Atótó-arére, ìkan nínú àwọn ọ̀dọ́ ní a rí nínú fọ́nrán kan tó ṣán kú lójijì ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà, àdúgbò Bádore Àjáh ní ìpínlẹ̀ Èkó, ní Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, D.R.Y tí ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà nfi ipá jẹ gàba lé lórí.
Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn ló péjọ le ọ̀gbẹ́ni náà lórí tí wọn sì ń ṣe ìdárò rẹ̀. Ṣùgbọ́n, dípò kí wọ́n gbé ẹni náà lọ sí ilé ìwòsàn, tàbí kí wọ́n pe àwọn ènìyàn rẹ̀ àti àwọn agbófinró ṣe ni ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn náà bẹ̀rẹ̀ sí ya àwòrán ẹni tí ó kú sílẹ̀, oníkálùkù sì nsọ oríṣiríṣi.
Ohun tí a lérò pé ó fa ìwà àìbìkítà yí kìí ṣe àìní ìfẹ́ láti ṣe oore, ṣùgbọ́n ìbẹrù nítorí ìṣesí awon agbófinró ìlú agbèsùnmọ̀mí Nàìjíríà tí ó ṣì njẹgàba lórí orílẹ̀ èdè wa ni.
Àwọn agbófinró yìí má ń sọ òòrè di ibi nítorí owó, tí olóòtọ́ọ́ á wá kú sí ipò ìkà nígbàtí ó bá ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ tí kò mọ nípa rẹ̀.A dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè tí ó bá wa gba orílẹ̀ èdè wa (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y).
Nínú ohun tí màmá wa, Olóyè Ìyá Ààfin Modúpẹ́ọlá Onitiri-Abiọla ti Ọlọ́run lo fún àṣepé iṣẹ̀ rẹ̀ sọ fún wa nípa àlàkalẹ̀ ìṣèjọba Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, ètò ìlera jẹ́ pàtàkì láti ṣe adínkù ikú òjijì àti ikú àìt’ọ́jọ́, ìwádìí lórí ewé àti egbò wa fún ìtọjú àti ìwòsàn kò sì ní gbẹ́yin.
Màmá wa tún tẹ̀síwájú pé, àwọn agbófinró pẹ̀lú ẹ̀ṣọ́ aláabọ̀ wa yóò ní ìdánilẹkọ̀ọ́ tó pé, láti bẹ́’gi dí’nà ìfìyàjẹni lọ́nà tí kò bá òfin mu.
Àwọn igbesẹ wọ̀nyí á jẹ́ kó rọrùn láti máa fi àwọn ìṣẹlẹ̀ pàjàwìrì báyìí tó ìlé iṣẹ́ ìjọba tí ó bá yẹ létí, kí wọ́n lè ṣe ohun tí ó tọ́ làsìkọ̀.
Àwọn ìjọba Adelé wa ń ṣiṣẹ́ lọ láti mú kí a bẹ̀rẹ̀ síi jẹ ìgbádùn àwọn àlàkalẹ̀ ìṣèjọba yìí ní kété tí wọ́n bá ti wọlé sí ilè iṣẹ́ ìjọba wa, ìgbà dí ẹ̀ báyìí lókù kí á lé àwọn àjẹgaba agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà kúrò lórí ilẹ̀ wa.