À bí ẹ ò rí iṣẹ́ tí èyí tí ó pe’ra rẹ̀ ní Ọọni ti ilẹ̀ Ifẹ̀, Ẹniìtàn Ogunwusi, rán àwọn ìjòyè rẹ̀ jáde lọ sí gbogbo àwọn ọjà ní ilẹ̀ Ifẹ̀. Èdè ẹrú kan ni ó sọọ́ báyi, medicine after death (ẹ má bínú pé mo lo èdè ẹrú). Ìtúmọ̀ ìyẹn ni, bàlúù tí ó ti fò ní Ọọni Ogunwusi ń ju ọwọ́ sí.

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

Ibo ni Ọoni wà láti ọdún tí gbogbo ọmọ Yorùbá tí ń pariwo fún ìgbàlà tí Ọọni kò sọ pé òun gbọ́, tàbí ìgbà tí àwọn ọdọ Yorùbá gbé ìpolongo lọ bàa ní ààfin nígbà tí ìrìnàjò Yorùbá Nation ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ láti dá sí gbígba ni sílẹ̀ kúrò lóko ẹrú nígbà tí ìyà pọ̀ ju, ṣùgbọ́n, dípò kí ìwọ Ọọni Ogunwusi jáde sí wọn ki ó bá wọn sọ̀rọ̀ bíi bàbà sí àwọn ọmọ rẹ̀, kí o fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀, ń ṣe ni o fi àwọn tọ́ọ̀gì rẹ àti ìbọn lé wọn dànù, tí wọ́n ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn léṣe.

Ọọni Ogunwusi náà ló wá ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ̀ pé kò gbọ́dọ̀ sí ẹlẹ́gbẹ́ jẹgbẹ́ mọ́, ó wá jẹ́ pé ẹ ò lè gbé ètò tiyín sílẹ̀, à fi ohun tí ẹ bá gbọ́ lẹ́nu ìyá wa MOA, ṣé bí wọ́n ṣe máa ń to ìlú nìyẹn ni?.

Ẹ̀ jọ̀wọ́, ẹ sọ fún Ọọni Ogunwusi pé, ṣe bí ó mọ̀ pé ìran ìs’òwò níí jèrè, níwọ̀n ìgbà tí ẹ kò rí nǹkan ṣe sí ọjà ọ̀wọ́n gógó tí àwọn ìyá lọ́jà ń rà wá tà ní ọjà, pé kí ó lè dín owó wọ’nú ọjà kí ayé le dẹ̀rùn fún ará ìlú. Yorùbá bọ̀, wọn ní, amúkun, ẹrù rẹ wọ́; ó ní, òkè lẹ ń wò, ẹ kò wo ìsàlẹ̀. Ohun tí ó yẹ kí ẹ hú légbò, ni ẹ wá ń já léwé.

Èyí ni ìmọ̀ràn àwa Indigenous Yorùbá People sí Ọọni Ogunwusi àti gbogbo ẹ̀yin onímọtaraẹni nìkan: Ẹ gbà fún ọ̀gá yín, MOA, ọkọ Nàìjíríà, ẹ pa ìtìjú tì, kí ẹ wá dara pọ̀ mọ́ àwa Indigenous Yorùbá People, kí á lè jọ jẹ ìgb’áyé gbádùn ilẹ̀ D.R.Y.