Ọba ‘bìnrin ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ní ó ndarí ìlú agbèsùnmọ̀mí nàìjíríà fún ọdún mẹ́ta lẹ́yìn òmìnira òfegè tí wọ́n fún ìlú apanilẹ́kún jayé náà, tí ó túmọ̀ sí pé abẹ́ àkóso ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ní ìlú náà ṣì wà.

Ní ẹgbàá ọdún ó dín ḿẹ́tàdínlógójì, àwọn olórí ìlú náà gbé ìgbésẹ láti yọ ọwọ́ ọba ‘bìnrin ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti ìjọba rẹ̀ kúrò nínú ìṣèjọba ìlú agbèsùnmọ̀mí nàìjíríà, wọ́n ṣe òfin pé ètò ìṣèjobà Olómìnira ní ìlú náà yíó máa lò.

Èyí túmọ̀ sí pé ọba ‘binrin ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tàbí ọba kankan kò ní àṣẹ mọ lórí ìlú tàbí nínú ilẹ̀ náà mọ́. Òfin yí ló fagilé ipò àti àṣẹ ọba pátápátá, wọ́n sì tí fi òfin náà rọ gbogbo ọba lóyè ní ìlú akótilétà nàìjíríà.

Níwòn ìgbà tí ilẹ̀ Yorùbá wà nínú ìlú agbèsùnmọ̀mí nàìjíríà nígbà náà, kò sí ọba kankan ní ilẹ̀ Yorùbá mọ́ láti ọdún náà lọ, tí ó jásí pé nígbàtí Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) dì òmìnira ní ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbàá-ọdún-ó-lé-méjìlélógún, tí a sì bẹ̀rẹ̀ ìṣèjọba-ara-ẹni, tí a sì búra wọlé fún olórí ìjọba Adelé wa, bàbá wa Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọ́kọrẹ́, ní ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbàá-ọdún-ó-lé-mẹ́rìnlélógún, kò sí ọba kankan ní ilẹ̀ Yorùbá.

Democratic Republic of the Yorùbá latest news updates

Màmá wá Olóyè Ìyá Ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla tí Olódùmarè lò fún àṣepé òmìnira wa yìí kọ́ ló rọ ọba ilẹ̀ Yorùbá l’oyè, àwọn Fulani àti olóṣèlú nàìjíríà tí ó wa ní ìjọba nígbà náà ni ó ṣe òfin tí ó yọ àwọn ọba ní ipò.

Gbogbo ọba awúrúju tí wọ́n ńfi sí ipò láti ọdún náà kò bá òfin mu, ẹ̀tàn lásán làsàn àti àgàbàgebè láti lò wọ́n fún rírẹ́ àwọn ará ìlú jẹ ni. Àwọn ọba yí jẹ̀ irin íṣẹ́ àti ẹrú tí àwọn olóṣèlú àti àwọn òyìnbó amúnisìn nlò fún àwọn iṣẹ́ búburú wọn. Ọba kankan kò lè dá àṣẹ pa, bẹ́ẹ̀ni wọn kò ní àtìlẹyìn àwọn alálẹ̀ rárá nítorí ìfẹ́ ará ìlú kò sí ní ọkàn àwọn ọba yí.

Àwọn tó wà lóri oyè báyìí kò tilẹ̀ tọ́ sí orí àpèrè náà, adé orí wọn kìí ṣe ti àbáláyé, àgbélẹ̀rọ gbáà ni. Wọn kìí ṣe aṣojú ará ìlú, aṣojú olóṣèlú, òyìnbó amúnisìn àti àpò ará wọn ni wọ́n jẹ́.