Àṣìṣe nlánlà, èyí tí ètò amúnisìn tó njẹ́ nàìjíríà ṣì nṣe, ni kí wọ́n máa pe ilẹ̀ Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) ní ara Nàìjíríà.

A kìí ṣe ara nàìjíríà yín mọ́ – ẹ la etí yín kí ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀. Láti ogúnjọ́ oṣù bélú, ẹgbàá-ọdún ó lé méjìlélógún ni a ti kúrò lára yín, nígbàtí a ṣe ìkéde òmìnira Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) kúrò lára nàìjíríà.

Ó ti lé ní ọdún méjì báyi, ẹ yé tan ara yín jẹ mọ́; kí ẹ sì sọ fún gbogbo àwọn ẹ̀ka ìṣàkóso yín kí wọ́n yéé pe ilẹ̀ Yorùbá (D.R.Y) mọ́ ara Nàìjíríà mọ́. Ẹ ṣọ́ra yín o! A nsọ fún-un yín.

Nígbàtí a fi Ìwé Ìgbàpadà (Reclamation Letter) ránṣẹ́ sí àwọn gómìnà yín tó wà ní ilẹ̀ Yorùbá (D.R.Y) ní àárín ọjọ́ kéjìdínlógún oṣù ọ̀pẹ, ẹgbàá-ọdún ó lé méjìlélógún, títí di oṣù ṣẹrẹ ẹgbàá-ọdún ó lé mẹ́talélógún, tí gbogbo wọn sì ri gbà, ṣebí a fi ẹ̀dà ìwé ọ̀ún ránṣẹ́ sí ààrẹ nàìjíríà yín nígbà náà? Nítorí náà, nàìjíríà, ẹ ṣọ́ra yín gidi gan-an, ẹ yé ka Yorùbá (D.R.Y) mọ́ ara Nàìjíríà mọ́.

Ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), ẹ wá gbọ́ ìròyìn kan tí a rí ní yàjóyàjó, nínú èyí tí àwọn ajẹgàba Nàìjíríà, ètò-amúnisìn tí kìí ṣe ìlú, tí kìí ṣe orílẹ̀-èdè, tí wọ́n nsọ̀rọ̀ nípa àwọn owó tí àwọn ènìyàn ti san fún ajínigbé ní ìlú wọn, nàìjíríà, ní ọdún yí, ẹgbàá-ọdún ó lé mẹ́rinlélógún.

Ọ̀ràn tí wọ́n wá dá níbẹ̀ ni pé, wọ́n ṣì nka ilẹ̀ Yorùbá (D.R.Y) mọ́ ara Nàìjíríà. Wọ́n máa kó kátikàti tí wọ́n nsọ yẹn, wọ́n máa ko jẹ ní àìpẹ́ yí, ẹ̀yin ẹ máa wòran láti rí ìyà-ẹ̀sín wọn.

Ṣùgbọ́n a ní kí á fi tó wa léti, àwa I.Y.P ti D.R.Y, ọ̀rọ̀ rírùn tí wọ́n nsọ nípa owó tí wọ́n nsan fún ajínigbé.

Gẹ́gẹ́bí wọ́n ṣe sọ, gbogbo owó tí àwọn ènìyàn san fún ajínigbé ní nàìjíríà àti ní D.R.Y ní ọdún yí, jẹ́ trílíọ̀nù méjì àti okòó-lé-n’igba ó lé mẹ́wa owó náírà wọn (N2,230,000,000,000).

Owó tí agbésùnmọ̀mí nàìjíríà, tí ó jẹ́ pé àwọn náà ni wọ́n fi àyè gba àwọn ajínigbé, owó tí wọ́n sọ pé àwọn ènìyàn ní nàìjíríà àti ní D.R.Y (níbi ti nàìjíríà ti njẹgàba), owó tí wọ́n ti san fún ajínigbé ní ọdún tó nlọ sí òpin yí nìyẹn o! Ohun tí ó ndùn nínú wọn tí wọ́n fi nsọ èyí, ìyẹn ni kò yé wa o!

