Ní Orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y), màmá wa Oloye ìyá-ààfin Modúpẹ́ Onítìrí-Abíọ́lá jẹ́ kó yé àwa ọmọ ìbílè Yorùbá (I.Y.P) wípé aní láti bímọ si nítorí ọmọ Yorùbà ti dínkù, ìdí nìyí tí ojúlówó ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá ní láti fẹ́ ara wọn láti bí I.Y.P.
Ètò yóò wà fún I.Y.P – onjẹ yóò pọ̀ ní orílẹ̀ èdè wa. Ilé ìwé ọ̀fẹ́ láti alákọ-bẹ̀rẹ̀ títí dé àkọ́gboyè àkọ́kọ́ ní Fásitì. Ètò ẹ̀yáwó yóò wà fún ẹni tó bá nífẹsí láti tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀. Ní kété tí ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá bá ti pé ọmọ ọdún mọ́kànlélógún ètò ilẹ̀ ti wà ní’lẹ̀ fun ati ìrànlọ́wọ́ láti kọ, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Kò sí ìbẹ̀rù tàbí ìfòyà fún àwa ọmọ aládé láti ṣe ohun rere gbogbo tó bá wù wá nítorí wípé déédéé ìgbà yìí àti ní déédéé àsìkò yìí Ọlọ́run Olódùmarè tí rántí àwa ìran Yorùbà sí rere nípasẹ̀ àlàkalẹ̀ tí Ó gbé lé MOA lọ́wọ́.
Ohun tó kù ni kí àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P), kí á ma jó, kí á ma yọ̀, kí á ma bí si, kí á sì ma rẹ̀ sì.
Ìbùkún ni fún Orílẹ̀ Èdè mi, Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá (D.R.Y).