Ọ̀kan gbòógì lára àṣà ilẹ̀ Yorùbá ni ìsọmọlórúkọ jẹ́, Yorùbá gbàgbọ́ pé orúkọ á máa fi bí ọmọ ṣe jẹ́ hàn, orúkọ á sì máa ro ọmọ, àti pé orúkọ ọmọ ni ìjánu ọmọ. Oríṣịríṣị àkíyèsi ni àwọn òbí máa ń ṣe kí wọ́n tó lè pinnu orúkọ tí wọ́n máa fún ọmọ.
Wọ́n máa ń ṣe àkíyèsi ipò tí ọmọ wà nígbà tí a bí i, wọ́n tún máa ń ṣe àkíyèsi ipò tí ẹbí wà lásìkò tí wọ́n bí ọmọ náà, ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣẹ̀ ní kété tí wọ́n bí ọmọ náà, tàbí ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣẹ̀ nígbà tí ìyá rẹ̀ wà nínú oyún ọmọ náà. Yàtọ̀ sí èyí, wọ́n tún máa ń ṣe àkíyèsi ọjọ́ àti àsìkò tí ọmọ náà wáyé. Irúfẹ́ àwọn àkíyèsí yìí ló bí owé kan tí àwọn Yorùbá máa ń pa wí pé “ilé là ń wò ká tó sọmọ lórúkọ”.
Yorùbá gbàgbọ́ pé bí orúkọ ọmọ bá ṣe rí ni ọmọ náà yóò ṣe hùwà, àti pé orúkọ ọmọ ní í ro ọmọ. Èyí jẹ yọ nínú òwe Yorùbá kan tó sọ pé “a sọ ọmọ ní ṣódé, ó dé, a sọ ọmọ ní ṣóbọ̀, ó bọ̀, a sọ ọmọ ní ṣórìnlọ, ó lọ, kò wálé mọ́, ta ni kò ṣàìmọ̀ pé orúkọ ọmọ ní í ro ọmọ”.
Ní ayé àtijọ́, ọjọ́ kẹsàn-án ni a máa nsọ ọmọkùnrin ní orúkọ, ọjọ́ keje ni ti ọmọbìnrin,ọjọ́ kẹjọ sì ni ti àwọn ìbejì. Díẹ̀ lára àwọn orúkọ tí àwọn Yorùbá ti máa ń pe ọmọ tuntun kí ó tó di ọjọ́ ìsọmọlórúkọ ni, Ìkókó, aròbó, Kóńkólóyọ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Inú ìyàrá ni ìyá ìkókó gbọ́dọ̀ wà pẹ̀lú ìkókó náà láti ọjọ́ tí ó bá ti bímọ títí di ọjọ́ ìkomọjáde. Ọjọ́ ìsọmọlórúkọ ni a ó tó gbé ọmọ náà jáde láti inu ìyàrá ìdí nìyí tí a fi ń pe ọjọ́ ìsọmọlórúkọ ní ọjọ́ ìkọ́mọjáde.
Àwọn èròjà fún ètò ìsọmọlórúkọ ní ilẹ̀ Yorùbá ní ayé àtijọ́ ni àádùn, ìrèké,omi tútù, epo, iyọ̀,ẹja, oyin, orógbó, ọtín, obì, owó àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ tí wọ́n yóò sì máa mú àwọn èròjà wọ̀nyí ní ọ̀kọ̀ọ̀kan láti fi wúre fún ọmọ náà.
Ṣùgbọ́n ó ṣeni láàánú pé a kò tẹ̀lé àwọn ìlànà wọ̀nyí mọ́ láyé òde òní ẹlòmíràn kò tilẹ̀ mọ̀ wípé fífi orógbó àti obì wúre dúró fún ẹ̀mí gígùn ni, tí àádùn, oyin àti iyọ̀ sì dúró fún adùn, ìdùnnú àti ayọ̀.
Ṣùgbọ́n a dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè tí ó gbé màmá wa ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla dìde lásìkò yí láti ra ayé àwa ọmọ Yorùbá padà kúrò nínú ìparun, nítorí pé màmá wa ti sọ fún wa wípé gbogbo àṣà wa ti àwọn amúnisìn ti gbà lọ́wọ́ wa ni a ó padà sí gẹ́gẹ́ bí àwọn babańlá wa tií ṣeé láti ìgbà ìwásẹ̀.