Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X
The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal

A Ríkà Nínú Ìwé Ìròyìn Pilot Ti Ọjọ́ Jimo, Ọjọ́ Kẹrìnlá Oṣù Kẹfà Ọdún Ẹgbàá-Ó-Lé-Mẹ́rin-Lé-Lógún Wípé Àwọn Kan Tí Wón Pé Ara Wọn Ní Yorùbá Nation Agitators Gba’ná Jẹ Fún Àwọn Tí  Wọ́n Pe Ara Wọn Ní Gómìnà Ìwọ-Oorun Nigeria Wípé Dandan Ni Kí Àwọn Gba Òmìnira Fún Yorùbá, He Èé!, Yorùbá Èwo Tún Ní?, Ẹ Gbà Wá O, Ṣe Wón Máa Ń Gba Ìlú Kan Ní Eemeji Ni Bí?

Kàyéfì Ní Ọ̀rọ̀ Náà Jé O, Nítorí, Àwa Ojúlówó Ọmọ Yorùbá Àtàtà (Indegenous Yorùbá People), Kìí Se Ajijagbara Mó Ó, Àwa Ti Gba Ìlú Tiwa, A Ti Gba Òmìnira Tiwa, A Ti D’ìlú, A Ti Ní Olórí Adele Tí A Sì Ti Búra Fún, Wón Sì Ti Bèrè Ètò Amayéderun Ní Olókan Ọjọkan Fún Gbogbo Àwọn Ọmọ Yorùbá Àtàtà.

Ká Ìròyìn: Ìjọba Agbésùnmọ̀mí Nka Yorùbá Mọ́ Naìjíría! Hábà!

Ẹ Dúró Na!, Ọdún Wo Ni Wọ́n Tó Fẹ́ Gba Ominira Tiwọn Na?, Àyàfi Kìkì Irọ́ Láti Ọdún Mẹrin Sẹ́yìn Láì Rí Ohunkóhun Tọ́’ka Sí, Tí Wọ́n Ti Ń Pá Irọ́ Fún Àwọn Ènìyàn, Tí Wọ́n Ń Tàn Wọn Je Ní Ojojumo, Ó Mà Ṣe O.