Ní Orílẹ̀-èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y), ìgbádùn tí yóò wà fún wa kò lóǹkà, àìríjẹ ti di ohun ìgbàgbé ní ilẹ̀ Yorùbá, oúnjẹ tó dára ní a óò máa jẹ́, nítorí pé ìjọba D.R.Y kò ní fàyè gba ayédèrú oúnjẹ GMO tàbí lílo èròjà tó leè ṣe àkóbá fún àgọ́ ara nínú iṣẹ́ ọ̀gbìn.

Gbogbo àwọn ẹnu ibodè wa ni wọ́n yóò ti máa ṣe àyẹ̀wò fínnífínní lórí ohunkóhun tí wọ́n bá ń kó wọlé sí orílẹ̀ èdè wa èyí ni láti ríi dájú pé wọn ò kò oúnjẹ tó leè ṣe ìpalára wá fún wa.

Say no to GMO foods in yoruba
IYP say no to GMO seeds / foods

Ètò ìrànwọ́ yóò wà fún àwọn àgbẹ̀ láti leè máa pèsè oúnjẹ lọ́pọ̀ yanturu, nítorí pé ilẹ̀ ọlọ́ràá ni Olódùmarè fún wa, aò nílò láti bá orílẹ̀ èdè kankan d’òwòpọ̀ kí a tó leè jẹun, gẹ́gẹ́ bí màmá wa Modupẹọla Onitiri-Abiọla ṣe máa ń sọ fún wa wípé, àwa ni yóò máa pèsè ohun tí a nílò, ohun tí a bá sì ń pèsè náà ni a óò máa lò.