Láìpẹ́ yí ni ìròhìn kan tún tẹ̀ wá lọ́wọ́ o, lórí ìgbésẹ̀ ìkọ̀kọ̀ kan tí àwọn òyìnbó amúnisìn tún ngbé, látàrí kí Áfríkà ṣáà máa sin àwọn; ṣùgbọ́n irọ́ ni wọ́n npa! Yorùbá ti lọ ní ti’wa; ṣúgbọ́n a máa ṣe àlàyé ọ̀rọ̀ náà, kí ó le yé wa yékéyéké, àti kí á le mọ èyí tí ó kan Yorùbá níbẹ̀.
Ẹ ránti pé, orí ilẹ̀ wa, ní Democratic Republic of the Yoruba, ni ìlẹ̀ tí Dangote sọ pé òun rà fún ìlé-iṣẹ́ ìfọpo wa. Ìyẹn ìkan.
Èkejí, ṣé ó ti yé wa, pẹ̀lú gbogbo ohun tí a ti nsọ, pé àwọn òyìnbó amúnisìn wọ̀nyí, wọn ò ro ti Áfríkà sí rere rárárá: wọn ò fẹ́ ìtẹ̀síwájú kankan fún Áfríkà!
Wọ́n dẹ̀ máa nlo aláwọ̀dúdú kí ó dojú ìjà kọ aláwọ̀dúdú ẹgbẹ́ rẹ̀ ni; nípa èyí, kò ní sí ìdàgbàsókè ní ilẹ̀ Áfríkà, àwọn òyínbó á máa jẹ lọ.
Èyí tí a wá gbọ́ nísiìyí ni pé arákùnrin akọ̀ròhìn kan, David Hundeyin, sọ pé àwọn ẹgbẹ́ òyìnbo kan ti sọ fún òun o, ó sì gbé ẹ̀rí rẹ̀ jádé, pé wọ́n á fún òun ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta owó dọ́la tí òun bá le ṣe iṣẹ́ kan fún àwọn. Kíni iṣẹ́ náà?
Wọ́n ní kí ó kọ ìròhìn síta pé kò yẹ kí Dangote ó ṣe ilé-iṣẹ́ ìfọpo yẹn, torí pé, gẹ́gẹ́bí wọ́n ṣe sọ, wọ́n ní àwọn epo rọ̀bi wọ̀nyẹn, àti èyí tí wọ́n ti fọ̀, máa nṣe àkóbá fún agbègbè, àyíká àti atẹ́gùn; nítorí náà, kí ó bá wọn fi ìròhìn kíkọ gbógunti Dangote kí ó jáwọ́ kúrò ní iṣẹ ìfọpo yẹn.
Inkan tí ó wà níbẹ̀ ni pé, èkíní, àwọn òyìnbó wọ̀nyí ní ilé-iṣẹ́ ìfọpo tiwọn, tí wọ́n fẹ́ kí Nàìjíríà ó máa fi epò rọ̀bì ránṣẹ́ sí wọn láti fọ̀, kí wọ́n wá tàá padà fún Nàìjíríà; nítorí èyí, tí Dangote náà bá ti bẹ̀rẹ̀ sí ni fọpo, ó ti nṣe àkóbá fún àwọn òyìnó ọ̀ún nìyẹn! Ẹ má gbàgbé pé orí-ilẹ̀ D.R.Y ni gbogbo eléyi dá lé lórí o, a ṣì mbọ̀ níbẹ̀.
Tí Dangote bá nfọ epo, ó tún túmọ̀ sí pé, ilẹ̀ Aláwọdúdú ti nṣe nkan tí á tún mú ìdàgbàsókè wá nìyẹn: nítorínáà, pé wọn ò fẹ́ kí Dangote bá wọn pín oníbárà, àti pé wọn ò tilẹ̀ fẹ́ kí Aláwọ̀dúdú ó gbéra rárá, òun ni wọ́n fi ní àwọn á fún David Hundeyin ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta owó dọ́là, kí ó bá àwọn fi ìròhìn àtakò ba ayé Dangote jẹ́, kí ó le jáwọ́ kúrò ní ọ̀rọ̀ pé òun fẹ́ fọ epo! Ṣé ó nyé wa!?
Nítorí èyí, wọ́n níláti wá àwáwí kan, ìdí tí Dangote kò ṣe gbọ́dọ̀ tẹ̀ síwájú nínú èrò fífọpo tí ó ní òun fẹ́ fọ epo!
