Àwọn ẹ̀tọ́-àtọ̀run-wá, tí àgbáyé náà sì j’ẹrí sí, ni àwọn nkan tí ìràn Yorùbá dúró lé lórí, tí ó fi jẹ́ pé, l’oní, àti títí-ayé, a jẹ́ orílẹ̀-èdè aṣàkóso ara-ẹni.
L’ara àwọn ẹ̀tọ́ wọ̀nyí ni, Ẹ̀TỌ́ LÁTI Ṣ’ÀKÓSO-ARA-ẸNI, èyí tí ó túmọ̀ sí ẹ̀tọ́ láti dádúró, èyí tí a tún le pè ní ẹ̀tọ́ láti yan ọ̀nà-ẹni fún’ra ẹni, gẹ́gẹ́bí àpapọ̀ èèyàn ní agbègbè kan.
Ẹ̀tọ́ míràn ni Ẹ̀TỌ́ ÀWỌN ỌMỌ-ÒNILẸ̀, ỌMỌ ÌBÍLẸ̀. Èyí ni ẹ̀tọ́ tí àwọn tí ó bá jẹ́ pé ilẹ̀-àjogúnbá wọn, ilẹ̀ àwọn babanlá-baba wọn, láti ìgbà ìwásẹ̀, ni wọ́n ngbé, tí wọ́n fi ṣe ìbùdó, tàbí tí wọ́n lè tọ́ka sí, pé àwọn babanlá-baba wọn ni ó ni ilẹ̀ náà.
Lára àwọn ẹ̀tọ́ tí irúfẹ́ àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀, ní, ni ẹ̀tọ́ láti dádúró láyè ara wọn, kí wọ́n sì máa fún’ra wọn ṣe àkóso ìgbé-ayé ara wọn, láìsí pé ẹnikẹ́ni nṣe àkóso lé wọn lórí, tí kìí ṣe ara wọn, tàbí tí ó nṣiṣẹ́ fún ẹnikẹ́ni tí kìí ṣe ara wọn, lòdì sí ìfẹ́ àwọn ọmọ-ìbílẹ̀ náà lábẹ́ ẹ̀tọ́ yí.
Ẹ̀tọ́ kẹ́ta, míràn, ní Ẹ̀TỌ́ ÀWỌN ÌRÀN, èyíinì, àwọn tó jẹ́ pé, ìran kan-náà ni wọ́n jẹ́; ìtàn-ìran kan-náà ni ó pa gbogbo wọn pọ̀; àṣà àti ìgbé-ayé-ìran kan-náà yí sì pa wọ́n pọ̀, bẹ́ẹ̀ ni èdè kanṣoṣo tí ó jẹ́ ti ìran ọ̀ún pa wọ́n pọ̀, wọ́n sì ní ilẹ̀-àti-agbègbè àjogúnbá, kan-náà, tí ó pa wọ́n pọ̀, èyí tí ó jẹ́ ilẹ̀-ìbílẹ̀ wọn.
Àwọn tí ó jẹ́ ìran kan-náà yí, lára àwọn ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní, ní àgbáyé, ni ẹ̀tọ́ láti dádúró, pàápàá lórí ilẹ̀ babanlá-baba wọn, kí wọ́n sì máa fún’ra wọn ṣe àkóso ìgbé-ayé ara wọn, láìsí pé èlòmíràn njẹgàba lé wọn lórí!
Ẹ̀tọ́ míràn tún ni Ẹ̀TỌ́ ÀWỌN ÈNÌYÀN TÍ ILẸ̀-ÀJOGÚNBÁ WỌN KÒ NÍ ÀBÙLÀ! Èyí túmọ̀ sí pé, àwọn tí ó jẹ́ pé kò tún sí ilẹ̀-àjogúnbá kankan tí ó gba àárín ilẹ̀-àjogúnbá tiwọn kọjà. Ilẹ̀-àjogúnbá wọn kò ní àbùlà rárá. Lára àwọn ẹ̀tọ́ tí irúfẹ́ àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ní, ni pé, wọ́n ní Ẹ̀tọ́ láti dádúró, kí wọ́n sì máa fún’ra wọn ṣe ètò-àkóso ìgbé-ayé wọn fún’ra wọn, lápapọ̀, láìsí pé ẹnikẹ́ni tí kìí ṣe ara wọn njẹgàba lé wọn lórí.
Gbogbo àgbáyé ni ó mọ̀ nípa àwọn ẹ̀tọ́ wọ̀nyí, èyí tí ó sì wà bẹ́ẹ̀ ní Àkọsílẹ̀ níwájú àgbáyé.
Gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ wọ̀nyí ni àwa Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) dúró lé lórí, nígbà tí a ṣe Ìkéde Òmìnira wa kúrò lára Nàìjíríà, ní ogúnjọ́ oṣù bélú, ẹgbàá-ọdún ó lé méjìlélógún, tí a sì kédè rẹ̀, ní àkọsílẹ̀ bákan-náà, sí àjọ àgbáyé, tí kò sì sí ẹnikankan tí ó gbé ohùn ìlòdì-sí jáde, nítorí pé gbogbo àgbáyé mọ̀ pé, Ìkéde-Òmìnira wa, lórí Ẹ̀tọ́ wa ni.
Lẹ́yìn eléyi, ni a fi tó gbogbo àwọn gómìnà nàìjíríà létí, èyí tí a ti wá kúrò nínú rẹ̀, nípasẹ̀ ìkéde òmìnira wa yí, èyíinì, àwọn tí ó wà ní orí-ilẹ̀ Yorùbá, pé, a ti wá láti gba gbogbo ohun tí ó jẹ́ ti Ọmọ Yorùbá – ilẹ̀, ilé-iṣẹ́, bárékè, àti bẹ́ẹ̀-bẹ́ẹ̀ lọ.
Gbogbo àwọn gómìnà mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ tí ọ̀rọ̀ náà kàn, ni wọ́n sì rí ìwé tí a kọ síwọn náà gbà, pẹ̀lú ìbuwọ́lùwé pé lẹ́tà náà dé ọ̀dọ̀ wọn, wọn kò sì fèsì kankan tí ó lòdì sí ìwé-ìfitónilétí náà, láti oṣù-ọ̀pẹ, ẹgbàá-ọdún ó lé méjìlélógún, sí oṣù ṣẹrẹ, ẹgbàá-ọdún ó lé mẹ́talélógún tí gbogbo wọn ti gba ìwé náà láìsí ìdáhùn-àtakò kankan.
Pẹ̀lú ìdánilójú yí, tí gbogbo àgbáyé sì mọ̀, tí a sì ní ẹ̀tọ́ láti dádúró, èyí tí a sì ti ṣe ìkéde rẹ̀ láti ogúnjọ́ oṣù bélú ẹgbàá ọdún ó lé méjìlélógún, ni a fi bọ́síta, tí Ìyá-Òmìnira-Yorùbá, Màmá wa, Modúpẹ́ Onítìrí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá-Ààfin), ní orúkọ Gbogbo Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P) ti D.R.Y, ṣe Ìpolongo Ìṣàkóso-Ara-Ẹni Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) ní ọjọ́ kéjìlá, oṣù-igbe, ẹgbàá-ọdún ó lé mẹ́rinlélógún! Ìjáde wa kúrò nínú nàìjíríà wá di ohun tí nàìjíríà, gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún láti ọjọ́ náà, nítorí pé, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni a ṣe ìbúra-wọlé fún Olórí-Ìṣàkóso Adelé wa, Bàbá wa, Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọ́kọrẹ́, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
Lára àwọn àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè gbé fún Ìran Yorùbá, nípasẹ̀ Màmá wa, MOA, ni àlàkalẹ̀ fún Ètò Ẹ̀kọ́. Nínú àlàkalẹ̀ yí, ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ wà fún gbogbo I.Y.P ti D.R.Y láti ilé-ìwé alákọbẹ̀rẹ̀ títí di ìgboyè-kíní ní fásitì, tí ẹ̀yáwó tí kò ní èlé lórí sì wà fún gbogbo I.Y.P tí ó bá fẹ́ ka ìwé si, lẹ́yìn èyí, tí sísan ẹ̀yáwó náà padà kò sì nira rárá!
Ṣùgbọ́n kíni agbésùnmọ̀mí nàìjíríà ṣe? Ní kété tí a ti ṣe ìbúra-wọlé fún Olórí Ìṣàkóso-Adelé wa, tí ó sì yẹ kí àwọn gómìnà-Nàìjíríà tí ó wà ní ilẹ̀ Yorùbá ó jọ̀wọ́ iṣẹ́ sílẹ̀ fún Ìṣàkóso-Adelé wa, nṣe ni wọ́n fi àáké kọ́rí, tí wọ́n jẹgàba sóri ibi tí kìí ṣe tiwọn! Látàrí eléyi, lọ́wọ́lọ́wọ́ báyi, gbogbo àlàkalẹ̀ D.R.Y fún ètò-ẹ̀kọ́, èyí tí ọmọ I.Y.P ti yẹ kí a máa jẹ ìgbádùn rẹ̀, láti oṣù mẹ́jọ, gbáko, báyi, tí Ìṣàkóso-Adelé wa ti wà ní ìkàlẹ̀, àwa I.Y.P kòì tíì rí ìgbádùn náa jẹ, nìtorí oríkunkun nàìjíríà àti àwọn gómìnà wọn tí wọ́n nhu ìwà agbésùnmọ̀mí àti ìjẹgaba ní ilẹ̀ D.R.Y.
