Ọkùnrin ọmọ ìlú Uganda kan ní ó sọọ́ o, ó ní ìṣòrò Áfríkà ni àwọn tí ó pe’ra wọn ní olórí, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ àwọn gan-an ni agbésùnmọ̀mí, nítorí àwọn ni wọ́n npàdí àpò pọ̀, pẹ̀lú òyìnbó amúnisìn, láti ta ara ìlú wọn sí ìgbésí ayé ìṣẹ́, látàrí kí àwọn nìkan ṣáà ti ní owó lókè okun, kí wọ́n sì máa ṣ’ọla, ṣùgbọ́n kí ó má sí ìdàgbàsókè kankan ní ìlú tiwọn ní Afríkà.

❗PÀJÁWÌRÌ FÚN ÀÀBÒ❗KÁÀKIRI GBOGBO ÌPÍNLẸ̀ YORÙBÁ TÍTÍ DÉ OLD Ọ̀YỌ́ EMPIRE, Ẹ MÁA YA FỌ́TÒ FÚLÀNÍ, OLỌ́PA, OLÓṢÈLÚ, SÓJÀ, TÍ Ẹ BÁ FURA SÍ ÌRÌN ÀTI ÌṢESÍ WỌN NÍ AGBÈGBÈ YÍN. KÍ Ẹ FI ṢỌWỌ́ SÍ BÀBÁ ÌJÌNLẸ̀ +905367341665 (WHATSAPP). (ÌKÉDE… Pín Sórí Àgbàgbé X (Twitter)
The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal

Ọkùnrin náà tún tẹ̀ síwájú, ó ní àwọn amúnisìn wọ̀nyí máà n mọ̀ọ́-mọ̀ fa ìpínyà láarin àwọn ará-ìlú níbikíbi tí wọ́n ti nfi àwọn èníyàn ṣ’ẹrú, kí wọn lè borí àwọn ènìyàn ọ̀ún; wọ́n á wá bẹ̀rẹ̀ sí jalè àwọn ènìyàn náà, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n á máa ko ohun ọrọ̀ ilú náà; lẹ́yìn gbogbo ìwọ̀nyí, wọ́n á ṣì pàpà kórira àwọn aláwọ̀-dúdú ọ̀ún síbẹ̀.

Ṣé èyí kò kúkú yàtọ̀ sí gbogbo ohun tí Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, ti nsọ fún wa láti ìgbà dé ìgbà. Ṣùgbọ́n, ohun tí ó jẹ́ pàtàkì fún àwa ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá ti Democratic Republic of the Yoruba, báyi, ni kí á fí gbogbo ìrírí wọ̀nyẹn sẹ́yìn, bí àfìsẹ́hìn tí eégún nfi’ṣọ, kí á wá kọjú sí ibi tí a nlọ gan-an gan. Wíwọlé Ìjọba Adelé wa sínú oríkò ilé-iṣẹ́ ìjọba wa gbogbo ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá ni kí á gbá’jú mọ́ báyi o, kí á lè bẹ̀rẹ̀ sí gbé ìgbé-ayé wa ní rere, ní pẹrẹu.

Ominira yoruba daily news update - the democratic republic of the Yorùbá
Ìròyìn Òmìnira Olojoojumọ – Bèrè fún ẹ̀da títí rẹ!