Ní òtítọ́ àti ní òdodo, àwọn aláwọ̀funfun, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n mọ̀ pé irọ́ ni àwọn npa, síbẹ̀, wọ́n dúró nínú irọ́ yẹn láti sọ pé aláwọ̀dúdú kò já mọ́’nkankan, wọ́n sì nṣiṣẹ́ tọ̀ọ́ ní ojoojúmọ́!
Ẹ̀bi wọn náà dẹ̀ kọ́ọ; ṣébí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ìlú ní Áfríkà, nígbà tí wọ́n sọ pé àwọn gba òmìnira, ṣebí ṣe ni wọ́n túbọ̀ kó’ra wọn sí’nú ẹrú-ṣíṣé, látàrí pé wọ́n ṣì pàpà nj’abọ̀ fún àwọn amúnisìn wọn, lórí ọrọ̀-ajé wọn, l’ẹyìn tí wọ́n dẹ̀ ti sọ pé àwọn ní òmìnira! Irúfẹ́ òmìnira wo ni wọ́n wá ní o?
Ìdí nìyí tí àwọn òyìnbó wọ̀nyí ṣe nfi ọ̀bọ lọ aláwọ̀dúdú títí di àkókò yí, káàkiri; ṣùgbọ́n, pẹ̀lú ìṣèjọba-ara-ẹni Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, èyí tí ó ti bẹ̀rẹ̀ báyi, ìgbà ọ̀tun ti dé o!
Èyí ni ìgbà-àkọ́kọ́ ní àgbáyé, tí orílẹ̀-èdè aláwọ̀dúdú máa dìde pẹ̀lú òmìnira òtítọ́, tí kì nṣe òmìnira àdàmọ̀dì ! Ìdí ni’yí tí Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, ṣe sọ pé a ò níí kúrò nínú oko-ẹrú kan kí á tún lọ bọ́ sí òmíràn.
Ìròyìn tí a rí lórí YouTube, láìpẹ́, l’ó fihàn bí àwọn èèyàn tí ọ̀rọ̀ àwa tí kì nṣe aláwọ̀ ẹlẹ́dẹ̀ jẹ lógún, bí wọ́n ṣe ṣe ìjíròrò, ní orílẹ̀-èdè Netherlands, lórí bí Áfríkà ṣe lè ní ìlọsíwájú.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì nṣe ohun gbogbo tí wọ́n sọ níbẹ̀ ni a lè fara mọ́, síbẹ̀, ohun kan tí ó jẹyọ ni pé, nígbàtí wọ́n dá Àjọ-Àgbáyé sílẹ̀, ní ẹgbàá-ọdún ó-dín márun-dín-lọ́gọ́ta, wọn ò lérò àti ka àláwọ̀dúdú mọ́ ara àgbáyé ọ̀ún.
Ọpẹ́ ni kí á máa dá báyi lọ́wọ́ Olódùmarè, fún Ìyá Wa, Ìyá Ìran Yorùbá, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọlá, fún iṣẹ́ ribiribi tí wọ́n ti ṣe, tí wọ́n sì nṣe fún ìtẹ̀síwájú Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y).
Látàrí ògo D.R.Y, ìrètí wà pé ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ìlú aláwọ̀dúdú yíò kọ́ ẹ̀kọ́.
Nínú fọ́nrán náà, a ríi pé àwọn kàn ò mọ̀ pé èdè àti àṣà ṣe pàtàkí ní dídìde ilẹ̀ Adúláwọ̀; a dúpẹ́ pé Màmá wa ti jẹ́ kí á mọ pàtàkì eléyi; kí gbogbo Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P), kí a fọwọ́-sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Ìjọba Adelé wa fún ìpìlẹ̀ rere yí, tí yíò fihàn gbangba pé àwa ti wà gẹ́gẹ́bí orílẹ̀-èdè kí àwọn àjọ tí wọ́n wà l’agbayé l’oni ó tó wáyé, a dẹ̀ mọ rírì èdè, àṣa àti ìṣe ní ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè. Kí Oluwa kí ó bùkún orílẹ̀-èdè wa, D.R.Y, títí láí.