Màmá Ìran Yorùbá, Olùgbàlà tí Olódùmarè rán sí àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), màmá wa, Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá-Ààfin) ti fọ’hùn sí’ta – lórí àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè fún wọn, fún orílẹ̀-èdè wa D.R.Y, fún ètò-ààbò.

Màmá wa MOA sọ pé Àlàkalẹ̀ tí ó wà lọ́wọ́ àwọn fún ètò-ààbò ní D.R.Y, èyí tí ó jẹ́ Àlàkalẹ̀ fún àwọn-ọmọ-ogun Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), àrà-ọ̀tọ̀ ni. 

Ní àìpẹ́ yí, nígbàtí Màmá nbá àwa I.Y.P ti D.R.Y sọ̀rọ̀, ni wọ́n gbé ọ̀rọ̀ náà sí’ta. 

Màmá wá sọ pé, àlàkalẹ̀ irin-iṣẹ́-ológun tí àgbáyé kò rí rí, ó wà nínú àlàkalẹ̀ ètò-ààbò fún I.Y.P ti D.R.Y.

MOA tẹ̀síwájú wípẹ́, lágbára Ọlọ́run, ìkéde máa wà fún àwọn tó bá wù láti ṣe iṣẹ́-ológun fún orílẹ̀-èdè wa, D.R.Y, ìkéde máa wà nípa bí wọ́n ṣe máa fi orúkọ sílẹ̀ àti bẹ́ẹ̀-bẹ́ẹ̀ lọ.

Àwọn kan-náà tún wà níkàlẹ̀, gẹ́gẹ́bí Màmá wa MOA ṣe sọ, tí wọ́n fẹ́ wá láti káàkiri gbogbo òkè-òkun. Gbogbo ètò-ìkọ́ṣẹ́ tí oníkálùkù bá nílò, ni wọ́n máa rí gbà. Oníkálùkù ni wọ́n máa fi sí ipò tí ó yẹ kí wọ́n wà. 

Màmá sọ pé ìgbádùn-rẹpẹtẹ ni ó wà nínú Àlàkalẹ̀ náà, fún àwọn ọmọ-ogun D.R.Y. MOA tilẹ̀ sọ fún wa pé, nkan-kan wà nínú àlàkalẹ̀ ètò-ààbò D.R.Y tí ó jẹ́ pé, ní gbogbo àgbáyé kò sí ìlú tó ní nkan-náà.

Ọmọ-Ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P) ti D.R.Y, Èdùmàrè ti ṣewá lógo! Kí a máa dúpẹ́.

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal

Ìbùkún ni fún Orílẹ̀ Èdè mi, Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá D.R.Y.
Bíbíire kò ṣeé fi owó rà