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal

Nínú owó náà, èyí tí ó pọ̀ jù (trílíọ̀nù kan àti òjìlénírínwó bílíọ̀nù naira – N1,440,000,000,000) ni ó jẹ́ pé ní àwọn ìgbèríko ni wọ́n ti jí àwọn ènìyàn náà gbé, tí ẹgbẹ̀rin bílíọ̀nù ó dín mẹ́fà àti ọ̀tàlénírínwó mílíọ́nù (N794,460,000,000) sì jẹ́ ti èyí tí ó ṣẹlẹ̀ ní àwọn ìlú-nlá-nlá.

Èyí tí ó ṣẹlẹ̀ ní ìpínlẹ̀ mẹ́fà ní Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), láì tíì ṣírò ti ìpínlẹ̀ ìṣàkóso Ọ̀yọ́ ti Àtijọ́ (Old Oyo Empire), iyé owó náà jẹ́ òjìlénigba bílíọ̀nù ó lé mẹ́jọ àti okòó-dín-ní ẹgbẹ̀rin mílíọ̀nù naira (N248,780,000,000).

Ìdí tí a ò fi mọ iye tí ti Old Oyo Empire wa tí ó jẹ́, ni pé, àwọn ajẹgàba ètò-amúnisìn tí wọ́n npè ní nàìjíríà yí, wọ́n ṣe ẹnu wọn ṣùtì máa ka Old Oyo Empire wa mọ́ “North Central Nigeria”) tí wọ́n ṣírò owó ẹ̀ papọ̀. Ara ọ̀ràn pípe D.R.Y ní ara nàìjíríà náà nìyẹn o!

Ẹ wá gbọ́ o! – nàìjíríà, ẹ kúrò lórí ilẹ̀ wa! Kò sí ẹni tó bérè ẹjọ́ iye tí àwọn ènìyàn san fún ajínigbé, kò sí ẹni tó bérè ẹjọ́ yẹn lọ́wọ́ yín!

AbdulRahman AbdulRazaq, jáde kúrò ní orikò-ilé-iṣẹ́ ìṣàkóso D.R.Y ní Ìlọrin; Ododo, ìwọ náà, kí lo ṣì nṣe ní Sẹkitéríátì wa ní Lọ́kọ́já? Kúrò níbẹ̀.

Ayédatiwa, kí lo nṣe ní Sẹkitéríátì D.R.Y ní Àkúrẹ́; Oyèbánjí, kúrò ní sẹkitéríátì wa l’Adó-Èkìtì, ilẹ̀ Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) lo wà yẹn, kìí ṣe nàìjíríà mọ́, láti ogúnjọ́ oṣù bélú ẹgbàá ọdún ó lé méjìlélógún, a sì ti bẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso-ara-ẹni wa ní ọjọ́ kéjìlá oṣù-igbe, ẹgbáà ọdún ó lé mẹ́rinlélógún! O mọ̀ o! Yéé ṣe orí-kunkun.

Ìwọ Jídé Sanwó-Olú, kúrò ní Sẹkitéríàtì wa ní Ìkẹjà! Máṣe mú nkan wa kankan kúrò níbẹ̀ o! Ìwọ ṣáà jọ̀wọ́ iṣẹ́ sílẹ̀ fún Accountant-General àti Adájọ-Àgbà.

Ṣèyí Mákindé, oríkunkun tóo ṣe yẹn ti tó, máṣe tún dá kún àwọn ọ̀ràn tí o ti dá tẹ́lẹ̀. Rọra kúrò ní Sẹkitéríàtì ní Ìbàdàn, kóo jọ̀wọ́ iṣẹ́ sílẹ̀ fún Accountant-General àti Adájọ́-Àgbà.

Adémọ́lá Adélékè, ìwọ rọra kúrò l’oríkò ilé-iṣẹ́ ìṣàkóso ní Òṣogbo ní tìẹ! Má jampata o! Rọra máa lọ. Democratic Republic of the Yoruba fẹ́ lo nkan wa.

Dàpọ̀ Abíọ́dún, kúrò ní Sẹkitéríàtì wa l’Abẹ́òkúta, rọra máa lọ, jọ̀wọ́ iṣẹ́ sílẹ̀ fún olùdarí-ètò ìṣúná àti fún Adájọ́-Àgbà.

Lóbátán! Inkan tí D.R.Y sọ pé kí ẹ ṣe nìyẹn; a ò bérè ẹjọ́ kíni tani san fún ajínigbé.

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal

Tí iná bá ńjó lóko, màjàlá á ṣe òfófó