ỌLỌ́RUN OLÓDÙMARÈ, ÀWÁMÁRIDÍ, NÍSIÌYÍ, BA GBOGBO OHUN-IBI JẸ́, PÁTÁPÁTÁ; GBOGBO MÁJẸ̀MÚ ÌRÁNṢẸ́-ẸNI-IBI, ÀṢÌTÁÁNÌ, GBOGBO ÌLÉRÍ, ÈTÒ, ÈTE, ÀTI ÈRÒ TÍ Ó LÒDÌ SÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ YORÙBÁ, ÌRAN YORÙBÁ, ILẸ̀ YORÙBÁ, ÌṢÈJỌBA YORÙBÁ, AGBÈGBÈ-ÀJOGÚNBÁ YORÙBÁ. NÍ AGBÁRA TÍ ỌLỌ́RUN FI NJẸ́ ÈMI-NI, KÍ ÌPARUN NÁÀ ṢẸLẸ̀ SÍ ÀWỌN Ọ̀TÁ YORÙBÁ WỌ̀NYÍ, LỌ́WỌ́LỌ́WỌ́ BÁYI

OLÓDÙMARÈ, ALÁGBÁRA, TÍ Ó NÍ IPÁ; OLÓDÙMARÈ TÍ Ó NÍ IPÁ LÓJÚ OGUN, ỌLỌ́RUN ÀWỌN ỌMỌ-OGUN, ṢE ÌPARUN PÁTÁPÁTÁ, NÍSIÌYÍ, FÚN ÀṢẸ, AGBÁRA ÀTI IPÒ TÍ WỌ́N NLÒ LÁTI JẸGÀBA LÓRÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TI YORÙBÁ, ÌRAN YORÙBÁ, ILẸ̀ YORÙBÁ, ÌṢÈJỌBA YORÙBÁ, AGBÈGBÈ-ÀJOGÚNBÁ YORÙBÁ.

ṢE ÌPARUN FÚN GBOGBO ÌWÀ ÌDÚKOKÒ, ÌJẸGÀBA, DÍDẸ́RÙBANI, ÌHÀLẸ̀, ÌGBÓGUN-TINI, TÍ WỌ́N DOJÚKỌ ỌMỌ-ÌBÍLẸ̀-YORÙBÁ, TI ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TI YORÙBÁ

Nígbà tí Olódùmarè ṣẹ̀dá ìran Yorùbá, ó fún wa ní èdè kan ṣoṣo èyí tí a ń pè ní èdè Yorùbá, èyí ń sọ fún wa wípé ọ̀kan ni wá, nítòótọ́ ahọ́n lè yàtọ̀ ṣùgbọ́n orílẹ̀ èdè kan ni a jẹ́ nítorí pé orílẹ̀ èdè tí kò bá sọ èdè kan náà kìí ṣe orílẹ̀ èdè rárá, bóyá wọ́n kàn ṣẹ̀dá irúfẹ́ orílẹ̀ èdè bẹ́ẹ̀ yálà láti fi ṣe okòwò tàbí ṣe iṣẹ́ ibi míràn ni. 

Nítorí náà gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P) ti orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) ẹ jẹ́ kí a wà ní ìṣọ̀kan, kí a sì gbárùkù ti àwọn adelé wa, gbogbo ìgbà náà ni màmá wa ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla ìyá ìran Yorùbá máa ń sọ fún wa wípé ọ̀kan ṣoṣo ni wá. Kò sí nkan tó ń jẹ́ wípé Èkó ni ẹnìkan ti wá tàbí Èkìtì ni ẹnìkan, ìkan náà ni gbogbo wa.

Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a ṣe ara wa lọ́kan, níbikíbi tí a bá ti rí ọmọ Yorùbá, ẹ jẹ́ kí a fi ìfẹ́ hàn sí ara wa nítorí pé ní orílẹ̀ èdè D.R.Y kò ní sí ìpinyà kò dẹ̀ ní sí ìyapa nítorí abẹ́ Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y ni gbogbo wá wà.