Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ohun ni a nílò ìwádi-ìjìnlẹ̀ lórí rẹ̀, gẹ́gẹ́bí Màmá wa, Ìyà-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá ṣe sọ, pé a máa ṣe ìwádi àti àgbéjáde Ìtàn wá; bẹ́ẹ̀ ni a máa ṣe ìwádi àwọn ohun ìwòsàn abáláyé wa.
Màmá wa sọ bákannáà pé gbogbo ẹni tí ó bá ní ẹ̀bùn fún òwò kan tàbí òmíràn tí ó jẹ́ pé àwọn kan jẹ gàbá lé lórí ní ilẹ̀ Yorùbá, kí á lọ wádi nípa rẹ̀, láti máà ṣé, nítorí ẹnikan-kan kò ní gàba lé ọmọ Yorùbá nínú òwò kankan.
A tún ti mọ̀, tẹ́lẹ̀, pé, ìwádi tó pọ̀ ni ó máa wáyé nípa iṣẹ́-ẹ̀rọ ní oríṣiríṣi.Kíni ìwọ̀nyí nsọ fún wa?
Wọ́n nsọ fún wa pé iṣẹ́ wà gidi fún wa, gẹ́gẹ́bí ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) láti gbé oríṣiríṣi ìmọ̀ jáde, fún iṣẹ́ tí ìwádi wọ̀nyí máa já sí, tí èyí á wá jẹ́ ìpilẹ̀ṣẹ̀ fún oríṣiríṣi àbáyọrí-sí-rere ní iṣẹ́ ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè wa.
A ò gbọ́dọ̀ ṣe ọ̀lẹ o. Ó túmọ̀ sí pé iṣẹ́-ọpọlọ, ìwádi-ìrònú-jinlẹ̀ àti ṣíṣe àwárí oríṣiríṣi Ìmọ̀, Ọgbọ́n àti Òye, máa kó ipa tó lágbára gidi ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y).