Ìròyìn tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́lọ́wọ́, báyi ní orí ẹ̀rọ-ayélujára, sọ pé, lára àwọn olùkọ́ ní fásitì ìpínlẹ̀ Èkó, Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), èyíinì, lára àwọn olùkọ́ ní LASU, wọ́n ti fi ilé wọn sílẹ̀, wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí ní sùn sí ibi-iṣẹ́ wọn, ní ọ́fíìsì wọn ni lára wọn nsùn sí báyi, ọmọ wà nílé, aya wà nílé, baálé sùn sí ọ́fíìsì, odindi olùkọ́ fásitì!
Bí orí àga ni wọ́n nsùn sí, bíi wọ́n tẹ́ní sílẹ̀ ni, a ò wá mọ̀, ṣùgbọ́n ìròyìn náà sọ pé lára àwọn olùkọ́ fásitì, ní LASÙ, ní ìpínlẹ̀ Èkó, Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), ti nsùn sí ọ́fíìsì wọn báyi, torí owó-epo bẹntiróòlù ti wọ́n kọjá èyí tí olùkọ́-fásitì máa lè gbé ọkọ̀ tiwọn lọ síbi iṣẹ́, bẹ́ẹ̀ náà ni ó ti wọ́n kọjá èyí tí wọ́n lè máa wọ ọkọ̀ elérò! Wọ́n ti fi ọ́fíìsì wọn ṣe ilé báyi, lára àwọn olùkọ́ wọ̀nyí. Ibẹ̀ ni wọ́n ti nsùn tí wọ́n ti njí, látàrí ìjẹgàba nàìjíríà sí orí ilẹ̀ D.R.Y!
Tí kìí bá nṣe ìjẹgàba nàìjíríà yí, àwọn olùkọ́-fásitì wọ̀nyí, ìgbà mẹ́rindínlógún, ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ni wọn ìbá ti gba owó-ọ̀ya wọn báyi, tí ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan sì jẹ́ owó tí ó tó owó, láti oṣù mẹ́jọ sẹ́yìn tí ó yẹ kí àwọn agbésùnmọ̀mí gómìnà-nàìjíríà wọ̀nyí, tí ó ti yẹ kí wọ́n kúrò níbi tí wọ́n jẹgàba sí – nítorí ọ̀sẹ̀-méjì-méjì ni owó òṣìṣẹ́ ní orílẹ̀-èdè wa, D.R.Y. Ìgbà mẹ́rindínlógún ni àwọn olùkọ́ wọ̀nyí ìbá ti gba owó báyi o!
A tilẹ̀ gbọ́ pé nínú ọ́fíìsì tàbí yàrá-ìkẹ́kọ, ní àwọn òlùkọ́ tàbí akẹ́kọ míràn, pàápàá, ti ndá’ná onjẹ! Háà! Nígbàtí ìṣàkóso D.R.Y ní ètò ìgbé-ayé ìrọ̀rùn fún gbogbo I.Y.P ti D.R.Y! Ṣé ẹ rí ìyà tí kò tọ́ sí ọmọ Yorùbá, tí àwọn ajẹgàba wọ̀nyí njẹ́ kí ó ṣẹlẹ̀ sí I.Y.P?
Ní fásitì ìlú Ìbàdàn, olú-ìlú Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), nkan kò rọgbọ níbẹ̀ bákan-náà. Ìròyìn náà sọ pé lára àwọn olùkọ́ fásitì ọ̀ún, bákan-náà, tí ó bá ti ndi ọwọ́-alẹ́ kí iṣẹ́ wọn ó tó parí, nṣé ni wọ́n á kúkú sùn sí’nú ọ́fíìsì wọn, látàrí wàhálà tí ó wà nínú pé kí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ tún kó sí ojú-títì láti máa lọ sí’lé!
Wọ́n ni àti gbọ́ bùkátà ti di ìṣòro gidi fún àwọn. Bẹ́ẹ̀ kẹ̀ sì ré, gbogbo nkan ìròbinújẹ́ wọ̀nyí ni ìbá ti di ohun àtijọ́, tí ó bá jẹ́ pé àwọn ìkà gómìnà nàìjíríà wọ̀nyí kò hùwa ìjẹgàba ni. Ṣùgbọ́n wọ́n máa kúrò láìpẹ́ yìí.
Olùkọ́ kan ní fásitì Ìbàdàn sọ pé àwọn kò rí ilé tí ó dára gbé, bẹ́ẹ̀ ni owó tí àwọn ngbà kò tó nkan-kan.