Wọn ò rí àwáwí kankan ju pé àwọn epo láti inú ilẹ̀ ló nṣokùnfà àyíká àti ojú-ọjọ́ tó nyí padà káàkiri àgbáyé!
Ṣùgbọ́n àwọn òyìnbó wọ̀nyí kò wá le fún’ra wọn kojú Dangote láti sọ fún pé, Jáwọ́ lọ́rọ̀ ìfọpo tí o nsọ yẹn o! Ìdí nìyí tí wọ́n fi wá lọ bá David Hundeyin, gẹ́gẹ́bí akọ̀ròyìn, kí ó gbogun ti Dangote kí ó le jáwọ́ níbẹ̀.
Ìnkan méjì ní a rí fà yọ níbẹ̀, ọmọ Yorùbá: èkíní ni pé, ṣé ẹ ti wá ri dájú báyi pé ètò tí àwọn òyìnbó wọ̀nyí ní fún aláwọ̀dúdú ni pé kí aláwọ̀dúdú má ṣe gbérí!
Èwo ló kàn wọ́n bí Dangote fẹ́ fọpo tàbí kò fẹ́ fọpo! Tí ó bá jẹ́ pé ọwọ́ wọ́n mọ́, wọn ò ṣe lọ kojú Dangote fún’ra wọn?
Ṣùgbọ́n torí wọn ò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀ pé àwọn ni wọ́n wà nídi ọ̀rọ̀, ni wọ́n ṣe lọ bá Hundeyin lábẹ́lẹ̀, tí wọ́n ní àwọn á fun ní owó kí ó bá wọn kọ ìròhìn àkọlù sí ọmọ Fulani Dangote yí. Ìròhìn yí kìí ṣe nípa Dangote, kò sí nkan tó kàn wá pẹ̀lú ìpọ̀nrípọngbá Dangote, a fẹ́ jẹ́ kí ẹ mọ́ bó ṣe nlọ ní àgbáyé yí ni, gẹ́gẹ́bí àwọn òyìnbó wọ̀nyí kò ṣe fẹ́ kí aláwọ̀dúdú ó gbérí!
Ohun kéjì tí ó ṣe pàtàkì tí a fẹ́ pe àkíyèsí gbogbo ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá sí, ni pé, orí ilẹ̀ D.R.Y ni ọ̀rọ̀ yí dá lé lórí: ìdí nìyẹn tí ó fi kàn wá! nítorí èyí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, láyé, a ò lè sọ pé ohun tí àwọn òyìnbó yẹn nfẹ́, pé ó dára: rárá o! kò dára, ìwà amúnisìn wọn nìyẹn, kí Áfríkà má lè dá nkan rere ṣe, ìyẹn ni àwọn nlépa!
Bẹ́ẹ̀ náà ni ó jẹ́ pé, láyé, a ò le sọ pé Dangote jàre wọn: kò sí èyí tí ó kàn wá, láarin aṣiwèrè òyínbó amúnisìn àti agbésùnmọ̀mí Dangote: kí wọ́n kó èyí tó nṣe wọ́n lọ sí Nigeria; tiwa ni pé, NÀÌJÍRÍÀ, kó wàhálà ẹ kúrò lórí ilẹ̀ Yorùbá.
Ní kété tí Olódùmarè bá ti ràn wá lọ́wọ́, tí Nàìjíríà ti fi orí ilẹ̀ wa sílẹ̀, láìpẹ́, àwa gẹ́gẹ́bí orílẹ̀-èdè D.R.Y mọ bí a ṣe máa ṣe ìdájọ́ gbogbo ohun tí ó jẹ mọ ọ̀rọ̀ ọmọ Fulani, Dangote, lórí ilẹ̀ D.R.Y. Orílẹ̀-Èdè wa máa júwe fún Dangote ibi tí ó máa kọrí sí!
Lẹ́hìn èyí, bẹ́ẹ̀ náà ni òfin àti ìpinnu D.R.Y máa ri pé amúnisìn kankan, ó ṣe òyìnbó ni, tàbí kò ṣe òyínbó, láyé, kò ní rí àyè ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá láti gbé ìgbésẹ̀ oríburúkú kankan: àti agbésùnmọ̀mí Dangote, àti wèrè òyìnbó amúnisìn, ẹ kọjá sí Nàìjíríà o!
kí Nàìjíríà ó dẹ̀ kúrò lórí ilẹ̀ Democratic Republic of the Yorùbá.