Nígbàtí a bá ngbọ́ pé àwọn òyìnbó amúnìsìn fẹ́ pa ọmọ aráyé, àwọn kan le má fẹ́ gbàgbọ́; ṣùgbọ́n òtítọ́ gedegbe ni ọ̀rọ̀ yí.
Ìba àwọn tó bá kù, tí wọn ò pa, wọ́n fẹ́ ṣe ètò kí wọ́n máṣe lè gbé irúfẹ́ ìgbé-ayé tí wọ́n fẹ́ gbé, ṣùgbọ́n kí ó jẹ́ pe àwọn tí wọ́n pe’ra wọn ní “alágbáyé” (globalists) ni wọ́n máa máa ṣe àkóso ayé àwọn ènìyàn náà.
Ká má tilẹ̀ fa ọ̀rọ̀ gùn, lára bí wọ́n ṣe npa ọmọ ènìyàn ni kí wọ́n sọ pé àrùn kan ti wà níta o, (bẹ́ẹ̀ àwọn dẹ̀ ló kó àrùn náà wá), wọ́n á wá sọ pé kí àwọn ènìyàn wá máa gba abẹ́rẹ́ àjẹsara – bẹ́ẹ̀ kẹ̀ dẹ̀ ré, wọ́n á ti fi oró sínú àjẹsára ọ̀ún láti ṣekú pa ọmọ ènìyàn; bóyá lẹ mọ̀, pé, ó ti pẹ́ tí Bill Gates ti máa nsọ pé iye ọmọ ènìyàn tí ó wà láyé yí ti pọ̀jù, àti pé wọ́n ní láti dín iye ènìyàn tó wà lágbayé kù, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ngbé oríṣiríṣi àìsàn sígboro ayé, láti ṣekú pa ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọmọ èèyàn, wọ́n á wá dẹ́rùba ‘yàn pé kí wọ́n wá gba abẹ́rẹ́ àjẹsára, bẹ́ẹ̀ dẹ̀ ni abẹ́rẹ́ yẹn gan lá tún wá túbọ̀ ṣekú pa ẹni tí kò kú tẹ́lẹ̀.
Paríparì ohun tí àwọn wèrè tó nṣe bí pé àwọn ló ṣẹ̀dá ọmọ ènìyàn yí, paríparì ohun tí wọ́n fẹ́ ni pé kí wọ́n lè gba àkóso ayé yí, nípa kíkó ìpayà fún ọmọ ènìyàn, èyí tí oníkálùkù á wá jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún wọn.
A ti gbọ́ ní àìpẹ́ yí, bí wọ́n ṣe tún ti bẹ̀rẹ̀ sí sọ ọ̀rọ̀ àìsàn kan tí ó njẹ́ mpox, èyí tí wọ́n ní ó bẹ̀rẹ̀ ní Congo, àti pé àwọn fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí gbé ìgbésẹ̀ nípa kí ó máṣe kárí ayé, irọ́ ni o! Àwọn ni ó kó mpox ọ̀ún síta!
Obìnrin onímọ̀-ìjìnlẹ̀ sáyẹ́nsì ti àwọn òyìnbó, tí ó nṣiṣẹ́ ní ilé-iṣẹ́ Bill Gates (Bill Gates Foundation), ti kígbe síta, ó ní ohun ò mọ kí ni ilé-iṣẹ́ Bill Gates ọ̀ún lè ṣe láti pa òun lẹ́nu mọ́, ṣùgbọ́n ẹ̀rí-ọkàn kò jẹ́ kí òun ó simi o, ni òun ṣe kígbé sita!
