Láti ìgbà láíláí ni àwọn Ọba ilẹ̀ Yorùbá ti jẹ́ ọ̀dàlẹ̀, ìkà àti alábọ̀dè sí ìran Yorùbá, kí àwọn amúnisìn tóó dé ni wọ́n tí ń kó ọmọ Yorùbá l’ẹ́rú àti lẹ́rù, ìdí nìyí tí àwọn aláwọ̀ funfun ṣe fi ńkan tí ò tó ńkan kó àwọn ọmọ Yorùbà lẹ́rú. Ọgbọọgbán ni àwọn amúnisìn lò láti gba ìṣàkóso ilẹ̀ Yorùbá kúrò lọ́wọ́ àwọn ọba yìí.

Lẹ́hìn tí àwọn ọba ilẹ̀ Yorùbá pàdánù agbára àti ipò wọn, síbẹ̀, àwọn amúnisìn nlo àwọn Ọba láti tẹ̀síwájú láti tẹ orí àwa ọmọ Aládé rì sínú ìyà, ìwà ọ̀dàlẹ̀ láti tẹ́ àwọn aláwọ̀ funfun wọ̀nyí lọ́rùn.

Inú ìwà burúkú yí ni àwọn ọba wà títí di ìgbà tí Olódùmarè gbé Olùgbèjà dìde fún àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, ìyá wa Modupẹọla Onitiri-Abiọla láti já àjàgà tí àwọn ọba àná gbélé ọmọ Yorùbá lọ́rùn. Kí ọlá, ọlà àti ìkẹ́ Olódùmarè kówà lórí màmá wa MOA.

Olódùmarè lo Màmá wa, MOA, láti gba ìṣàkóso orílẹ̀-èdè wa padà ní ọjọ́ kéjìlá oṣù igbe ẹgbàá-ọdún ó lé mẹ́rinlélógún, tí a sì ṣe ìbúra-wọlé fún Olórí Ìṣàkóso Adelé Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y), Bàbá wa, Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọ́kọrẹ́ ní ọjọ́ náà, lẹ́yìn tí a ti kọ́kọ́ ṣe ìkéde Òmìnira Orílẹ̀-Èdè wa ní ogúnjọ́ oṣù bélú ẹgbàá-ọdún ó lé méjìlélógún.

Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni, nínú àgbékalẹ̀ orílẹ̀-èdè wa D.R.Y kó sí ọba mọ títí ayé. 

Ògò àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá á búyọ, Ọba ni akò ní rímọ́ títí láí ní D.R.Y.

The Democratic Republic of the Yoruba also known in the Yoruba history as Yoruba Nation, Yoruba Kingdom, Yoruba Land and Yoruba Country is the newest nation in the world. The 55th nation in Africa and 17th in Western Africa as of 12th April 2024. Yoruba is know a sovereign nation and its no longer part of Nigeria.