Ọ̀rọ̀ kan tí ó jáde lórí ẹ̀rọ ayélujára ló sọ pé Amẹ́ríkà kàn sọ pé àwọn nṣe ìjọba Tiwatiwa ni, kò rí bẹ́ẹ̀. Ọkùnrin tí ó sọ ọ̀rọ̀ yí sọ pé, ẹni yíò wù kó wà lórí àlééfà ní Amẹ́ríkà, àwọn tó ndarí Amẹ́ríkà ni àwọn oníṣòwò àti olùdókòòwò aláda-nlá!
Àwọn ni wọ́n nsọ nkan tí ìjọba máa ṣe, kì nṣe àwọn ará ìlú. Àwọn kan-náà ọ̀ún ni wọ́n nfún àwọn olóṣèlú lówó, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrètí pé wọ́n máa rí nkan gbà padà láti ọwọ́ ìjọba ni o!
Ọkùnrin tí ó sọ ọ̀rọ̀ yí wá sọ pé ó ṣe pàtàkì kí àwọn ará-ìlú ó kúkú dojúkọ àwọn ilé-iṣẹ́ aládani tí wọ́n jẹ́ aládanlá wọ̀nyí, kó jẹ́ pé àwọn gan-an ni ará ìlú máa pèníjà pé kí wọ́n ṣe ohun tó tọ́!
Ìdí ni pé àwọn ilé-iṣẹ́ aládanlá wọ̀nyí ni ènìyàn tó wà nínú èégún. Àwọn ni ó jẹ́ pé inkan tí wọ́n bá ti fẹ́ náà ni ìjọba Amẹ́ríkà máa nṣe.
Kíni eléyi ṣe kàn wá? Ó kàn wá nítorí pé kò sí nkan tí a lè ṣe kí ó jásí bí a ṣe fẹ́ gan-an gan ní Orílẹ̀-Èdè wa, Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) láì jẹ́ pé a bá tẹ̀lé Àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè ti gbé fún wa nípasẹ̀ Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá; ìdí ni pé Àlàkalẹ̀ yí ni ó máa jẹ́ kí oníkálùkù ó mọ ipò rẹ̀, àti ohun tí ó lè ṣe, pẹ̀lú èyí tí kò lè ṣe!
Àlàkalẹ̀ yí fi dandan le pé ohun gbogbo gbọ́dọ̀ wà ní ojúkorojú; nítorí èyí, kò sí pé àwọn aládanlá kan níbi kan ní wọ́n nda ìjọba síbí-sọ́hun, yàtọ̀ sí ohun tí ìlú nfẹ́!
Iṣẹ́ gidi ni eléyi máa jẹ́ fún wa, láti ri pé kò sí ẹni tí ó lè gba agbára kúrò lọ́wọ́ ará ìlú!
Ìbùkún ni fún Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y); Ìbùkún ni fún Ìránṣẹ́ Olódùmarè sí Ìran Yorùbá, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá.