Ní ojoojúmọ́ ni àwa ìran Yorùbá yóò máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run Olódùmarè fún iṣẹ́ ìyanu tó ṣe fún wa, tó mú wa kúrò lóko ẹrú nípasẹ̀ màmá wa Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá Ààfin), pẹ̀lú ìrọ̀rùn láìsí ogun. Màmá ìrọ̀rùn lóbádé, ẹ ṣé púpọ̀, ìran Yorùbá mọ̀ọ́ lóore.
Oríṣiríṣi ètò fún ìgbé ayé ìrọ̀rùn ló ti wà nílẹ̀ fún gbogbo ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) ti orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y), lára wọn ni oúnjẹ tó dára ní àsìkò. I.Y.P kankan kò tún sun ẹkún àìríjẹ mọ́.
Oúnjẹ yóò pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ fún t’èwe t’àgbà, kìí wá tún ṣe oúnjẹ lásán, ṣùgbọ́n oúnjẹ tó dára, tí yóò ṣe ara ní àǹfààní, èyí tí yóò sì wà ní àrọ́wọ́tó ẹnìkọ̀ọ̀kan, nítorí pé oúnjẹ ṣe pàtàkì púpọ̀. Kò sí òbí tí kò ní rí owó ra oúnjẹ fún àwọn ọmọ rẹ̀, oníkálukú ni yóò ní iṣẹ́ lọ́wọ́.
Kí a jẹ t’ọ̀sán láìní ìrètí kíni a fẹ́ jẹ ní alẹ́, ìyẹn ti di àfìsẹ́yìn tí eégún ń fi’sọ. Àsìkò tó bá wù wá ni a óò jẹun tí a fẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ Aládé, a ò tún jẹun bí ẹrú mọ́.
Kí a sì tún rántí pé, kò sí ààyè fún irúgbìn GMO ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá (D.R.Y), nítorí irúgbìn aṣekúpani ni, ẹ̀sùn apànìyàn ni pẹ̀lú.
Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí màmá wa MOA bá wa sọ láìpẹ́ yí wípé, ní kété tí àwọn aṣojú orílẹ̀ èdè wa bá wọlé sí oríkò ilé iṣẹ́ ìṣàkóso, ara àwọn iṣẹ́ tí wọn yóò kọ́kọ́ ṣe ni pípèsè oúnjẹ.
Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a máa múrasílẹ̀ fún àjọyọ̀ tó ń bọ̀ lọ́nà, kò sí Ìbànújẹ́ fún wa, ayọ̀ ni ti wa.
Ìbùkún ni fún Orílẹ̀ Èdè mi, Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá D.R.Y.