Ìròyìn tí a rí lórí ẹ̀rọ-ayélujára, X, ní ìkànnì @AfricaFactsZone , ni ó gbe jáde o, pé àìsàn tí ó ṣe àwọn ènìyàn ní kàyéfì, torí pé àwọn obìnrin ni àìsàn náà nṣẹlẹ̀ sí, á sì máa mú wọn jó ijó tí wọ́n ò fúnra wọn pinu láti jó, tí kò sì sí onílù tàbí olórin, tí wọ́n á sì ní ìgbóná ibà ní àgọ́-ara-wọn pẹ̀lú bí wọ́n ṣe njó náà, òun ni a gbọ́ pé ó nṣẹlẹ̀ ní Uganda, ní apá ìlà-oòrùn Áfríkà báyi.
Ṣé a ò kúkú mọ̀, kíni gan tí ó lè fa ìrúfẹ́ ibà-àti-ijó-jíjó yí? Ṣùgbọ́n, bí a ṣe ri sí, nínú fọ́rán náà, ó dàbí ìgbà tí ó bá jẹ́ pé inkan náà mú àgọ́ ara wọn kí ó ṣáà máà lọ sókè lọ sísàlẹ̀, lọ sẹ́gbẹ, wọn ò lè rìn tààrà bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ò lè gbé ẹsẹ̀ sórí ilẹ̀ dáradára.
Ẹnikan ní láti dì wọ́n mú tàbí fọwọ́ gbá wọn mú, kí wọ́n mọ́ ṣubú! Àìsàn náà kò yé àwọn ènìyàn rárá, gẹ́gẹ́bí ìròyìn náà ṣe sọ.
Kíni ó lè máa ṣẹlẹ̀? Ibi kan tí a rí nínú fọ́nrán náà dàbí ilé-ìwòsàn, ṣùgbọ́n kò sí àrídájú pé wọ́n rí nkan tí a lè tọ́ka sí ṣe lórí ọ̀rọ̀ náà.
Ṣùgbọ́n tí a bá ní ká fi ojú ṣùnnùkùn wo ọ̀rọ̀ náà, ṣé ó ní nkan tí wọ́n jẹ, tàbí tí wọ́n mú, tàbí tí wọ́n fún wọn, ní agbègbè náà, tí ó wá ṣe ìpalára fún wọn ní? A gbọ́ pé ní agbègbè tí ó ti ṣẹlẹ̀ náà, ó ti lé ní ọ̀ọ́dúnrún àwọn obìnrin tí ó ti ní àìsàn yí, báyi, tí ó sì ntàn kiri.
Ẹ jẹ́ kí a ṣọ́ra, kí Olódùmarè sì fi ààbò rẹ̀ lé wa lórí.
A ò ní ṣàì rán ara wa létí, àwọn ìlànà tí ó wà ní D.R.Y, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, fún ìlera ara wa – ẹ yàgò fún onjẹ́ tàbí irúgbìn tí ó bá jẹ́ ayédèrú (GMO); ẹ má sì ṣe gba abẹ́rẹ́-àjẹsára kankan.
Títí tí àwọn agbésùnmọ̀mí, ajẹgàba nàìjíríà, ètò-amúnisìn tí kìí ṣe ìlú, tí kìí ṣe orílẹ̀-èdè, títí tí wọ́n á fi sá kúrò ní ilẹ̀ wa tí wọ́n jẹgàba sí láìpẹ́, nípasẹ̀ oore-ọ̀fẹ́ Olódùmarè sí àwa I.Y.P (ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá) ti D.R.Y; gbogbo àwọn àgbo ìbílẹ̀ wa tí a ti mọ̀ láti ayébáyé, tí ṣíṣe’ṣẹ́ wọ́n dájú, ẹ jẹ́ kí á lò wọ́n tí ohunkóhun bá ṣẹlẹ̀.
Èéfín ni ìwà; kò ṣeé fi pamọ́