Tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa orílẹ̀ èdè tí Olódùmarè dá lọ́lá ní àgbáyé, ipò Kínní ni orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) wà nípasẹ̀ àlàkalẹ̀ ètò ìsèjọba tí Olódùmarè gbé fún Màmá wa ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla.
Àlàkalẹ̀ yí kún fún orísìírísìí ètò ìgbá’yé-gbádùn, àti pé yóò dá àwa ìran Yorùbá padà sí orírun wa ni. A óò gbé àṣà wa lárugẹ, iná mọ̀nà-mọ́ná tí kò ní sẹ́’jú, ọ̀nà tó já geere, ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ láti ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ títí dé ipele ìkẹ́kọ̀ọ́ gb’oyè Kínní ní Fáṣítì, ètò ìwòsàn ọ̀fẹ́ fún gbogbo ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P), ètò ìrànwọ́ fún àwọn àgbẹ̀, ètò ẹ̀yáwó tí kò ní èlé fún àwọn oníṣòwò àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Àjẹ-ẹ̀-jẹtán ni ore tí Olódùmarè ṣe fún wa yí, ìran Yorùbá ti kúrò nínú oko ẹrú títí láé, a ò sì tún ní padà sínú rẹ̀ mọ́. Ìdí nìyí tí màmá wa MOA ṣe sọ wípé, àlàkalẹ̀ ètò ìsèjọba yí, ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ fi kún un tàbí yọ kúrò nínú rẹ̀, bí yóò ṣe wà títí láé nìyí.
Nítorí náà, àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá dúpẹ́ lọ́wọ́ màmá wa ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla lọ́pọ̀lọpọ̀ fún iṣẹ́ ribiribi tí wọ́n ṣe fún ìran Yorùbá, a mọ rírì iṣẹ́ rere yín màmá wa, kí Ọlọ́run Olódùmarè túbọ̀ máa ṣe àtìlẹ́yìn fún un yín. Bákan náà ni a kí gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P) wípé, a kú oríire!