Olùkọ́ míràn ní fásitì Ìbàdàn yí, sọ pé, nítorí àwọn ìṣòro tí àwọn ndojúkọ gẹ́gẹ́bí olùkọ́, kò jẹ́ kí àwọn ní ìbalẹ̀-ọkàn àti àlááfíà láti lè fi gbogbo-ara kọ́ àwọn akẹ́kọ́.
Ní àwọn fásitì kan ní agbègbè Àkúrẹ́, gẹ́gẹ́bí ìròyìn náà ṣe so, olùkọ́ kan sọ pé, gẹ́gẹ́bí gbogbo nkan ṣe le, ko-ko-ko, fún wọn, àwọn olùkọ́ fásitì kan ti gba kámú pé àwọn ò lè wá sí’bi iṣẹ́ ju ìgbà méjì, ó pọ̀ tán, ìgbà mẹ́ta, l’ọsẹ̀! Olùkọ́ náà sọ pàtó, ó ní kò sí olùkọ́ fásitì kankan, ní agbègbè tiwọn, tí ó nwá sí’bí iṣẹ́ ní ojoojúmọ́, mọ́! Ọ̀rọ̀ náà ti dé bẹ̀! Oníkálùkù kàn nrò-ó nínú ara rẹ̀, pé ìgbà mélo ni òun á lè lọ ni.
Ṣé ẹ ri, I.Y.P, bí ìjẹgàba nàìjíríà ṣe nba ètò-ẹ̀kọ́ ní ilẹ̀ D.R.Y jẹ́? Kò yẹ kí ilé-ẹ̀kọ́ kankan ó wà ní ṣíṣí báyi. Ìjẹgàba nàìjíríà ló jẹ́ kí ilé-ẹ̀kọ́ wà ní ṣíṣí. Ẹ má gbàgbé, gbogbo I.Y.P ti D.R.Y, pé, àṣẹ ti jáde, pé kí á mú àwọn ọmọ wa kúrò ní gbogbo ilé-ìwé wọ̀nyí, kí a yé ṣe àtìlẹ́yìn fún àwọn ajẹgàba wọ̀nyí.
Àwọn olùkọ́ tó wà ní fásitì Ilé-Ifẹ̀, Democratic Republic of the Yoruba, wọ́n ní, lára wọn, láti Iléṣà tàbí Òṣogbo ni wọ́n ti nwá sí ibi-iṣẹ́, tí wọ́n sì nná bíi, ó kéré tán, ẹgbẹ̀rún-lọ́nà-ọgbọ̀n owó wọn ní nàìjíríà, l’ọs’ọ̀sẹ̀ lórí owó epo! Èló ni wọ́n ngbà tí eléyi máa fi rọrùn? Olùkọ́ tí ó sọ ọ̀rọ̀ yí, sọ pé òun tí òun jẹ́ “kòfẹ́sọ̀” pàápàá, òun ò lè fi gbogbo ara ṣe iṣẹ́ torí pé owó tí òun ngbà kò ká’jú ìlù!
Ní ìpínlẹ̀ Ìṣàkóso-Ọ̀yọ́ ti Àtijọ́ (Old Oyo Empire), Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), àwọn olùkọ́ kan ní fásitì Ìlọrin àti ní Malete, sọ pé iye tí àwọn ngbà kìí ṣe owó rárá! Kò tó nkan gidi láti ṣe.
Ẹ jọ̀wọ́, ọmọ I.Y.P ti D.R.Y, irú ìdájọ́ wo ni ẹ rò pé ó tọ́ sí àwọn agbésùnmọ̀mí, ajẹgàba nàìjíríà wọ̀nyí, tí wọn kìí ṣe ìlú, wọn kìí ṣe orílẹ̀-èdè, ètò-amúnisìn lásán-làsàn, tí wọ́n tún wá nfi ipá dúró sórí ilẹ̀ wa?
Àwọn olùkọ́-fásitì wọ̀nyí sọ pé òwó tí àwọn ngbà, ó ti’ni lójú tí a bá gbé-e sí ẹ̀gbẹ́ iye tí olùkọ́-fásitì ngbà ní àwọn ibòmíràn ní àgbáyé.
Ọmọ Yorùbá (I.Y.P ti D.R.Y), ẹ jẹ́ kí á gbárùkù ti ohun tí Màmá wa, Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá-Ààfin) nṣe, kí á sì fi ọwọ́-so-ọwọ́-pọ̀ pẹ̀lú ìṣàkóso adelé wa, láti ri pé, àwọn ajẹgàba wọ̀nyí kúrò ní orí ilẹ̀ wa ní kíá!
Ẹ máṣe gbàgbé, kí á máa gbáradì fún Àjọyọ̀ wa tí ó nbọ̀ láìpẹ́.