Nígbà gbogbo ní àwa ìran Yorùbá yóò máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè tó sí’jú àánú wò wá, tó rán ìyá onínúure sí wa láti tú wa sílẹ̀ kúrò nínú oko ẹrú, gẹ́gẹ́ bí màmá wa, ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla ṣe máa ń sọ fún wa wípé, ọmọ Yorùbá ò ní ti oko ẹrú kan bọ́ sí òmíràn.

A ní ìdánilójú pé ní kété tí àwọn adelé wa bá ti wọlé sí oríkò ilé iṣẹ́ ìjọba ní àwọn ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y), ìrọ̀rùn dé fún wa nìyẹn, ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá kankan kò tún ṣe ẹrú mọ́. 

Ọmọ Aládé ní wa, a ti gba ògo wa padà. Nítorí náà, gbogbo àwa I.YP. ti orílẹ̀ èdè D.R.Y níbi gbogbo tí a bá wà, ẹ jẹ́ kí a padà sílé ká lè pa’wọ́pọ̀ tún orílẹ̀ èdè wa ṣe. Ẹrú tí a ṣe lábẹ́ àwọn amúnisìn yí tó gẹ́ẹ́, a ti di òmìnira.

The Democratic Republic of the Yoruba also known in the Yoruba history as Yoruba Nation, Yoruba Kingdom, Yoruba Land and Yoruba Country is the newest nation in the world. The 55th nation in Africa and 17th in Western Africa as of 12th April 2024. Yoruba is know a sovereign nation and its no longer part of Nigeria.