̀gbìn tí àwọn àgbẹ̀ yòó ma gbìn, jẹ́ ti ayédèrú, kò gbọ́dọ̀ jẹ́ ti àbáláyé rárá.
Ṣé ènìyàn ni eléyí tàbí ẹranko? ẹni tó ti pinu lọ́kàn rẹ̀ láti dín àwọn ènìyàn tí Ọlọ́run dá kù lórí lẹ̀ àgbáyé.
Yàtọ̀ sí ìwà-ibi Bill Gates, ìwà ájẹbánu pọ̀ púpọ̀ láàrín àwọn ènìyàn ní àgbáyé, èyí tí ó sì wọ́pọ̀ láarín àwọn alákoso ilẹ̀ ajíríyà tí a ti kúrò.
Ìyá wa, Modupẹ Onìtírí-Abiọla, fẹ́ ìtúsílẹ̀ àwọn ènìyàn wọn kúrò nìnú ìgbèkùn àìríjẹ, àìrímu àti ikú àìtọ́jọ́.
Àwa Ọmọ orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) ẹ jẹ́ kí á máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè tí Ó ran Màmá lọ́wọ́ láti jẹ́ a-wí-bẹ́ẹ̀-ṣe-bẹ́ẹ̀. Ẹ jẹ́ kí a jọ gbárúkù ti ohun tí Ẹlẹ́da wa gbé lé wọn lọ́wọ́, kí ẹwà àti ògo òmìnira Ilẹ̀ Yorùbá le jẹ́ tiwa.
Gẹ́gẹ́bí Ìyá wa ṣe máa ń sọ pé Yorùbá kò ní kúrò ní oko ẹrú kan bọ́ sí oko ẹrú kejì. Torí ìdí èyí, gbogbo wa gbọ́dọ̀ gbáradì láti ṣisẹ́ pẹ̀lú Olórí Ìjọba-Adelé wa àti gbogbo adelé wa.