Ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y) àlàkalẹ̀ ètò ẹ̀kọ́ tó yè kooro ti wà fún àwọn akẹ́kọ̀ wa láti ilé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ títí dé ilé ìwé gíga.
Ẹ̀kọ́ tó péye ni àwọn akẹ́kọ̀ wa yóò máa kọ́ ní ilé ìwé pẹ̀lú àwọn ohun èlò ẹ̀kọ́ ti ìgbàlódé lorísìírísìí tí yóò mú ẹ̀kọ́ náà rọrùn fún àwọn akẹ́kọ̀ àti fún àwọn olùkọ́ bákan náà.
Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe mọ̀ wípé Olódùmarè dá àwa ìran Yorùbá pẹ̀lú ọpọlọ pípé, àkokò nìyí tí ògo àwa ọmọ Yorùbá ti orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá yóò búyọ nípasẹ̀ àlàkalẹ̀ ètò ẹ̀kọ́ tó ti wà nílẹ̀ fún àwọn akẹ́kọ̀.
Gbogbo àwọn yàrá ìkàwé ni yóò dùn ún wò. Iná mọ̀nà-mọ́ná tí kò ní ṣẹ́’jú bẹ́ẹ̀ni omi ẹ̀rọ yóò wà ní àrọ́wọ́tó àwọn akẹ́kọ̀ wa. Ẹ̀rọ ayárabíàsá náà yóò wà fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́, ore ọ̀fẹ́ yóò wà fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti ṣe ìwádìí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀. Ìwọ̀nyí àti àwọn ohun míràn ni a óò jẹ ìgbádùn rẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́ ní orílẹ̀ èdè D.R.Y.
Ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ fún ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P), láti alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ títí dé àkọ́kọ́ gboyè ní Fáṣitì. Àti pé, èyíkéyìí nínú àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P) tó kọ̀ láti kó ọmọ rẹ̀ kúrò ní ilé ìwé agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà tí ó nfípá jẹ gàba lórí ilẹ̀ wa D.R.Y, lẹ́yìn tí màmá wa Modupẹọla Onitiri-Abiọla (olóyè ìyá ààfin) ti kéde wípé kí a kó àwọn ọmọ wa kúrò ní ilé ìwé, irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ yóò san owó ilé-ìwé àwọn ọmọ rẹ̀, tí owó ilé-ìwé náà yóò sì pọ̀ jù tí àwọn àjèjì lọ, gẹ́gẹ́ bí màmá wa MOA ṣe sọ fún wa.
Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a fi ọwọ́ so’wọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn aṣojú wa kí gbogbo wa lè jọ jẹ ìgbádùn lọ́kan-ò-jọ̀kan tó ti wà nílẹ̀ fún gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá ti orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá.
Ìbùkún ni fún Orílẹ̀ Èdè mi, Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá, D.R.Y.