Gẹ́gẹ́bí a ṣe mọ̀; Ìyá Ìran Yorùbá, ẹni tí Olódùmarè ti rán sí wa gẹ́gẹ́bí Olùgbàlà, ti máa nsọ fún wa, pé, a máa padà sí Orísun wa ni – àṣẹ Ẹlẹ́da wa ni èyí.
Kíni orísun wa? Ibi tí a ti ṣàn wá; ìṣèjọba-ara-ẹni wa, gẹ́gẹ́bí Yorùbá, láìsí lábẹ́ ẹnikẹ́ni!
Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ti fi yé wa pé nṣe ni a máa padà sínú àṣà abínibí wa nínú ohun gbogbo – títí kan bí a ṣé nwá onjẹ nínú ilé-iṣẹ-ọ́lónjẹ gbogbo.
Àṣà wa nìkan ni ó bá ìṣẹ̀dá wa mu; ìdí nìyẹn tí a níláti padà sí àṣà wa! Láìṣe bẹ́ẹ̀, kí Ọlọ́run máṣe jẹ́ kí ẹ̀dá wa kí ó takò wá o! A ò ní gba àbọ̀dè fún ara wa.
Àṣà wa ni ohun ìbílẹ̀ wa; ohun tí ó bá ẹ̀jẹ̀ tí Olódùmarè fi dá Yorùbá, tí ó ba mu – ohun tí ó jẹ́ pé láti ìṣẹ̀dálẹ̀ Yorùbá ní a ti nṣe é, tí ó dẹ̀ ngbè wá; ohun tí ó fún wa ni ẹ̀mí “ilé-ni-mo-wa” kì nṣe ohun tí ó jẹ́ àjèjì sí ẹ̀mí ọmọ Yorùbá, ẹ̀mí Ìran Yorùbá.
Gẹ́gẹ́bí ewé àti egbò, fún àpẹrẹ – àwọn ohun tí Olódùmarè ti fi sí Àyíká wa, pé kí wọ́n le jẹ́ ààbò àti ìwòsàn fún ara wa. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a máa nní ọgbọ́n kún ọgbọ́n ni, síbẹ̀, èyí tí Ọlọ́run ti fún wa, tí ó jẹ́ Àbáláyé, a máa padà sínú rẹ̀, kí ilẹ̀ àbáláyé wa yí, kí ó le gbè wá.
Màmá ti máa nsọ fún wa pé ó ní bí àwọn Bàbá wa ṣe ní ìgbé ayé rere níjọ́ láíláí, kí amúnisìn ó tó gòkè odò; a máa ṣe àwárí àwọn ohun tó mú kí wọ́n ní irúfẹ́ ìgbé-ayé-rere bẹ́ẹ̀.
A ti bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú lílo èdè wa; láti inú lílo èdè yí ni oríṣiríṣi nkan míì tí ó jẹ́ ti àbáláyé ti máa búyọ.
Ṣebí ó ní àwọn ọgbọ́n tí àwọn Baba wa ní, tí wọ́n fi nṣe àgbéjáde oríṣiríṣi iṣẹ́, bíi gbígbé nkan àgbẹ̀dẹ jáde; oríṣiríṣi Ìmọ̀ nípa ilẹ̀ tí a fi ndá’ko, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nkan, tí ó jẹ́ ti Ìbílẹ́, ló máa búyọ; bí àwọn ìyá wa ní ayé àtijọ́ tí máa nṣe àwọn iṣẹ́-ọwọ́ kan, èyí tí ó jẹ́ pé, títí di òní, a ò tíì rí ìran míràn tí ó ríi ṣe tó Ìran Yorùbá.
Ẹ jẹ́ kí a rántí bí àwọn òyìnbó amúnisìn, ṣe gbà pé ẹ̀kọ́, àṣà àti ìjọ́mọ-lúàbí wa ga ju tiwọn lọ, ṣùgbọ́n tí wọ́n wá gbe tiwọn yẹn lé wa lọ́wọ́! Ṣùgbọ́n tí ìyá ìran Yorùbá sọ pé èyí tí a sọnù yẹn, a máa padà sínú rẹ̀.
Yorùbá ni wá; àṣà Yorùbá nìkan ló le pé wa.