Ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P) ti Orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá (D.R.Y), a kí ara wa kú oríre fún ayé ìdẹ̀rùn tí Olódùmarè lo màmá wa,
Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá-Ààfin) fún, nípasẹ̀ mùdùnmúdùn àlàkalè ètò tí Olódùmarè fi rán màmá wa MOA sí àwa ọmọ aládé.
Láti ọmọ ọwọ́ títí di arúgbó, ìgbé ayé ìrọ̀rùn ti dé bá wa ní D.R.Y. Ìdí nì yìí tí ó fi yẹ kí á máa yìn Olódùmarè nítorí ní déédéé ìgbà yí àti ní déédéé àsìkò yìí ni Ó lo MOA fún wa láti jẹ́ kí á rí ore orílẹ̀ èdè wa D.R.Y jẹ.
Kò sí I.Y.P tí yóò tún ṣe ẹrú mọ́, àfi àwọn tí ìdílé wọn bá ti dalẹ̀ ọmọ Yorùbá nìkan. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a fi ọwọ́sow’ọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn adelé wa, kí a sì yàgò fún ohunkóhun tó lè mú ìfàsẹ́yìn bá orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y.
Ìbùkún ni fún Orílẹ̀ Èdè mi, Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá D.R.Y
A kì í ní k’ọmọdé má d’ẹtẹ̀, tó bá ti lè dá’gbó gbé