Ó ti wá d’ojú ẹ̀, pátápátá báyi o, Ọmọ Yorùbá, ṣé ẹ mọ̀ wípé a ti ní ìjọba tiwa ní ìsinìyí, a sì ní l’ati bo’jú tó ara wa, gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè. Àwa ni a fẹ́ òmìnira o, a sì ti ri.

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

Ní òtítọ́ àti ní òdodo, àgbékalẹ̀ (èyíinì, àlàkalẹ̀, tabí BluePrint) fún Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá wà níbẹ̀ (D.R.Y), a dẹ̀ máa tẹ̀le, pẹ̀lú ìrànl’ọwọ́ Olódùmarè, àti iṣẹ́ kárakára tí ìjọba ol’orí ire tí Olódùmarè fún wa yí; ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́bí ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, a ní l’ati mọ̀ wípé, ohun tí ó wà l’ẹhìn ọ̀fà, ó ju òje lọ o!

Gbogbo wa pátá, gẹ́gẹ́bí ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P), ni a níláti dìde, kí á sì kọ́ àwọn ọmọ wa náa, l’ati ìran-dé-ìran, wípé, Yorùbá dádúró fún ara wa ní gbogbo àgbáyé yíi ni o! A kò gbọdọ̀ jẹ́ kí àgbáyé kí ó gbá wa lọ o!

Ṣe bí ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá kan ni ó nsín wa ní gbẹ́rẹ́ ìpàkọ́ yi!

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal

Ó wá sọ sí’wájú wípé, ohun kan wà ní àgbáyé yí o, tí a npè ní ‘òṣe’lú àgbá’yé’ (international politics); ó sì wá jẹ́ ohun tí ó l’agbára púpọ̀.

A kò gbọdọ̀ ṣàì jẹ́ ọlọ́pọlọ púpọ̀ ní ọ̀rọ̀ òṣe’lú àgbáyé! Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ ni, kò sí bí ìpinu àti ète tí ìjọba wa ní fún wa, ṣe lè dára tó, àìní ọpọlọ pípé nípa oṣe’lú àgbáyé, máa da nkan rú fún wa ani!

L’akọ́kọ́ ná, kí á mọ̀ wípé, òyìnbó kò ní ìfẹ́ kankan t’ó dé’nú fún aláwọ̀dúdú o! Kí á ṣí’ra sọ ìyẹn ná, fún ara wa.

Èkejì, a níláti ṣọ́’ra gidigidi, gẹ́gẹ́bí orílẹ̀-èdè, fún ohunk’ohun tí ó bá ti jọ mọ́ ti ìgbàl’odé, ní pàtàkì, àwọn ohun tí ó bá ti jẹ́ wípé àwọn òyìnbó ni wọ́n nṣe agb’atẹrù ohun náà, tí wọ́n á dẹ̀ máa tẹ’nu mọ bíi wípé ó ṣe dandan kí gbogbo àgbáyé gbàá! Olódùmarè kò fi òyìnbó jẹ ipò olórí àgbáyé o!

Gẹ́gẹ́bí olúlówó ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá kan ṣe máa nsọ, o ní ṣe l’ó dà bí ẹni wípé àwọn angẹ́ẹ́lì burúkú tí Olódùmarè lé kúrò ní àjùlé ọ̀run yẹn, inú àwọn òyìnbó wọ̀nyí ni wọ́n sọ̀ ka’lẹ̀ sí! Kò sí irọ́ kankan ní’bẹ̀ o, gẹ́gẹ́bí ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá tí ó sọ ọ̀rọ̀ yíi ti fi lé’de.

Ó tún wá tẹ̀ síwájú, ó sọ wípé, àwọn funfun tí ẹ nwò yẹn, abu’nijẹ-fẹ́’yìsi ni wọ́n o!

Àwọn ni wọ́n máa máa ṣe ẹ́, àwọn náà ni wọ́n máamáa kí ẹ kú ìrọ́jú, tí wọ́n á tún máa sọ wípé àwọn dúró tì ẹ́, tí ó sì jẹ́ wípé, ọ̀nà àti túbọ̀ kó yín sí oko ẹrú ni wọ́n máa máa wá káàkiri!

Ẹni tí kò sún’ra kì, kí ó dẹ̀ ṣọ́’ra fún aláwọ̀ funfun ní ọ̀rọ̀ àgbáyé yí, irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ ni kí àwa fún’ra wa ó ṣọ́’ra fún o!

A ní l’ati mọ̀ wípé kò sí ọpọlọ tí òyìnbó ní, tí ọmọ Yorùbá kò ní kọjá ẹ̀ lọ o! kò dẹ̀ sí ohun náà tí òyìnbó màá ṣe, tí ọpọlọ ọmọ Yorùbá kò lè gbé èyí tí ó ga jùbẹ́ẹ̀ dìde!

Ṣùgbọ́n, kí a má máa rò wípé bí ti òyìnbó ṣe rí yẹn gan-an náà ni èyí tí Yorùbá bá máa gbé já’de náà, ṣe máa rí! Rárá o!

Ẹ dẹ̀ jẹ́ kí á rán’tí wípé Yorùbá ni ògo adúl’awọ̀ o! Kìí ṣe ti ìgbé’raga, ṣùgbọ́n kí á lè mọ títóbi àti wíwúwo iṣẹ́ tí Olódùmarè gbé kọ́ wa l’ọrùn o!

Àwa ni gbogbo adúl’awọ̀ máa máa wò o! Wọ́n á ní, ṣé Yorùbá ti gbé irú ìgbé’sẹ̀ yẹn ni?

Wọ́n á ní tí Yorùbá kò báì tíì gbé irúfẹ́ ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀, bóyá kí àwọn ṣì dúró ná, kí àwọn ṣì tún wo ọ̀rọ̀ yẹn dáradára. A ò ní ṣi alá’wọ̀ dúdú l’ọnà o!

Nítòótọ́, ti ara wa ni a máa gbọ́, gẹ́gẹ́bí ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá yíìí ṣe sọ, ṣùgbọ́n, ó ní wípé, kí a rán’tí o, wípé, bí Yorùbá bá ṣe ṣe orílẹ̀-èdè wọn sí, ni ó máa ṣ’okùn’fà ohun tí ó máa ṣẹ’lẹ̀ sí ìyókù adúl’awọ̀ o!

Ó ní, ẹ má ṣe tẹ̀lé òyínbó o! ẹ ṣe ohun tí Olódùmarè fẹ́ kí á ṣe, gẹ́gẹ́bí Yorùbá. Ó tún wá sọ sí’wá’jú, wípé, Yorùbá, ẹ ṣọ́’ra fún àwọn ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú òyínbó, èyí tí á tún wá sọ wá s’oko ẹrú ẹlẹ́ẹ̀kéló?