Ó ní wọ́n ti ngbé ìgbésẹ̀ ní ilé-iṣẹ́ Bill Gates ọ̀ún láti lo àwọn ọkọ̀ bàlúù ní òfúrufú, kí wọ́n fẹ́ afẹ́fẹ́ tí ó dàbí óògùn tí a fi npa ẹ̀fọn, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ èyí tí ó ní kòkòrò mpox tó lágbára gidi, kí wọ́n fẹ sí òfúrufú, kí mpox wá di àjàkálẹ̀ àrùn tí gbogbo ayé á wá máa ṣe ríborìbo, gẹ́gẹ́bí ìgbà Covid, àwọn èèyàn kò gbọdọ̀ jáde; wọ́n á di zombie, ibi tí àwọn globalists wọ̀nyí bá ti ní kí wọ́n dúró sí ni wọ́n máa dúró sí, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Àsẹ̀yìn wá, àsẹ̀yìn bọ̀, àwọn wèrè Bill Gates àti àwọn tó rán-an níṣẹ́, wọ́n á wá sọra wọn di apàṣẹ lórí gbogbo àgbáyé, ibi tí wọ́n bá ní kí èèyàn rìn sí ni wọ́n gbúdọ̀ rìn sí, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Wọ́n npèé ní “New World Order.”
A ní kí á fi tó wa létí ni o, kìí ṣe kí á páyà; rárá o! Gbígbé tí Olódùmarè gbé Màmá wa dìde, Ìránṣẹ́ Ẹlẹ́da wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, ní déédé àsìkò yí, ní déédé ìgbà yí, gẹ́gẹ́bí Màmá ṣe máa nsọ, pé kí á padà sí orísun wa, ó jẹ́ ìgbésẹ̀ gbòógì ní àgbáyé yí, láti ri pé, pẹ̀lú Àṣẹ Èdùmàrè, Ìran Yorùbá kìí ṣe èyí tí Bill Gates tàbí ẹnikẹ́ni lè da ayé rẹ̀ rú.
❗PÀJÁWÌRÌ FÚN ÀÀBÒ❗KÁÀKIRI GBOGBO ÌPÍNLẸ̀ YORÙBÁ TÍTÍ DÉ OLD Ọ̀YỌ́ EMPIRE, Ẹ MÁA YA FỌ́TÒ FÚLÀNÍ, OLỌ́PA, OLÓṢÈLÚ, SÓJÀ, TÍ Ẹ BÁ FURA SÍ ÌRÌN ÀTI ÌṢESÍ WỌN NÍ AGBÈGBÈ YÍN. KÍ Ẹ FI ṢỌWỌ́ SÍ BÀBÁ ÌJÌNLẸ̀ +905367341665 (WHATSAPP). (ÌKÉDE… Pín Sórí Àgbàgbé X (Twitter)Nítorí náà, àwa ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), kí a má ṣe rò pé irọ́ ni gbogbo nkan tí ó nlọ nígboro ayé tí ẹ bá ti ngbọ́ tí wọ́n nsọ̀rọ̀ díndín iye ènìyàn tó wà láyé kù, ṣùgbọ́n ìyẹn kìí ṣe ìpín ti wa, a dẹ̀ tún mọ̀ pé, nísiìyí tí Olódùmarè ti bá wa gba ìjẹ́-orílẹ̀-èdè wa padà, ó ní ìtumọ̀ fún ìtúsílẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn káàkiri, nítórí pé ó ní ipa tí Olódùmarè fún Ìran wa, Ìran-Ọmọ-Aládé, nínú ayé yí, a dẹ̀ máa lékè gbogbo ọ̀tá pátápátá.
Ẹ jẹ́ kí á mọ̀ pé ohun tí Olódùmarè tìtorí rẹ̀ gbé Ìran Yorùbá sí ayé yí máa tó jẹyọ ní kíákíá. Kìkìdá kí á lé àwọn agbésùnmọ̀mí olóríburúkú Nàìjíríà kúrò lórí ilẹ̀ wa, lágbára Ẹlẹ́da wa, kí á wá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àkóso ìgbé-ayé wa àti ilẹ̀-àjogúnbá wa; kò sí amúnisìn náà tí ó le fẹ̀yìn Yorùbá balẹ̀ mọ́ láí! Ó dèèwọ̀!